Sunday Igboho: Gani Adams yòǹbó àwọn gómìnà Yorùbá lórí ìpìnnu ìpàdé wọn pẹ̀lú darandaran

Oríṣun àwòrán, Iba Gani Adams
Aarẹ ọna Kakanfo nilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams tun ti sọrọ nipa awọn isẹlẹ to n waye lẹnu lọọlọ yii nilẹ Kaarọ Oojire.
Adams, lasiko to n kopa lori eto tẹlifisan kan nilu Eko salaye pe awa ọmọ Yoruba la n se ara wa nitori bi ko ba si ole ile, ti ita ko le wa ja.
O ni o ti foju han pe awọn eeyan kan laarin iran Yoruba lo n lẹdi apo pọ mọ awọn ọdaran kan laarin Fulani darandaran lati maa huwa ika to gogo yii.
- Seyi Makinde lo ṣí ilé mi tó jóná pẹ̀lú ‘transformer 500kva’ - Sunday Igboho
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
- Nkan márùn ùn nípa Ọgágun Attahiru, òkúta tí Burati kọ̀ sílẹ̀, tó padà di igun ilé
- N kò fẹ́ oyè ọ̀gá àgbà páta fún ikọ̀ Amotekun nílẹ̀ Yorùbá - Sunday Igboho yarí
- Sunday Igboho yarí lórí àwọn ‘ọ̀rọ̀ ìbajẹ́’ tí Babafemi Ojudu kọ nípa rẹ̀
- Àwọn jàǹdùkú yìnbọn sókè lọ́pọ̀ ìgbà kí wọn tó jó ilé Sunday Igboho - Ọlọ́pàá Oyo
- N kò le ṣàtìlẹyìn fún arúfin láti tán ìṣòro ètò ààbò - Seyi Makinde
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
"Iwadii mi laarin awọn fijilante fihan peara awa Yoruba kan n fọwọ sowọpọ pẹlu awọn ọdaran Fulani lati maa ji awọn eeyan gbe gba owo lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.
Awọn eeyan wa lo ko ida mẹẹdọgbọn si ọgbọn laarin awọn ọdaran to n dunkooko mọ alaafia ilẹ Yoruba
Nigba ta fi ọrọ wa awọn ọdaran Fulani ti ọwọ tẹ lagbegbe Ilesa lẹnu wo, a ri pe ọmọ Yoruba lo n bawọn se ounjẹ, bẹẹ si ni Yoruba lo n fun wsn ni iroyin nipa ẹni ti wọn yoo ji gbe."
2013 ni emi ati Igboho ti foju kanra kẹyin, a ko sunmọ ara wa:
Aarẹ, nigba to n sọrọ lori igbesẹ ti ajijagbara Sunday Igboho gbe nilu Igangan, salaye pe, Igboho ko bun oun gbọ rara ko to lọ silu Igangan nibi to ti fun awọn Fulani ni gbedeke ọjọ meje lati ko aasa wọn nilẹ Yoruba.
Amọ o ni yoo nira lati bu Igboho lori igbesẹ to gbe naa nitori awọn eeyan ibẹ to n wa ominira, lo kesi pe ko wa gba awọn silẹ lọwọ awọn ọdaran Fulani naa.
"Ọdun 2013 ni emi ati Igboho ti foju kanra kẹyin, a ko fi bẹẹ sunmọ ara wa, bi o tilẹ jẹ pe n ko fara mọ igbesẹ to gbe amọ yoo soro ki ẹnikẹni to bu lori igbesẹ naa, tori Yoruba n poungbẹ fun ominira."
Nigba to n sọrọ lori ikede ti ọga ọlọpaa pata nilẹ wa, Adamu fun Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Oyo, lati lọ gbe Sunday Igboho wa silu Abuja, Adams ni ọrọ pọ nibẹ.
"Kii se Igboho nikan ni wọn fẹ gbe si ahamọ, awọn agbofinro gan n foju si emi naa lara lati gbe mi, emi ni ẹni akọkọ ti wọn fẹ gbe nitori ọrọ oselu.
Idi ree ti mo fi nilati sọra mi, bẹẹ si ni awọn oloselu kan ti tọwọ bọ ọrọ to nii se pẹlu Sunday Igboho yii.
Adams fikun pe "awọn eeyan to bu ẹnu atẹ lu wa lọdun 2015, ni wsn wa n lo Sunday Igboho bayii lati ba mi lorukọ jẹ, mo si fi ohun gbogbo ti mo ni si ewu fun ilẹ Yoruba.
Bawo ni Sunday Igboho yoo se lo iwa akikanju rẹ lati ba isẹ ti eeyan kan ti se fun ọdun mejidinlọgbọn jẹ? Yoruba maa n ba ti akikanju ati akọni wsn jẹ lẹyin o rẹyin ni."

Abọ ipade awọn gomina ati darandaran nilu Akure dara:
Wayi o, Oloye Gani Adams ti se sadankata si awọn gomina nilẹ Yoruba lori ohun ti wọn fẹnu ko le lori nibi ipade ti wọn se pẹlu awọn darandaran.
Atẹjade kan ti akọwe iroyin fun Adams, Kehinde Aderemi fisita lo sisọ loju ọrọ yii.
Aarẹ ni igbesẹ awọn gomina naa ni yoo mu adinku ba ipaya to wa nilẹ, ti yoo si wa ojutu laelae si eto aabo ti ko fara rọ lẹkun yii.
O fikun pe o yẹ ki gbogbo eeyan gbaruku ti ikọ Amotekun bayii lati pese aabo nilẹ Yoruba nitori ẹkun guusu Naijiria lagbara pupọ ju awsn ẹkun miran ni Naijiria lọ.
- Kìí ṣe àgbẹ̀ nìkan ni ọ̀daràn darandaran n pa, wọ́n n pa àwa Fulani nàá - Ààrẹ Miyetti Allah
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
- Afurasí Fulani daran-daran fi ìbọn fọ́ ìka obìnrin kan lójú pópó
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí Igangan
O wa koro oju si igbesẹ awọn eeyan kan lati sọ ikọ naa ni suna buruku, ki wọn si foju tẹnbẹlu aayan awọn gomina ilẹ Yoruba lori ikọ alaabo naa.
Wọn gbọdọ sawari awọn to jo ile Sunday Igboho:
Aarẹ Gani Adams ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn ọbayejẹ kan se lọ kan ina lu ile Sunday Igboho mọjumọ ọjọ Isẹgun, to si ni igbesẹ naa jẹ ara ọna lati da omi tutu si ajijagbara naa lọkan.
"O se ni laanu pe awọn alagbara kan ko dunnu si ohun to n waye lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, isẹlẹ ina naa lo si n fidi aifararọ eto aabo mulẹ.
Yoo si dara ki ijọba tanna wadi awọn eeyan to wa nidi isẹlẹ yii, ki ọwọja wahala yii ma baa peleke si.





















