Sunday Igboho: Gani Adams ní ọ̀ràn tí Igboho bá dá, aráàlú ló dá a
Iba Gani Adams ti da si awọn awuyewuye to n su yọ lori igbesẹ ti ajijagbara kan fun ilẹ Yoruba, Sunday Igboho gbe lati gbogun ti awọn ọdaran laarin Fulani darandaran.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC Yoruba, Gani Adams ni awọn onimọ ofin to ni nkan ti Sunday Igboho ṣe tako ofin, ni lati beere ibeere kan.
Ibeere to ni o yẹ ki wọn beere ni pe, ki lo de ti awọn agbofinro ko fi mu awọn ọdaran laarin awọn Fulani to tapa sofin, ti Igboho fi doju ija kọ wọn.
- Sunday Igboho ṣọ́ra ṣe, jẹ́ kí Seyi Makinde ṣiṣẹ́ tí òfin gbé le lọ́wọ́ - Ooni Ife
- Ẹlẹ́nu méjì ni ìjọba Buhari, òun ló ń pín Nàíjíríà yẹ́lẹyẹ̀lẹ - Wole Soyinka
- Wo ìgbẹ̀yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀ Yorùbá tó ran Fulani lọ́wọ́ láti kógun ja ìlú Osogbo
- Ẹ múra mi sílẹ̀ ẹ̀yin apààyàn Fulani ní Ogun, mò ń bọ̀ kánkán - Sunday Igboho
- Àwọn olóṣèlú ti ń fowó bẹ̀ mí kí n má bá Fulani jà torí ìbò 2023, àmọ́ o ti bọ́ - Sunday Igboho
- Sunday Igboho kò lẹ́tọ̀ọ́ láti lé Fulani nílùú, wọ́n sì le pè é lẹ́jọ́ - Femi Falana
- Wò ó bí Afọnja ṣe finú wénú pẹ̀lú Fulani ní Ilọrin títí tó fi jẹ iwọ
- Seyi Makinde lo ṣí ilé mi tó jóná pẹ̀lú ‘transformer 500kva’ - Sunday Igboho
Aarẹ Ọna kakanfo ni nitori iya to ti jẹ awọn Yoruba ''ko si ẹni to le da Igboho lẹbi nkan to ṣe''
''Awọn to ti pa Faborode, to pa eeyan to to aadọta ni Oke Ogun ati Ibarapa laarin ọdun mẹfa, ṣe nkan ti wọn ṣe ko tako ẹtọ ẹda ọmọniyan bi?
Gani Adams ni koda, bi eeyan ba tako nkan ti Sunday Igboho n ṣe, iru ẹni bẹẹ yoo jẹbi ilẹ Yoruba.
O ṣalaye pe, lootọ kii ṣe pe oun ati Sunday Igboho ti sọrọ ṣaaju ko to gbe gbogbo igbesẹ to n gbe, sugbọn ohunkohun ti ko ba a ṣe, ẹtọ Yoruba lo n ja fun.
''Lootọ aburo wa Sunday Igboho akikanju eeyan ni, bo ṣe n sọ wi pe aarẹ mọ nipa rẹ, lootọ ẹni to ba jẹ asiwaju lo maa n mọ nipa nkan.''
''Nigba tawa naa bẹrẹ, ta si kere, a maa n da ọran si awọn baba wa ninu ẹgbẹ Afẹnifẹre lọrun ni. Bi Igboho ba da nnkan silẹ, ọrun wa lo da si gẹgẹ bi agba''

Ni idahun si ibeere pe, ki lo de ti ko fi lewaju awọn to n ja fẹtọ Yoruba?
Gani Adams ni aarẹ Ọna Kakanfo kii dede ṣaaju ogun bi kii ṣe pe yoo ti ran awọn ọmọlẹyin rẹ ṣaaju igba naa.
O ni bi ọrọ ba di wi pe ipa awọn ti aarẹ ran lọ ko ba le ka nkan to wa nilẹ, igba naa ni aarẹ yoo to wa kan si awọn Ọba Yoruba, ko to le bọ sita lati koju ogun.
O pẹ ki Buhari to yan awọn olori ileeṣẹ ologun tuntun
Aarẹ Ọna Kakanfo sọ pe lootọ o pẹ ki aarẹ Buhari to yọ awọn ti ara ilu ti n ke pe ki o yọ nipo, ṣugbọn o pẹ ya ju rara lọ.
O ni ipenija aabo to ba Naijiria kọja ọrọ Fulani darandaran nikan nitori naa, awọn ti wọn gbe sipo yii gbọdọ mura siṣẹ.
Iba sọ pe ki Naijiria to le ri ifọkanbalẹ, ohun ti awọn to wa lori oye gbọdọ ṣe ni ki wọn ṣe atunto orileede Naijiria, eyi taa mọ si Restructuring.
O ni ti a ba ṣe atunto yii, taa si pada si eto ijọba ẹlẹkunjẹkun bi atẹyinwa, a o le ni awọn ẹka ijọba ti yoo mu idagbasoke ba agbeegbe kọọkan.




















