Ghana Covid 19 ban: A ti wọ́gilé àpèjẹ níbi ètò ìsìnkú àti ìgbéyàwó nítorí ìtànkálẹ̀ Covid 19 lẹ́ẹ̀kejì- Aarẹ Akufo Addo

Covid 19

Oríṣun àwòrán, @Jubilee House

Aarẹ Ghana Akufo Addo: A ti wọgile apejẹ isinku tabi igbeyawo nitori Covid-19

Aarẹ orile-ede Ghana ti wọn sẹsẹ dibo yan fun saa ikeji, Nana Akufo-Addo ti gbe ofin ati ilana idaaboobo tuntun mii kalẹ nitori aarun Covid-19.

Labẹ ilana yii, to bẹrẹ lọjọ to kẹyin osu Kini, ọdun 2021, ko ni si apejo isinku, igbeyawo, ati awọn apejọ idaraya mii titi di ọjọ ti ijọba ba ni pe o tun ya.

Nana Akufo-Addo fi ikede yi sita lasiko to n sọrọ atigbadegba lori bi nkan se n lọ nipa kikoju aarun Covid-19.

Yatọ si awọn igbesẹ wọnyi, Ghana tun fi lelẹ pe ki awọn ti yoo kopa nibi isinku o gbọdọ kọja eeyan mẹẹdọgbọn.

Àkọlé fídíò, Mckinley Erves di ẹni tọ ń ríran rí aàwọ̀ nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀

Bakan naa ni awọn aala ibode lori ilẹ ati ofurufu yoo wa ni titi pa gẹgẹ bi ọna ti ijọba n gbe lati dẹkun itankalẹ Covid-19 ni Ghana.

Aarẹ Akufo-Addo sọ fun awọn eeyan ilẹ naa pe fọfọ lawọn ile iwosan kun bayi.

Ati pe lojumọ kọọkan eeyan 700 lo n lugbadi aarun yi dipo awọn 200 to n lugbadi rẹ lojumọ latẹyin wa.

Laarin ọsẹ meji to kọja apapọ awọn ti wọn lugbadi aarun yi lọ soke lati 1,900 si 5,358.

Bi a ti se n sọrọ yii, awọn to lugbadi aarun yi ni Ghana lati ijọ to ti wọ ilẹ wọn jẹ 65, 427 ti eeyan 405 si ti padanu ẹmi wọn.

Àkọlé fídíò, Tolulope Adeleke Aire: Mo wòye pé àwọn ọkùnrin Nàìjíríà kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìtọ́jú ọmọ tu