Sunday Igboho: Wo àwọn èèkàn ìlú tó ń gbóṣùbá fún Òòṣà pé ó kú ọmọ ṣe

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram/SundayIgboho

Yoruba ni ta ba ri ẹni to seun, ẹ jẹ ka ki pe o seun nitori ku isẹ, lo n mu ori onisẹ ya, Yinni yinni, kẹni si le se omiran ni.

Ọpọ ọmọ Yoruba lo ti n dide nile wọn lati lọ ki ajijagbara kan nilẹ Kaarọ Oojire, Sunday Igboho ku isẹ takuntakun.

Bẹẹ ba tii gbagbe, Sunday Igboho lo lọ silu Igangan ni ọsẹ kan sẹyin lati lọ fawọn ọdaran Fulani lagbegbe Ibarapa ni gbedeke ọjọ meje, pe ki wọn ko aasa wọn lagbegbe naa.

Isẹlẹ yii lo n ja rainrain yika ilẹ wa, bi awọn eeyan kan si se n kọrin re ki Igboho, ni awọn miran ni o n se ofin lọwọ ara rẹ.

Sugbọn awọn ọmọ Yoruba kan ko duro lori ayelujara nikan, amọ wọn morile ile Sunday Igboho lati fi atilẹyin wọn han fun lori igbesẹ akin to gbe naa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Yoruba sa ni aja to ba lẹni lẹyin, nii pa ọbọ.

Eyi ko si tun le sẹyin bi awọn janduku ẹda kan ti ẹnikẹni ko mọ, se lọ sọ ina si ile Sunday Igboho ni oru ọjọ Aje si Isẹgun.

Ọpọ eeyan yika Naijiria si lo dide lati tabuku iwa laabi naa, ti wọn lo tako ofin, o si wa lati da omi tutu si ọkan ajijagbara naa ni.

BBC Yoruba wa se akojọpọ awọn ọmọ Yoruba to lọ ki Sunday Igboho nile rẹ ati awọn to pe lori foonu pe o ku ọmọ se, to fi mọ awọn to fi ọrọ iwuri ransẹ si.

Saheed Osupa:

Sunday Igboho n ki Saheed Osupa kaabọ sinu ile rẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/King (Dr) Saheed Osupa Akorede

Ni owurọ Ọjọru, ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kinni ọdun 2021, eyiun ọjọ keji ti awọn eeyan kan sọ ina sile Sunday Igboho, ni agba akọrin Fuji, Saheed Osupa se abẹwo sile rẹ.

Osupa, to ko awọn alatilẹyin rẹ kan lẹyin, lo ba Igboho ni alejo nile rẹ tuntun, to n gbe ni adugbo Soka nilu Ibadan.

Gbajumọ akọrin Fuji naa, tii se ọmọ bibi ilu Ibadan lo ti kọrin lọpọ igba fi kọrin re ki Sunday Igboho eyi to si n ja rain lori ayelujara.

Gẹgẹ bi fidio kan ti Saheed Osupa fi soju opo Facebook rẹ ti safihan rẹ, bi akọrin Fuji naa soju kan Sunday Iogboho lo n ki i ni mẹsan mẹwa.

Lara awọn oriki to si fi pe Igboho ni "Sanpọnna Oodua, Ẹkun, ọkọ oke, tawọn to duro ti ajijagbara naa si n ki Osupa kaabọ sinu ile naa.

Lẹyin eyi, ni Sunday Igboho ati Sahee Osupa wa wọnu yara igbalejo nla kan lọ lati tẹ sọrọ eyi ti ko han fun araye.

Sẹnetọ Rilwan Adesoji Akanbi:

Sen Rilwan Adesoji Akanbi ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Facebook/Sen Rilwan Adesoji Akanbi

Sẹnetọ tẹlẹ to soju ẹkun idibo guusu Oyo, Rilwan Adesoji Akanbi naa ti se ago onile sinu ile Sunday Igboho, lati ba kẹdun fun ile rẹ to jona, to si tun se sadankata si lori igbesẹ akin to gbe nilu Igangan.

Sẹnetọ naa lo kede pẹlu aworan loju opo Facebook rẹ pe oun ti lọ ki Sunday Igboho nile rẹ lori isẹ aksni to se, ti Igboho naa si tẹle wa sile pada.

Sen Rilwan Adesoji Akanbi ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Facebook/Sen Rilwan Adesoji Akanbi

Akanbi, tii se Ọkanlọmọ tilẹ Ibadan wa yonbo Igboho pe o mu alaafia jọba pada lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria lai naani idunkooko iku ati dukia rẹ ti wọn jo nina.

Asofin Sina Peller:

Lara awọn eekan ọmọ Oodua miran to yonbo isẹ akikanju ti Igboho se ni Sina Peller, tii se asofin to n soju ẹkun idibo Iseyin, Itesiwaju, Iwajowa ati Kajola nipinlẹ Oyo nile asoju-sofin ilẹ wa.

Sina, to jẹ gbajumọ alafẹ nilu Eko, nii tun se ọmọ bibi gbajugbaja pidan-pidan nni, Ọjọgbọn Abiola Peller to ti di oloogbe.

Shina Peller ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram/shinapeller

Bakan naa ni lo yẹ ko ye wa pe Sina Peller jẹ ọmọ bibi agbegbe Oke Ogun ti Sunday Igboho naa ti wa bi o tilẹ jẹ pe ilu wọn lo se ọtọọtọ.

Sunday Igboho wa lati ilu Igboho ni ijọba ibilẹ Oorelope nigba ti Sina Peller wa lati ilu Iseyin, nijọba ibilẹ Iseyin.

Loju opo Instagram rẹ, Peller sọrọ lori oniruuru awuyewuye to suyọ nipa igbesẹ ti Sunday Igboho gbe nilu Igangan, to si ni inu oun dun si ajijagbara naa.

O ni Igboho ni ohùn tawọn mẹkunnu gba sọrọ nipa iya tawọn ọdaran darandaran fi n jẹ wọn, to si n ṣa ni mẹsan-mẹwa pe "Igboho OOṣa."

Ọrọ ti Sina Peller sọ nipa Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram/shinapeller

"Igboho Oosa yẹ bi jagunjagun, mo si ki pupọ fun iwa akọni, iwuri ati akikanju rẹ pẹlu ipa to ko lati mu adinku ba iwa ọdaran lagbegbe rẹ.

Ko si aniani pe Igboho ti jẹ ki gbogbo aye mọ nipa ipenija eto aabo to n koju ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria bayii nitori iwa ika awọn ọdaran darandaran."

Asoju-sofin naa ni Igboho ti kọ itan to dara fun ara rẹ, itan ko si ni gbagbe ipa to ko lati sọrọ sita lasiko ti eto aabo mẹhẹ.

O wa rọ awọn ọmọ Naijria lati fọwọ sowọpọ, ki wọn si wa ni irẹpọ lati tako awọn ọta to n dide si wọn lẹka eto aabo.

Ooni, Igboho ati Alaafin

Ko tan sibẹ o, lara awọn eekan ọmọ ilẹ Yoruba miran to ti pe Igboho lori foonu lati ki ku isẹ takuntakun ni ,awọn agba oselu, oriade atawọn gbajumọ miran.

Lara awọn oriade to ti se awa lẹyin rẹ fun Igboho, gẹgẹ bi onitọsun ti darukọ wọn ninu fidio kan to n ja rain-rain lori ayelujara ni Ooni, Alaafin, Olubadan, Awujalẹ, Eleko ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan lo ni awọn oloselu bii Femi Fani Kayode ati Ayodele Fayose ti ransẹ ikinilaya si oun, ti Aarẹ Ọna Kakanfo Gani Adams naa ko si gbẹyin ninu awọn to n se atilẹyin fun.