Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìsìnkú Asẹ́yìn tí ìlú Iseyin Oba Abdulganiy Salawudeen Adekunle Oloogunebi tó wàjà
Wọ́n ti ti gbogbo ọjà Iseyin pa


Gbogbo ojà ni ilu iseyin lo wa ni titi pa.
Eyi waye lati bowo fun Kabiyesi Oba Dr Abdulganiyu Salawudeen Adekunle Oloogunebi Ajinese 1 Aseyin ti ilu iseyin ti o gbèsè lánàá
Ọpọlọpọ ara ilu Iseyin lo wo ààfin kabiyesi aseyein ti ilu iseyin lati daro.

Ninu oro re, ikolaba ti ilu iseyin Oloye agba Ismail Omotosho salaye fun akoroyin BBC to wa ni Iseyin ibi ti ọ̀rọ̀ de duro.
O ni pe ile iwosan ijoba ti ilu ibadan UCH ni kabiyesi ti waja lana.
O tun salaye pe ni kete ti oku Kabiyesi ba ti de si aafin ni eto isinku yoo bẹrẹ.
Oba Adekunle, eni ti iku re de leyin to lo odun mejilelogota (62) lori ile aye ati odun meedogun (15) lori ite.
Makinde, Ooni àtàwọn èèkàn míì ń ṣèdárò Aseyin tó wàjà

Oríṣun àwòrán, Makinde/Ooni
Ọpọ awọn eeyan jankan nilẹ Yoruba lo ti bẹrẹ si n ṣedaro Aseyin ti ilu Iseyin to waja, Oba Abd-Ganiy Adekunle Salawudeen Oloogunebi.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun 2022 yii ni Aseyin lọ darapọ mọ awọn babanla rẹ.
Ẹni ọdun mejilelọgọta ni ori ade naa ko to jade laye.
Iroyin iku Aseyin ba mi lojiji - Ooni
Ẹwẹ, Arole Oodua, Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi ti sọ pe ibanujẹ nla ni iku Aseyin jẹ fun oun.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Ooni, Moses Olafare fi ṣọwọ si awọn akọroyin, Ooni sọ pe iroyin iku ọba alade naa ba oun lojiji.
Atẹjade naa ni “Arole Oduduwa Olofin Adimula, Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja II, gba iroyin iku Aseyin lojiji pẹlu ibanujẹ ọkan.”
“Gẹgẹ bii ẹni to sunmọ Ooni ti wọn si jọ rinrinajo kaakiri pẹlu awọn ọba mii si awọn orilẹ-ede bii UK, Ghana, USA ati Brazil, Aseyin jẹ ẹnikan to fẹran alaafia to si fi gbogbo aye rẹ ṣiṣẹ fun ilọsiwaju ilu Iseyin.”
Lẹyin naa lo gbadura fun idile Aseyin, to si rọ awọn araalu naa lati lati ṣe ẹyẹ ikẹyin to jọju fun oloogbe ọhun.”
Iku Aseyin jẹ ọfọ nlan ni ipinlẹ Oyo – Makinde
Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo naa ti ṣedaro Aseyin ti ilu Iseyin.
O ni Aseyin jẹ ọkan pataki lara awọn ọba alade to gbagbọ, to si n ṣiṣẹ funitẹsiwaju ipinlẹ Oyo.
Makide sọ pẹ adanu nla ni iku ori ade naa jẹ laarin awọn lọbalọba nipinlẹ ọhun.
Lẹyin naa lo ba igbimọ lọblalọba ipinlẹ naa kẹdun, to si gbadura ki Eledua da ẹmi awọn to ku si.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Áṣẹyin ti Ìlú Isẹyin, Oba Abdulganiy Salawudeen Adekunle Oloogunebi tí wàjà
Aseyin ti ilu Iseyin, Oba Abd-Ganiy Adekunle Salawudeen Oloogunebi Ajinese 1 ti rebi agbaa ree.
A gbọ pe Oriade yi to jẹ akọṣẹmọṣẹ oniṣegun itọju ẹranko papoda lọjọ Aiku lẹyin aisan.
A gbọ pe wọn ti n gba itọju o to ọjọ mẹta ni ile iwosan nla fasiti UCH, to wa niluu Ibadan ki ọlọjọto de.
Oba Abd-Ganiy Adekunle Salawudeen, ẹni ọdun mejilelọgọta, ni ọba ilẹ Yoruba kẹrin ti yoo papoda lẹnu lọọlọ yi.
Ninu atẹjade kan ti akọwe aafin Aseyin, ọmọba Femi Olalere fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni ọjọ Aje, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 20222 yii ni baba yoo wọ kaa ilẹ sun.
Laarin oṣu mẹjọ sẹyin la ti gbọ nipa iku Oba Jimoh Oyewumi, Soun Ogbomoso; Oba Saliu Adetunji, Olubadan Ibadan; Oba Lamidi Adeyemi, Alaafin Oyo ti gbogbo wọn re iwalẹ aṣa.

Nigba aye rẹ, Aseyin ilu Iseyin ni alaga igbimọ awọn lọbalọba ni agbegbe Oke -Ogun ni ipinlẹ Oyo.
A ri akọsilẹ pe Abdul-Ganiy Salaudeen Adekunle Oloogunebi Ajinese 1 kii dakẹ lori ọrọ aabo ati idagbasoke ilu Isẹyin.
Bi a ko ba gbagbe ni igba ti ọrọ idasilẹ Yoruba Nation fi n gbona jainjain, Oriade yi sọ pe ki awọn ajijagbara fun ilẹ Yoruba ma ṣe gbe iwọde wọ ilu Iseyin nitori pe awọn ṣi n ṣọfọ awọn eeyan mẹrin ti awọn aṣọbode pa ninu ikọlu to waye nigba naa lọhun.
Loore koore si ni Asẹyin maa n kesi awọn olori Yoruba miran lati ri pe wọn fi iroyin to ba wa ni ikapa wọn ranṣẹ si awọn agbofinro lati le dẹkun awọn to n da omi alaafia ilẹ Yoruba ru.
Oba Salawudeen ni Asẹyin kọkandinlọgbọn ti yoo gun ori itẹ ilu Iseyin.
Lọdun 2006 lo gun ori itẹ lẹyin ti Ọba to jẹ ṣaaju rẹ Oba Ganiyu Adebayo Alobalowo II waja.












