Tọkọ-taya dèrò ẹ̀wọ̀n Kirikiri torí ìwà ọ̀yájú sí ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, David Hundeyin/Twitter
Obinrin kan, Adebayo Ayobami ati ọkọ rẹ, Clinton Ayobami, ti di ero ọgba ẹwọn Kirikiri nitori bi wọn se yaju si awọn ọlọpaa loju popo.
Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, David Hundeyin lo sisọ loju ọrọ yii ninu ikede kan to fi soju opo Twitter rẹ lọjọ Aje.
Hundeyin ni isẹlẹ naa waye lọjọ Aiku lasiko ti awọn osisẹ to wa ni agọ ọlọpaa Ipaja n sisẹ wọn loju popo nipa sise ayẹwo ọkọ.
Alukoro ọlọpaa naa ni adugbo Oluwaga-Ipaja ni awọn ọlọpaa ti da ọkọ Mẹsi-ọlọyẹ kan ti ko ni nọmba lara duro ni deede aago meji abọ ọsan.
Hundeyin tẹsiwaju pe “Obinrin naa lo fi iwanwara, ibinu ati ọna abuku maa beere lọwọ awọn ọlọpaa naa.
O fẹ mọ idi ti wọn fi da ọkọ awọn duro, ti wọn ko si da awọn mọto yoku to n lọ loju popo duro.
Obinrin naa si fi aake kọri lati dahun gbogbo ibeere tawọn ọlọpaa n bi.”
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko naa wa salaye pe, nigba ti awọn ọlọpaa naa ọhun fẹ maa mu wọn lọ si agọ wọn nitori pe wọn fura pe iwa ọwọ wọn ko mọ, ni tọkọ-taya naa ba bẹrẹ si ni yaju si wọn.

Oríṣun àwòrán, David Hundeyin/Twitter
“Tọkọ taya naa lo n na awọn osisẹ ọlọpaa, tawọn onitọun naa si gbẹlẹ le mọto wọn pe ko ni lọ.
A ti wa mu awọn tọkọtiyawo naa, ta si gbe wọn yọju sile ẹjọ lonii, ile ẹjọ si ti pasẹ pe ki wọn lọ fi wọn pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn kirikiri.”
Ninu ikede naa si ni Hundeyin fi fidio kan si, nibi ti tọkọ taya naa ati awọn ọlọpaa ti n wọ idimu.
Koda, obinrin naa gbe ọmọdebinrin, ọmọ tuntun, ti ko tii le ju ọmọ osu mẹta lọwọ, ti ọmọ naa si n ke tan tan tan.
Iwa idaluru ni ọyaju si ọlọpaa labẹ ofin, to si ni ijiya to yẹ:

Oríṣun àwòrán, David Hundeyin/Twitter
Hundeyin wa tọka si abala ofin ilẹ wa to tako iwa yiyaju si awọn osisẹ ọlọpaa lẹnu isẹ wọn.
O wa tọka si pe iwa idaluru ni ki araalu yaju si osisẹ ọlọpaa to ba wa ni ẹnu isẹ, to si ni ijiya to yẹ labẹ ofin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post














