Sunday Igboho: Ojudu tó pè mí ní tọ́ọ́gì kò lówó mi lọ́wọ́, mo kọjá ẹni tí wọn ń fi owó dí lẹ́nu

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho

Gbajugbaja ajijagbara ọmọ Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ sí Sunday Igboho ti sọ pe, ọrọ ijijagbara fún Yoruba ti oun wa lori rẹ ti di odo to n ṣan ti ko le boju w'ẹyin mọ bayii.

Nigba to n fesi sí ọrọ ti Sẹnatọ Femi Ojudu sọ nipa rẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu ileesẹ mohunmaworan kan, ti fidio rẹ lu ori ayelujara pa, ni Igboho ti fesi bẹẹ.

Babafemi Ojudu lo ni Tinubu fun Sunday Igboho lowo pe ko ma da rogbodiyan silẹ lasiko idibo Gomina ipinlẹ Ekiti, Igboho ni isọkusọ gbaa ni Sẹnatọ Ojudu n sọ lẹnu.

Koda Igboho ke pe Ọgbẹni Ojudu wi pe ko fi ọmọbibi inu rẹ bura ti o ba dáa lójú pe, oun gba owo lọwọ rẹ ni tootọọ.

Sunday Igboho ni ọna lati da omi tutu si oun lọkan lori ọrọ ijijagbara fun iran Yoruba ni isọkusọ ti Sẹnatọ Ojudu n sọ kiri.

Sunday Igboho ati Babafemi Ojudu

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

"Ṣugbọn baalu to ti fo ni wọn n juwọ si, ni ọrọ ijijagbara fun Yoruba da bayii," Igboho ṣalaye.

Igboho ni ọpọ oloṣelu Io ti ranṣẹ si oun pe ki oun maa fa wahala pẹlu awọn Fulani darandaran nitori ibo ọdun 2023.

Amọ, Igboho ni oun ti oun n fẹ ni pe ki gbogbo nkan pada bọ sipo nilẹ Yoruba.

O ni bamu bamu laa yo lawọn oloṣelu bi Sẹnẹtọ Ojudu n ṣe nilẹ Yoruba nigba ti nkan ko fara rọ fun ọpọlọpọ eeyan nilẹ Yoruba.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: N kò fẹ́ oyè ọ̀gá àgbà páta fún ikọ̀ Amotekun nílẹ̀ Yorùbá

"Awọn Fulani n pa awọn eeyan wa, awọn to ka iwe ko ri iṣẹ ṣe, awọn obinrin wa ti di aṣẹwo nitori airiṣẹ ṣe," Igboho lo sọ bẹẹ.

Ọgbẹni Adeyemo sọ pe, owo tó yẹ ki àwọn oloṣelu fi tọju awọn ọmọ Yoruba ni wọn n ko lọ si oke okun.

"Femi Ojudu gan an to n sọrọ ko lowo lọwọ to mi, mo kọja ẹni ti ẹ le fi owo di lẹnu," Igboho ṣalaye.

Igboho ni oun ko "lọmọ tabi iyawo ni Naijiria ti Fulani fẹ jigbe, amọ iran Yoruba ni mo n ja fun."

Ọgbẹni Adeyemo ni "eto abo to mọyan lori lo jẹ mi logun kaakiri ilẹ Yoruba, to ba jẹ ti emi nikan ni, miliọnu kan Fulani ko le da mi lọna."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

"Ẹyin oloṣelu, ẹyin naa mọ pe mo mọ gbogbo aṣiri yin lori bi ẹ ti n ko gbogbo owo to yẹ ki ẹ fi pese eto abo to peye nilẹ Yoruba, tori naa, ẹ lọ ṣọra yin o," Igboho kìlọ.

Ọgbẹni Adeyemo ni Sẹnẹtọ Ojudu ko le sanwo oun ti oun ba fẹ ṣe tọọgi lẹyin rẹ.

Koda o fikun ọrọ rẹ pe, Sẹnẹtọ Ojudu ko ní irú awọn ọkọ bọginni to wa lagbala oun, ki wa lo de to fi n ba oun ni orukọ jẹ kiri.

Sunday Igboho yarí lórí àwọn 'ọ̀rọ̀ ìbajẹ́' tí Babafemi Ojudu kọ nípa rẹ̀

Sunday Igboho ati Babafemi Ojudu

Ajafẹtọ ọmọ Yoruba nni, Sunday Igboho ti fesi si awọn koko ọrọ ti gbajumọ akọroyin ati oloselu kan, Babafemi Ojudu kọ nipa rẹ.

Ojudu, tii se oluranlọwọ pataki si aarẹ Muhammadu Buhari lo kọ apilẹkọ kan sita nipa Sunday Igboho lọjọ Aje, eyi to dabi ẹni ta epo si asọ aala ajafẹtọ Yoruba naa.

Ojudu lo sọrọ nipa awọn ajọsepọ Sunday Igboho ati agba oselu ninu ẹgbẹ oselu APC, Bola Ahmed Tinubu, eyi to fẹ jẹ ọrọ asiri laarin awọn mẹtẹẹtẹ.

Amọ nigba to n fesi sawọn ohun ti Ojudu kọ nipa rẹ, Igboho ni gbogbo ọgbọn ti Ojudu ati awọn to ran nisẹ yii n da nipa oun, pabo ni yoo ja si.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

O ni oun fẹ ki Ojudu sọra ṣe nitori ko si ootọ ninu ọrọ to n sọ pe oun gba owo lọwọ oloṣelu kankan.

''Nitori 2023 ni Ojudu ati awọn to n ran niṣẹ fi fẹ ba ilẹ Yoruba jẹ. Ati ojudu ati awọn to ran niṣẹ, Ọlọrun ko ni fun wọn ṣe''

''Mo fẹ fi da gbogbo eeyan loju pe, oloselu meji pere ni mo ba se, awọn naa ni oloogbe Lam Adesina ati Sẹnetọ Rashidi Ladoja."

Àkọlé fídíò, African Eye: Wo Jane Mugo, obìnrin bíi ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ bíi James Bond

Igboho ni "Ojudu mẹnuba pe mo lọ ba baba Adedibu lọdun 2009 amọ eyi fihan pe irọ lasan ni ọkunrin yii n pa nitori ọdun 2008 ni baba Adedibu jade laye.

Ninu ọrọ apilẹkọ yii, Ojudu ni agba oloṣelu ilẹ Yoruba kan fun Sunday Igboho lowo lati maṣe da atundi ibo Gomina ru nipinlẹ Ekiti lọdun 2009.

Koko to wa ninu ọrọ ti Babafemi Ojudu sọ nipa Sunday Igboho ati Tinubu niyi:

  • Lẹyin ti ile ẹjọ paṣẹ ki wọn tun ibo gomina ni ipinlẹ Ekiti di lọdun 2009 laarin Segun Oni ti PDP ati Kayode Fayemi ti ACN, Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu ACN fẹ fi tipa gba ipinlẹ Ekiti
  • Ko pẹ lo lu sita pe awọn eeyan kan lẹgbẹ oṣelu PDP fẹ lo awọn janduku fi da nnkan silẹ lasiko idibo naa
  • Tinubu gbe Babafemi Ojudu dide lati ba awọn gbajumọ janduku to le lọwọ ninu ibo naa sọrọ, ki o si fun wọn lowo gọbọi
  • Ojudu ba Ade Basket nilu Akure ati Fada Geri nilu Ondo sọrọ, wọn si tọwọ bọ iwe pe awọn ko ni da si idibo Ekiti ru nigba naa
  • Lẹyin ọpọlọpọ wahala, Babafemi Ojudu ni oun ri Sunday Igboho ti o ni sẹnatọ kan nipinlẹ Ọsun fẹ lo o, o ni oun si seto ipade laarin Igboho ati Tinubu
  • Ile itura kan ti ko jina si ile itura nla Premier Hotels ni Ibadan ni wọn ti pade
  • Tinubu sepade pẹlu Igboho nile itura Sunview nilu Akure ni nnkan bii agogo mẹwaa alẹ
  • Tinubu salaye pataki ijọba tiwantiwa fun igboho ati idi ti ko fi yẹ ki wahala maa wa lasiko idibo, Igboho si gba
  • Gbogbo asiko to lo nile itura naa pẹlu Tinubu, gbogbo nnkan ti wọn fi lọ igboho titi dori ohun mimu lo kọ ṣugbọn o gba ọrọ ti Tinubu sọ lọjọ naa, pẹlu ileri pe wọn ko ni da wahala silẹ lasiko idibo naa
  • Ojudu ni ẹri nla ni eyi pe lootọ Sunday Igboho le jẹ janduku ṣugbọn eeyan to lẹri ọkan ni, bi ẹ ba farabalẹ gbe ọrọ tọ ọ lọ
  • Gbogbo ile itura to wa nilu Ado Ekiti ni Tinubu ra gbogbo yara wọn patapata eyi to fi di dandan fun wọn lati mọ eeyan yowu to ba fẹ gba yara itura lasiko idibo naa
  • Ojudu sọ pe Igboho sọ fun oun pe ọdọ Baba Adedibu ni oun ti kọ isẹ tọọgi, oun si ni olori awọn janduku fun Adedibu nilu Ibadan.

Yoruba ati Fulani lo dìtẹ̀ pọ̀ jó ilé mi - Sunday Igboho sọrọ soke lori ile rẹ to jo

Aworan Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, BBC Sport

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, Sunday Igboho, tii se gbajugbaja ajafẹtọ Yoruba, ti awọn kan lọ dana sun ile rẹ ni adugbo Soka ni Ibadan, ti sọrọ lori isẹlẹ naa.

Sunday Igboho, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ, ninu eyi ti BBC Yoruba wa lara wọn lo ti kede pe, o jẹ iyalẹnu fun oun pe awọn Yoruba kan n lẹdi apo pọ pẹlu awọn Fulani lati maa tako oun.

Igboho sọ pe ''o jẹ iyalẹnu fun mi pe awọn Yoruba gan lo wa n pete pero pẹlu awọn Fulani darandaran lati wa sọ ina si ile mi.'

Ile mi ti wọn jo nina naa si dun mi gidigidi amọ eyi ko ni da omi tutu si mi lọkan lati ja fun iran Yoruba.

O fikun pe apapọ awọn dukia ti ina ọhun baana yoo to aadọta miliọnu naira.

Ile Igboho to jona

Igboho ni ohun ti oun n ja fun ni pe ki ijinigbe ati ipaniyan lati ọwọ awọn ọdaran Fulani yii wa sopin nilẹ Yoruba.

O fikun pe oun ko ni dakẹ titi ti awọn ọdaran Fulani naa ba kuro nilẹ Yoruba.

Nigba tawọn akọroyin beere lọwọ rẹ pe, ta lo fura si pe o le wa nidi iṣẹlẹ ina naa, Ajafẹtọ ilu ọhun ni oun ko le darukọ ẹni kankan ṣugbọn ''bi iku ile ko ba pani ti ode o le pani''

Ile Igboho to jona

''Ti ko ba lọwọ awọn Yoruba kan ninu...ki lo de ti wọn ko ṣe wa ba mi, ti wọn ba mọ wi pe awọn le ja? Sebi ile mi ni mo wa?

Ti wọn ba mọ pe awọn to bẹẹ, ti wọn si lagbara, wọn ko ba wa ba mi ninu ile ti mo n gbe, a wa mọ ẹni to jẹ ọkunrin laarin wa.

N ko ni oju opo Twitter ati Facebook, awọn ayederu oju opo ni wọn n si kiri lorukọ mi - Igboho

Wayi, Sunday Igboho ti kede fun gbogbo aye pe oun ko ni oju opo Twitter rara tabi Facebook rara.

Igboho, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ ni awọn ayederu oju opo Facebook ati Twitter ni awọn alaida kan si lorukọ oun lati fi maa tu awọn eeyan jẹ.

Ohun ti wọn kọ soju opo Twitter

Oríṣun àwòrán, @SundayIgboho2

''Gbogbo nkan ti ẹ ba ri nibẹ, ẹ sọra se pẹlu wọn, mi o ni oju opo Facebook tabi Twitter kankan''

O ni irọ ni gbogbo ohun tawọn eeyan n ka nipa oun lawọn oju opo ikansiraẹni naa.

O wa rọ awọn eeyan pe ki wọn ma ṣe tẹle ọrọ to wa nibẹ nitori oun ko ni oju opo kankan.