Abdulazeez Olajide Adediran Jandor: O ṣeni láànú pé owó Eko kò ṣiṣẹ́ fún ará Eko

Àkọlé fídíò, Abdulazeez Olajide Adediran Jandor: O ṣeni láànú pé owó Eko kò ṣiṣẹ́ fún ará Eko

Emi ko ki n ṣe ọmọ Tinubu, kóda, mi o gba 'Appointment' ri lọ́wọ́ Tinubu- Jandor PDP

Oludije dupo gomina ni ipinlẹ Eko labẹ ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, Omowe Abdulazeez Olajide Adediran Jandor gbalejo BBC Yoruba.

O sọrọ ilẹ kun lori ipenija awọn olugbe ipinlẹ Eko paapaa lori omiyale lasiko ojo, eto ọrọ aje ati nipa eto ẹkọ.

O ni pe opin de ba ijẹgaba lori awọn ara ilu nibi ti ẹnikan yoo ti maa paṣẹ lori eni to kan lati jẹ gomina, alaga, oba tabi ẹni to fẹ ki wọn yọ kuro nipo.

Funke Akindele ati Olajide Adediran

Oríṣun àwòrán, @Jandor Lagos4lLagos

Kini Jandor tun sọ?

Lori ọrọ pe PDP yan osere to tun n panile rin ni Funke Akindele ti ọpọ mọ si Jenifa, Jandor salaye ni kikun.

O ni pe kii se Jenifa ni PDp yan ni igbakeji oun bikose agbejoro Funke Akindele.

Ati pe ipinle Eko yoo jere lara Funke Akindele pupọ.

Bakan naa lo sọrọ lori ajósepọ rẹ pẹlu Bola Ahmed Tinubu to n dije dupo aarẹ labẹ ẹgbẹ APC.

Jandor ni pe oun ko wọ inu ile Tinubu ri o

Ati pe oun ko ba Tinubu joko papọ sọrọ ri nitori pe oun ko gba ipo ri lọwọ rẹ nitori iṣẹ owọ oun ni oun n se ni aladani.