Sunday Igboho: Mo ṣé iṣẹ́ mọkaliki ri, bẹ́ẹ̀ sì ní mò tí ṣiṣẹ́ aponmità kí n tó rìnnà ko oríire

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday_igboho1/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni oni ọjọ Kẹwa, osu Kẹwa ọdun 2021 ni ayajọ ọjọ ibi gbajumọ ajijagbara ọmọ ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan tun mọ si Sunday Igboho.

Nilẹ kaarọ o jiire, orilẹede Naijiria ati ni awujọ agbaye pata, ọrọ to n gbẹnu awọn ọmọ Yoruba ati ẹya miran ni ti họwu-họwu laarin Sunday Igboho ati ijọba apapọ.

Bakan naa ni awọn ohun ti Igoho se nipa ikọlu awọn afurasi darandaran Fulani si agbegbe Ibarapa, ijijagbara fun ọmọ Yoruba ati bi wọn se fi si ahamọ nilẹ Benin Republic si n ja rain-rain.

Ọrọ yii gbale o gba oko, debi pe akọni ọmọ Yoruba naa n koju igbẹjọ nilu Cotonou, nibẹ lo si ti n sami ọjọ ibi ọdun kọkandinlaadọta rẹ loke eepẹ.

Ọna lati sami ajọdun ọjọ ibi yii lo mu ki BBC se akojọpọ ohun mẹfa to se koko nipa Igboho, eyi ti ẹ ko mọ tabi gbọ ri nipa rẹ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

Sunday Igboho di ilumọọka lasiko laasigbo Modakẹkẹ ati Ife:

Ilu Modakeke ni ipinlẹ Osun ni Sunday Adeyemo dagba si bo tilẹ jẹ wi pe ilu Igboho ni ipinlẹ Oyo ni ilu abinibi rẹ.

Lasiko aawọ Modakeke Ife, Igboho ko ipa ribiribi lati fi gbe lẹyin awọn eeyan Modakeke.

Iwa akikanju ati isẹ takuntakun to se lasiko laasigbo naa lo mu ki awọn kan fi n sọ pe o loogun gan an bii Arọni.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin Tribune lọdun 2019 o sọ pe ''mo korira ki wọn maa yan eeyan jẹ.Idi ree ti mo fi gbe lẹyin Modakeke''

''Modakeke ni baba mi n gbe, ibẹ ni mo dagba si, ibẹ la kọle si, ti mo si bimọ sibẹ.

Se ki n yaju silẹ ki eeyan kan wa dana sun ile baba mi ni?

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

O ṣe iṣẹ mọkaliki, gun ọkada atiapọnmita ri, ki o to wa di ọlọla:

''Ọmọ atapata dide ni mi, baba mi ko si ni kọbọ'' ni apejuwe ti Sunday Igboho a maa saba ṣe to ba n juwe ara rẹ.

A ko ri akọsilẹ ibi to kawe de ṣugbọn ninu awọn fidio orisirisi to n fi soju opo rẹ ni Instagram, Igboho sọ pe oun jẹ iya to pọ, ki oun to jẹ eeyan laye.

Lẹyin to ṣiṣẹ mọkaliki, pọn omi ta ti, to n tun ọkada, lo bẹrẹ si ni ta ọkọ tokunbọ to si tatibẹ da ileeṣẹ Adesun Business Concept silẹ nilu Osogbo

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Lara orukọ apejẹ Baba Igboho ti baba rẹ n jẹ, lo ti mu Igboho inu orukọ rẹ:

Awọn to mọ Igboho ati itan rẹ yoo jẹri si wi pe gbajugbaja oloṣelu, Lamidi Adewolu Ladoja ko ipa ribiribi ninu igbesi aye Igboho.

Oun gan an fun ara rẹ ko ko iyan Ladoja kere ti a si maa fi imoore rẹ han si loorekoore.

Koda, isẹ kekere kọ ni Igboho se lati ri pe iya ko jẹ Rashidi Ladoja gbe lasiko to fi wa nipo, ti wọn si yọ lori oye fun osu mọkanla gbako.

Tiri di akoko yii, aarin Sunday Igboho ati Rashidi Ladoja si gunmọ, koda, aarin wọn ko se ri rara.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ladoja ní bí ìjọba kò bá fi ẹ̀lẹ̀ ṣe, ọ̀pọ̀ ajìjàgbara míì yóò dìde

O ni Ajọsepọ pẹlu awọn olorin, oloṣelu, elere tiata Yoruba ati awọn alfa nilẹ Yoruba

Saheed Osupa wa lara awọn ilumọọka olorin Yoruba to maa n kọrin ki Sunday Igboho.

Awọn oloṣelu ati elere sinima jankan jankan naa a maa ba a ṣe pọ.

Bi eeyan ba de oju opo rẹ ni Instagram niṣe lo kun fun aworan orisirisi to ba awọn eekan ilu ya.

Aworan Sunday Igboho ati Small doktor

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Rasheed Ladoja lo mu gẹgẹ bi awokọse

Ọjọ ọjọọkan ni Sunday Igboho ati Gomina ipinlẹ Oyo nigba kan ri Rasheed Ladoja pade nilu Ibadan.

Gẹgẹ bi awọn kan ti ṣe sọ, ibi ti Igboho ti n ja fun ẹtọ awọn eeyan ni Ladoja to foju si lara to sifa mọra ko maa ba ohun siṣẹ gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Ọdọ Ladoja ni Igboho ti wọ agbo oṣelu to si di wọlewọde awọn eekan oloṣelu ni ipinlẹ Oyo.

Koda ninu ohun to sọ ni pe awọn kan fun ohun lowo lati fidalẹ Ladoja ṣugbọn oun ko dalẹ rẹ.

Iyawo meji lo ni, wọn o si baa gbe pọ ni Naijiria:

Ninu ile janran ti Sunday Igboho kọ si adugbo Sooka nilu Ibadan ko si iyawo kankan to n ba a gbe ninu ile naa.

Yatọ si awọn ọmọ iṣẹ rẹ ati amugbalẹgbẹ rẹ ti wọn jijọ wa nibẹ, ko si iyawo tabi ọmọ rẹ nibẹ.

Aworan iyawo Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Ohun ti a gbọ ni pe iyawo rẹ kan wa ni orile-ede Germany ti ikeji naa si wa ni Canada.

Sunday ni oun ni ọmọ obinrin atri ọkunrin ṣugbọn o kọ lati sọ pato iye awọn ọmọ to bi fun awọn akọroyin.

Ọpọ igba ni wọn maa n ki Sunday Igboho ni Baba Dammy, Baba Ayomide ati bẹẹ bẹẹ lọ.