Dubai citizenship: Báyìí ni o ṣe lè di ọmọ onílùú ní Dubai pẹ̀lú òfin tuntun orílẹ́èdè U.A.E.

Awọn eeyan ilẹ UAE

Oríṣun àwòrán, Twitter/Sheikh Mohammed

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Orilẹede United Arab Emirates yoo bẹrẹ si ni maa fawọn alejo ni iwe igbelu fun igba akọkọ ninu itan ilẹ naa.

Amọ awọn isọri eeyan kan to le ṣe anfaani funh orilẹede naa ni ijọba pinnu lati maa fun ni iwe igbelu.

Igbakeji aarẹ ilẹ UAE to tun jẹ olori ilu Dubai, Sheikh Mohammed bin Rashid al Maktoum lo fọrọ yii lede lori ẹrọ ayelujara Twitter lọjọ Abamẹta.

Rashid al Maktoum ṣalaye pe ijọba orilẹede UAE ti pinnu lati maa fun awọn akọṣẹ-mọṣẹ, atawọn ti Eleduwa fun lẹbun ara ọtọ ni iwe igbeluu.

Awọn onimọ sayẹnsi, awọn onimọ ẹrọ, onkọwe, awọn oṣere atawọn ẹbi wọn naa yoo lanfaani si iwe igbeluu orilẹede UAE.

Awọn eeyan ilẹ UAE

Oríṣun àwòrán, Twitter/Sheikh Mohammed

Adari ilu Dubai ni igbimọ alaṣẹ orilẹede UAE, ileẹjọ abẹle Emiri atawọn igbimọ alaṣẹ mii ni yoo maa yan awọn to ba kun oju oṣunwọn lati gba iwe igbeluu.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bakan naa, awọn to ba gba iwe igbeluu UAE yoo lanfaani lati maa jẹ ọmọ orilẹede abinibi wọn.

Ninu oṣu kọkanla ọdun 2020 ni ijọba ilẹ UAE kede pe oun yoo maa fawọn alejo to ba ti kawe gba oye ọmọwe ni fasiti ni fisa ọdun mẹwaa.

Fisa naa wa fun awọn to ba kẹkọọ gboye lawọn ile iwe giga fasiti ti orilẹede UAE ba ni ajọṣepọ pẹlu wọn.

Awọn dokita oniṣegun oyinbo to ba tin gbe orilẹede UAE naa lanfaani lati gba irufẹ fisa yii.

Àkọlé fídíò, Pangolin Covid-19: Ẹ wo ẹranko tó ṣeéṣe kó ní ǹkan ṣe pẹ̀lú à[rùn Coronavirus!