Osogbo War: Wo bí ìrẹ́pọ̀ àti ìṣọ̀kan ṣe mú kí Yorùbá ṣẹ́gun Fulani lọ́dún 1840

Bí Yorùbá ṣe ṣẹ́gun Fulani lásìkò ytí wan kógun wọ Osogbo lọ́dun 1840

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yoruba ni itan kii ku, ẹsin iwaju si ni tẹyin n wo sare.

Ọ́jọ́ ti pẹ ti ajọsepọ ti wa laarin ẹya Yoruba ati Fulani, eyi ti ko sẹsẹ bẹrẹ, bẹẹ ni ko si yẹ ka gbagbe ipa ti Fulani ko ninu aye Alaafin Aolẹ, to fi sẹ epe fun iran Yoruba.

Bakan naa lo yẹ ka ranti ohun to waye laarin Fulani ati Afonja, aarẹ Ọna Kakanfo to tẹdo silu Ilorin, eyi to mu ki ilu naa bọ lọwọ akoso iran Yoruba.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọwọ lọwọ bayii, awuyewuye tun n lọ yika orilẹede Naijiria, eyi ti ko yọ ilẹ Yoruba silẹ, nipa ọsẹ ti awọn kanda kan ninu ẹya Fulani n se fawọn ọmọ ilẹ yii.

Bi awọn ọdaran kan laarin ẹya Fulani naa se n pa eeyan laibikita, paapa awọn agbẹ ti wọn n fi oko jẹ ẹran wọn, naa ni wọn n fi tipa ba awọn obinrin sun, wọn n ji eeyan gbe gba owo, ti wọn si tun ndigun jale.

Ọrọ naa ti wa le gongo bayii, ti igbe a ko fẹ Fulani mọ laarin wa si gba ẹnu ọpọ ẹya to wa lorilẹede Naijiria.

Idi ree ti BBC Yoruba fi mu itan Ogun Osogbo wa fun yin gẹgẹ bo se kan ẹya Yoruba ati Fulani, eyi ti yoo wulo fun wa lasiko yii lati fi kọgbọn.

Ibẹrẹ ogun Osogbo lọdun 1840:

Lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀yà Fulani tí kógun ja ìlú Ìlorin, tí wọn sì fí ibẹ̀ ṣe ibùgbé, ni wọn tí bá ìlú Oyo jagún saaju ní ọdún 1636 si 1835.

Síbẹ̀, aṣeyọri wọn naa kò tẹ́wọn lọ́rùn, ó ṣì wù wọ́n láti tan ibudó àti ìbi ti wọ́n yóò maa darí kaakiri ààrin gbùngbùn ilẹ̀ Yorùbá.

Eyi lo mu wọn gbéra láti lọ kógun ja ìlú Osogbo, tọ jẹ́ ọ̀kan lára ìlẹ̀ Yorùbá lọdun 1840.

Àwọn Fúlàní lábẹ́ ìdarí Ali tó jẹ́ Balogun Hausa ni ìlú Ìlọrin, lo saaju awọn ọmọ ogun Fulani lọ sí ìlú Osogbo láti lọ kogun ja ilu naa.

Nígbà tí Ọba ìlú Osogbo ri pé àwọn ará Ilorin yìí fẹ́ lágbára jù fún Osogbo lati koju, ló ránṣẹ́ sí Ibadan láti wa ràn lọ́wọ́.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: N kò fẹ́ oyè ọ̀gá àgbà páta fún ikọ̀ Amotekun nílẹ̀ Yorùbá

Kíá ni Ibadan lábẹ́ àkóso Obele tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Mobitan àti Alade Abimpagun, rán àwọn ikọ̀ ọmọogun lọ láti lọ ràn wọ́n lọ́wọ́ ni Osogbo.

Gbogbo ìgbìyànjú àwọn ikọ̀ yìí kò le kojú àwọn Fulani Ilorin, wọn tún rán ikọ̀ míràn lọ lábẹ́ àkóso ògbóntarìgì jagunjagun mii.

Amọ síbẹ̀, Fulani lati Ilorin borí gbogbo ogun tí wọ́n jà, tí wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ilẹ̀ lọ.

Nígbà tí Ibadan ri pé bí Ilorin ṣe n ba lọ yìí, wọ́n kò ni pẹ́ gba gbogbo ilẹ̀ Yoruba mọ awọn lọ́wọ́, ni wọ́n tún rán ikọ̀ míràn tó lágbára, tó sì pọ̀ jú tí àtẹ̀yìnwá lọ́ silu Osogbo.

Balogun Oderinlo si lo lewaju awọn ọmọ ogun Ibadan naa láti do jú ikọ̀ ọmọogun Fulani Ilorin.

Nígbà tí Oderinlo àti àwọn ikọ̀ rẹ̀ dé ojú ogun, ni wọ́n ri pé ǹkan ti bàjẹ́ ju bi àwọn ṣe lérò lọ.

Wọ́n kò tilẹ̀ le fí ojú wọ́n han ni ìtà gbngba níwájú ogun Fulani nítorí àwọn ẹṣin tí Ilorin ko wá soju ogun ko gba gbẹrẹ.

Lẹ́yìn ogúnjọ́ tí wọ́n de Osogbo, wọ́n kò le jà ní níta gbangba, Oderinlo wá dábàá pé Elepo, tó jẹ́ ògbójú jagunjagun nilẹ Ibadan, ni àwọn nílò gidigidi lójú ogun.

Sáájú ni olori ogun Ibadan ti yari kanlẹ tẹlẹ pe Elepo kò ni lọ sí ojú ogun nítorí ìwà aidaa ti wọn lo hù lásìkò ayẹyẹ Agbamaja, ti wọn si n fi iya rẹ jẹ lọwọ.

Ní kété oníṣẹ́ Odẹrinlo jẹ́ ni Ibadan, bi o tilẹ jẹ pe o wu Baṣọrun lati ran Elepo lọ sí ogun Osogbo sùgbọ́n kò fẹ se bẹẹ, ko ma ba a tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ tí asáájú ogun ìlú Ibadan fi lélẹ̀.

Bashorun wá fún Elepo npe ko lo Màlúù láti lọ fi bọ òrìṣà rẹ̀ tó jẹ́ Orí, kí ó sì gbàdúrà kí Ibadan rẹ̀yìn ọ̀tá lójú ogun.

Lójú ogun lọ́hùn, Ibadan kò le sún mọ́ ibi ti àwọn Fulani lati Ilorin tí n jagun lójú ọ̀sán nítorí bẹẹrẹ ni Osogbo tẹ́ lọ bí ẹní, tí ẹsin àwọn Fulani Ilorin yóò si tètè rí ẹnikẹ́ni to ba n bọ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Báwo ni wọ́n ṣe borí?

Niwọn igba to jẹ pe ọgbọn kii tan laye, ka wa lọ sọrun, ọgbọn ko si di igi, afi okun, awọn ọmọ ogun Ibadan wá pinnu láti máa kojú awọ́n ọmọ ogun Fulani Ilorin tí ojú ilẹ̀ bá ti pofírí, nígbà ti àwọn ẹsin wọn kò ni le ríran ri ina alẹ mọ́.

Àwọn ọmoogun Osogbo yóò gbéra tó bá ti di aago méjì ọ̀sán lọ sí ojú ogun, iṣẹ wọ́n ni láti ri dájú pé amí kankan kò sí níbẹ̀, tí wọ́n bá sì rí èyíkéyìí, wọ́n yóò mu.

Ní máìlì kan sí ibùbá àwọn Ilorin, wọ́n yoo dúró láti ṣe àtúntò bí wọ́n ṣe fẹ́ kọlu wọ́n.

Àwọn ọmọogun Osogbo tó ti lọ sáájú ni yóò dúró sí ààrín ogun, Olóyè Abitiko àti Labuju ní yóò maa dari ogun ni apá ọ̀tún, Balogun Oderinlo pẹ̀lú àwọn olóyè Ibadan tó kù, ni ń mójú tó apá òsì.

Àrín òru ni wọn ṣe ìkọlu sí àwọn ọmọ ologun Ilorin, akọmọnà wọn loju ogun lọjọ naa ni "Eélòó ni owó odò"

Ìdí tí wọ́n fí ń lo àkọmọ̀nà yìí ni pé, wọ́n gbọdọ̀ wọ inú odò Osun kí wọn tó le wọ inú aarin ilu Osogbo tí wọ́n bá n bọ̀ láti iha gúúsù, ẹni ti kò bá sí ti le pe ọ̀rọ̀ yìí, ó túmọ̀ sí pé, ọ̀tá ni.

Báyìí ni wọ́n ń gorí ara wọ́n mọ́lẹ̀ láàrín àwọn ọmọogun Ilorin nítorí àwọn ọmọogun Ilorin ti dána sí ààrín wọ́n, àwọn Ilorin kò tilẹ̀ le móríbọ́, ẹ̀tù inú ibọ̀n wọ́n, si ló sun wọ́n gúrúgúrú.

Awọn ọmọ ogun Ibadan bẹ ori ọlọtẹ ọmọ Yoruba to gba abọde fun Fulani:

Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe èyí, Ibadan bori ogun náà, tí wọ́n sí kó àwọn eeyan jànkàn-jànkàn lẹ́rú.

Lára àwọn ti wọ́n kó lẹ́ru ní Jímba, Jimba ni olórí àwọn ẹrú Emir Ilorin.

Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ali, tó jẹ́ olórí ogun Ilorin

Olóyè Lateju

Ajikobi, Ajikobi yii si ni Balogun àwọn Yorùbá, eyi to tumọ si pe awọn ọmọ Yoruba kan fọwọ sowọpọ pẹlu ẹya Fulani lati maa ko ogun ja iran Yoruba.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

Wọ́n fi Jimba àti ọmọ Ali kalẹ̀ láti máa lọ ní aláfíà, sùgbọ́n wọ́n bẹ́ àwọn méjì tó kù lórí nítorí pé ọmọ bibi Yorubá ní wọ́n, ìwà ọ̀dàlẹ̀ sì ni wọ́n hù láti lọ darapọ̀ mọ́ Ilorin.

Bíborí Ogun yìi jẹ́ aṣeyọri ńla fún ẹ̀yà Yorùbá, Ibadan mú ìlú Ibokun tó jẹ́ ọkan lára àwọn ìlú Ijesha, ti kò jìnà sí ìlú Osogbo lẹru pẹ̀lú nitori wọ́n fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ilorin.

Lẹ́yìn Ogun yìí, Ibadan wá lọ tún ara mú, wọ́n lọ sí ọ̀pọ̀ ogun, ti wọ́n sì jáwé olúborí bọ̀.

Lára àwọn ogun ti wọn tun ja lẹyin ogun Osogbo ni Ogun Kiriji, níbi ti àwọn awọn olórí ogun Ibadan ti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilu Igbajọ, ti wọ́n sì n sááju ogun fun ìgbà pípẹ́.

Bí àwọn ọmọ ogun Ekiti parapọ̀ ṣe lágbára tó, wọ́n kò ṣẹ́gun wọ́n.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ọmọ ogun nígbà náà ni Fabunmi Okeemesi, Ogedengbe Agbogungboro ti Ijesa, Apasikoto Pasigegele ìlú Igbajo àti Latoosa ti Ibadan.

Itan ti Ogun Osogbo kọ wa:

A kọgbọn pe agbajọ ọwọ la fi n fọya, ajeje ọwọ kan ko gbe, o yẹ ki ilẹ Yoruba pawọpọ ran ara wọn lọwọ lasiko ti ọta ba n gbe ogun bọ.

Itan naa kọ wa pe ka mase dalẹ ara wa nilẹ Yoruba nitori ọdalẹ balẹ ku, ẹni to dalẹ yoo ba ilẹ lọ.

A tun kọgbọn pe ka mase maa fi oju tẹnbẹlu ẹnikan, a dijọ wulo fun ara wa ni.

Ogun Osogbo tun kọ wa pe ki iran Yoruba ni ifẹ ara wọn, nitori airin lọwọọwọ nii jẹ ọmọ ejo niya.