Nigeria Police Force News: Wo àwọn òfin nínú iṣẹ́ agbófinró tí kò gbe obìnrin

Oríṣun àwòrán, others
Awọn ofin iṣẹ akanṣe kọọkan ṣegbe fun ọkunrin ju obinrin lọ lorilẹ-ede Naijiria ni ariwo to gab ẹnu awọn eeyan bayii.
Lara awọn iṣẹ ti wọn n pariwo rẹ ni iṣẹ agbofinro ti awọn ofin kan ti de awọn obinrin yatọ si awọn ọkunrin.
Saaju ni iroyin kan ti jade pe Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti fọwọ osi juwe ile fun ọlọpaa obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Olajide Omolola.
Wọn ni eyi ko ṣẹyin pe o loyun lai ṣe igbeyawo.
Ileeṣẹ ọlọpaa mẹnuba abala ofin to ṣagbekalẹ iṣẹ ọlọpaa ni Naijiria eyi to sọ ni abala 127 pe ki wọn da obinrin to ba gboyun ti ko ṣe igbeyawo duro lẹnu iṣẹ ọlọpaa ni Naijiria.
Iroyin ibẹ wa ni pe iwe ofin agbekalẹ ileeṣẹọlọpaa ni Naijira to ti wa lati ọdun 1968 naa ni wọn ṣi n ṣamulo titi di isinyi.
Ni eyi to jẹ ọkan lara ofin ti ko ṣegbe fobinrin rara nibẹ.
Labẹ ofin naa ni a ti ri awọn ofin miran ti ko segbe fabo pe:
- Abala 128 ko faaye gba obinrin ọlọpaa lati wọ ẹṣọ ara bii yẹti eti tabi ẹgba ọrun lasiko to ba wa lẹnu iṣẹ.
- Obinrin to ba ti di abilekọ tabi to wa ninu oyun ko ni oore ọfẹ lati darapọ mọ ọlọpaa Naijiria ayafi to ba ti wọ iṣẹ ṣaju ibimọ tabi iloyun.
- Obinrin to wa lẹnu iṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bii omidan gbọdọ kọkọ gab aaye nipa kikọ lẹta ibeere fun iyọnda si ọga ọlọpaa patapata ni Abuja IGP ṣaaju igbeyawo rẹ.
- Abala ofin yii wa ni 124 ni eyi ti wọn ni yoo fun ileeṣẹ ọlọpaa laaye lati ṣe iwadii irufẹ ọkọ ti obinrin naa ba fẹ fẹ.
- Obinrin ọlọpaa to ba fẹ se gbe igbeyawo ti gbọdọ kọkọ ṣiṣẹ fun o kere tan ọdun mẹta ko to maa gbero igbeyawo ati iyọnda.
- Awọn agbofinro obinrin gbọdọ fi lẹta "W" ṣaaju orukọ ipo ati oye rẹ ki awọn eeyan le mọ pe ọlọpaa obinrin ni.















