Sunday Igboho: Ọlọ́run lọ́wọ́ sí bí mo ṣe lọ dojú kọ apààyàn Fulani ní Ibarapa

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho
Ajijgbara ọmọ ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyemo, ti sps eeyan mọ si Sunday Igboho ti leri leka pe awọn onisẹ ibi laarin awọn Fulani nipinlẹ Ogun ti rugi oyin.
Igboho, ninu fidio miran to lu ori ayelujara pa kede pe oun yoo le awọn onisẹ ibi Fulani naa jinna rere nipinlẹ Ogun.
O ni ariwo isẹ ibi awọn ọdaran darandarn nipinlẹ Ogun ti de etigbọ oun, oun si ti setan lati dahun si igbe ẹbẹ awsn ọmọ Yoruba to wa nipinlẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wò ó bí Afọnja ṣe finú wénú pẹ̀lú Fulani ní Ilọrin títí tó fi jẹ iwọ
- Ògo ilẹ̀ Yorùbá ní Sunday Igboho jẹ́, ẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ìràwọ rẹ̀ wọlẹ̀ - OPC
- Àwọn olóṣèlú ti ń fowó bẹ̀ mí kí n má bá Fulani jà torí ìbò 2023, àmọ́ o ti bọ́ - Sunday Igboho
- Àwọn jàǹdùkú yìnbọn sókè lọ́pọ̀ ìgbà kí wọn tó jó ilé Sunday Igboho - Ọlọ́pàá Oyo
- Sunday Igboho kò lẹ́tọ̀ọ́ láti lé Fulani nílùú, wọ́n sì le pè é lẹ́jọ́ - Femi Falana
- Seyi Makinde lo ṣí ilé mi tó jóná pẹ̀lú ‘transformer 500kva’ - Sunday Igboho
- Ṣọ́jà àti ikọ̀ aláàbò ESN tí Nnamdi Kanu, ṣíná ìbọn fúnra wọn
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
- Wo ìgbésẹ̀ tí àwọn lọ́balọ́ba, ọlọ́pàá àti Seyi Makinde fẹ́ gbé lórí áàwọ Ibarapa
Bẹẹ ba gbagbe, ariwo sọ lẹnu ọjọ mẹta yii nigba ti awọn sọja lọ na awọn agbẹ lawọn abule kan nipinlẹ Ogun lori ẹsun pe wọn ko gba awọn darandaran laaye lati da ẹran jẹ ni agbegbe naa.
Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, Sunday Igboho ni asiko ti to ti Ọlọrun fẹ tu awọn Yoruba silẹ lọwọ ide awọn onisẹ laabi laarin awọn darandaran naa.
O si yẹ ko ye awọn eeyan pe lilọ ti mo lọ si agbegbe Ibarapa lati lọ kilọ fawọn onisẹ ibi Fulani naa ni Ọlọrun lọwọ si.
Iya to n jẹ awọn eeyan ni agbegbe Ibarapa naa ti pọ ju, eyi to le gongo pẹlu iku Ọmọwe Aborode, isẹlẹ yii si lo tu asiri awọn isẹlẹ buruku to n waye nibẹ."
Igboho tẹsiwaju pe "pẹlu aṣẹ Ọlọrun ọba, awọn isoro apaayan Fulani nipinlẹ Ogun naa yoo yanju.
Gbogbo awọn ọdaran Fulani to ba wa loke Ogun ni ko maa mura mi silẹ, mo n bọ kankan."
Ajafẹtọ ẹni naa wa gbarata lori bi awọn oloselu se n pagi dina ijagudu rẹ lati gba awọn iran Yoruba silẹ lọwọ inira, eyi toun n se pẹlu ootọ inu.
Àwọn ọba yarí mọ́ gómìnà Abiodun lọ́wọ́ lórí ìwé ẹ̀hónú nípa darandaran tó pòórá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Ṣe ẹ ri iwe ipẹjọ wa lori awọn ọmọ ologun to fiya jẹ awọn agbẹ wa ni ijọba ibilẹ ariwa Yewa?''
''Rara a ko ri iwe ipẹjọ kankan.''
Ọrọ fakinfa to n waye ree laarin ijọba ipinlẹ Ogun ati awọn oriade ijọba ibilẹ ariwa Yewa.
Eyi ko si sẹyin iwe ifehonuhan ti awọn ọba kọ pe ko tẹ awọn lọrun bi awọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria kan ṣe fiya jẹ awọn agbẹ.
Bi a ko ba gbagbe, laipẹ yii ni iroyin gbode pe awọn ọmọogun orileede Naijiria kan fiya jẹ awọn agbẹ lagbegbe Yewa, nitori awọn agbẹ naa kọ lati jẹ ki awọn darandaran Fulani fi maalu wọn jẹko.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ọba Eselu ti ilu Eselu Oba Akintunde Akinyemi naa si wa lara awọn oriade to kọ iwe ifẹhonuhan si ileesẹ ọlọpaa, ologun ati ijọba ipinlẹ Ogun.
Amọ ṣa, oluranlọwọ Gomina ipinlẹ Ogun lori ọrọ ipolongo, Remmy Hazzan ti salaye pe awọn ko ti ri iwe ihonu han yi gba.
Hazzan fikun ọrọ rẹ pe isẹlẹ́ naa ko ṣokunkun si ijọba ati pe awọn ti n gbe igbeṣẹ lati yanju rẹ.
''A ko ti ri iwe ipẹjọ naa gba ṣugbọn a mọ wi pe iru nnkan bayi n waye''
Nigba tawọn akọroyin beere lọwọ rẹ pe, ki ni igbesẹ ti ijọba n gbe lọwọ o ni ''iwadii ṣi n lọ lọwọ ki gbogbo awọn ti ko ba ti fi iwe ranṣẹ ki wọn ṣe bẹ.''
O ṣalaye pe Gomina yoo ṣe iwadii ọrọ́ naa ati pe oun to rọrun lati ṣe ni ''ki Gomina pe awọn ọga ọmọogun to wa ni bareeke Alamala, ki wọn ṣe iwadii iṣẹlẹ yii''
Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ yanya pe oun ti ri iwe ifẹhonu han naa gba ni tawọn.



















