Ẹ má bú ọkọ́ mi mọ́, Bàbá Tobi kò jẹ́bí bó ṣé dáná sún aṣọ èrè ṣíṣá ọmọ rẹ - Ìyá Amusan

Agbábọ́ọ̀lù ní Bàbá Tobi, èmi ìya rẹ̀ náà ń sáré, Ọlọ́run ló gbógo fún wa - Mama Amusan

aworan Tobi Amusan

Oríṣun àwòrán, Tobi Amusan

Iya to bi Tobi Amusan ti o di ilumọọka lagbaye ati akọni ori ọdan ti ko si ẹlẹgbẹ rẹ, Iyafin Amusan ti sọrọ lori ọrọ kan ti ọmọ rẹ sọ.

Tobi lo sọ fun ẹka ere idaraya BBC pe baba oun maa n dana sun asọ ere idaraya oun ni lasiko ti oun n gbaradi, nitori iwe lo fẹ ki oun gbajumọ.

Amọ nigba ti oun naa n ba BBC Yoruba sọrọ, iya Tobi Amusan ni ki awọn ọmọ Naijiria maṣe bu ẹnu atẹlu baba ọmọ oun.

O ni awọn eeyan n bu ọkọ oun lẹyin ti Tobi ni baba oun maa n dana sun asọ ati bata oun nitori pe oun fẹ maa sare ori ọdan. 

Tobi Amusan lẹyin ti o gba ami ẹyẹ agbaye nidi ere sisa onimita ọgọrun, salaye pe ọpọlọpọ igba ni mama oun ma parọ fun baba oun pe oun lọ sí ṣọọṣì.

Amọ to si jẹ pe oun lọ se igbaradi fun ere sísa ni.

Iyafin Amusan wa sọ fun BBC Yoruba pe ara ọmọ lo ta baba Tobi nitori fura Tobi lo ni oun fẹ di dokita.

Mama Tobi ni ojuse awọn si ni lati tọ Tobi sọna, ko le kọkọ moju to ẹkọ rẹ, ko si yago fun ere sisa.

Agbabọọlu ni Baba Tobi, emi iya naa si n sare

“Agbabọọlu ni Baba Tobi, ẹmi iya rẹ gan mo ma n sa ere, fun idi eyi, Baba Tobi fẹ ko gba jumọ eto ẹko rẹ lo fi gbe igbesẹ naa.

Sugbọn o ni ibi ti Ọlọrun ba ni eeyan yoo de, yoo de ibẹ lasẹ Eledumare.”

Iyafin Amusan ni lati ile iwe alakọbẹrẹ ni Tobi Amusan ti bẹrẹ si n ma sare, ki o to lọ si oke okun.

O tẹsiwaju pe, bi ọrọ Naijiria ṣe ba ni lẹru wa lara idi ti baba Tobi fi gbe igbesẹ naa, ti o si rọ awọn eeyan lati mase bu ẹnu atẹ lu igbese wọn.

“Ile iwe jẹ ọkan googi to sọ ọmọ mi di ilu mọka.”

“Lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni ọmọ mi ti n sare, titi ti o fi lọ ka iwe ni oke okun, to fi wa ri anfani lati sare fun Naijiria.

aworan Tobi Amusan

Iyafin Amusan wa rọ awọn obi ati alagbatọ lati maṣe dẹkun nidi sise atilẹyin fun awọn ọmọ wọn, gẹgẹ bi o ṣe ṣe fun Tobi.

Sugbọn o ni ki wọn ri daju pe wọn ran awọn ọmọ naa lọ si ile iwe fun ẹkọ to peye.”

“Pẹlu Ọlọrun, awọn ọmọ le de ibi ti wọn fẹ, a gbọdọ gbaruku ti wọn pẹlu adura, a gbọdọ ran wọn lọ si ile iwe.”

Tobi Amusan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Màmá mi máa ń parọ́ fún bábá mi pé mo lọ sí ṣọ́ọ́ṣì, tí mo bá lọ gbaradì fún eré sísá - Tobi Amusan

Tobi Amusan: Bàbá mi jó aṣọ eré sísá mi níná, ìwé ló fẹ́ kí n kà

Tobi Amusan ti di ilumọọka lagbaye ati akọni ori ọdan ti ko si ẹlẹgbẹ rẹ nidi ere sisa onimita ọgọrun.

Laipẹ yii si ni okiki rẹ kan pe o ti laluyọ nidi ere sisa, to si ti gba ami ẹyẹ agbaye nidi ere idaraya naa.

Ọmọ Naijiria ni Tobi Amusan, o wa lati iran Yoruba, to si gbe ogo orilẹede yii ga.

Nigba to n ba ẹka ere idaraya BBC sọrọ, Tobi Amusan salaye awọn akoko to lo ni Naijiria ati ibasepọ pẹlu ẹbi rẹ.

Iwe ni awọn obi mi fẹ ki n gbajumọ gẹgẹ bii obinrin:

Tobi, tii se ẹni ọdun mẹẹdọgbọn lo salaye pe ọpọ ipenija lo dide si oun nitori ere sisa ti oun yan laayo naa.

Tobi sọ fun BBC pe awọn obi oun ko gba gbẹrẹ rara, ti wọn si mu iwa ọmọluabi lọkunkundun.

O ni ẹkọ iwe nikan ni wọn fẹ ki awọn ọmọ wọn dojukọ, ati pe gẹgẹ bii obinrin, wọn ro pe oun ti n si ẹsẹ gbe, ti oun ko si ni afojusun to dara.

Tobi Amusan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iya mi ri awọn ohun temi ko ri, o maa n ba mi parọ fun baba mi ti mo ba lọ sare:

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n salaye iru atilẹyin to ri gba lati ọdọ iya rẹ, Tobi Amusan ni iya oun ni oju inu, to si ti ri awn ohun ti oun ko ri nipa ọjọ ọla oun.

“Mama mi ro pe o yẹ ki awọn fun mi ni aaye lati se oun to wu ọkan mi, to si maa n fa mi leti lati mase ja oun kulẹ ninu igbẹkẹle ti oun ni ninu mi.

Mama mi yoo sọ fun baba mi pe ipade ẹgbẹ akọrin ni mo lọ ni sọọsi wa nigba kiigba ti mo ba yọ jade nile, tabi ko sọ fun pe mo lọ sibi eto ariyanjiyan akẹkọọ ta n pe ni Debate.

Gbogbo asiko yii, mo ti lọ sibi idije ere sisani awn ipinlẹ miran. Bi gbogbo rẹ si se bẹrẹ ree.

Ni ọjọ kan, baba mi yari, to si koro oju si mi nigba ti asiri tu pe mo n lọ sa ere ori ọdan ni. O jo gbogbo awọn asọ ere sisa mi.

O wa sọ fun mama mi pe iyẹn ni ko jẹigba ikẹyin ti oun yoo foju kan mi ni ibudo ere idaraya.”

Amọ bi o tilẹ jẹ pe baba rẹ ko ni igbẹkẹle tabi igbagbọ ninu ere sisa to yan laayo, sibẹ Tobi Amusan ni igbagbọ pupọ ati igbẹkẹle ninu ara rẹ, eyi to mu ko moke ninu ere sisa.

Tobi Amusan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ààrẹ Buhari, Sanwo-Olu, Dapo Abiodun ki Amusan to gba ‘’World 100m Hudles Champion”’

Aworan Tobi Amusan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Aarẹ Muhammadu Buhari ti darapọ mọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọ Naijiria lagbaye lati ki arabinrin Tobi Amusan ku oriire.

Iyen lẹyin to gba Ami ẹyẹ wura fun Naijiria ninu idije World Athletics Championships ti ọdun 2022.

Amusan to jẹ ẹni ọdun marunlelogun naa lo ṣe ohun ti enikan o ṣeri lasiko to di ọmọ Naijiria akọkọ lati gba Wura ni idije Championship

Ninu ọrọ Aarẹ Buhari, o kii pe o ku oriire to si mu iwuri ba orin orilẹede Naijiria , ti wọn kọ lati sami si Ami ẹyẹ wura to gba naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Aarẹ Buhari ni iṣẹtakuntakun to ṣe naa mu ayọ ati idunnu ba awọn ọmọ Naijiria, eleyii to mu wọn gbagbọ wi pe ko si ohun to ṣoro lati ṣe pẹlu igbagbọ.

O fikun un pe aseyori re yoo jẹ moriya fun awọn ọmọde to n bọ ni ẹyin rẹ lati mọ daju pe ẹni to ba ṣiṣẹ takuntakun yoo ri ere rẹ.

Mo ṣe ipo kẹrin, ìkẹrin, ikẹrin, ki n to jawe olubori – Tobi Amusan

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Eko, Bajide Sanwo-Olu ni itan Amusan jẹ itan Naijiria, eleyii to fi daju pe ti awọn ọmọ Naijiria ba gbagbọ ninu ara wọn, ko si ohunkohun to lee ṣoro ṣe fun wọn.

O ni arabinrin naa kọ awọn ọmọ Naijiria lati ṣiṣẹ ki wọn si mọ pe ere n bẹ fun oniṣẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Ninu ọrọ tirẹ, gomina ipinlẹ Ogun to pe arabinrin naa ni ọmọ oun ti oun yan ni nkan bii osu diẹ ṣẹyin lati ṣe moriya fun iṣẹ to yan laayo.

Amusan to jẹ ọmọ ipinlẹ Ogun ni gomina Abiodun ba yọ ayọ to si ni gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Ogun wa ni ẹyin rẹ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3

Gbajugbaja elere idaraya, Usain Bolt naa ki ku oriire to si ni aṣeyọri rẹ lamilaaka, to si wu ni lori.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 4

Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Amusan ni ohun ni awọn eniyan ma n lo ọrọ o ku diẹ fun nitori igba mẹta ọtọọtọ ni ohun ti ṣe ipo kẹrin, ki o to di pe oun gba ade wura naa.

O gba 100,000 dollars fun Ami ẹyẹ New World Record ati 70,000 dollars fun ami ẹyẹ wura

Amusan lo kọkọ fakọyọ ninu idije to kangun si aṣekagba (Semi-Finals) lẹyin to gba jawe olubori ni iṣeju aaya (12:12 SECONDS)

Lẹyin eyi lo wa fọbale ni aṣekagba idije naa nibi to ti wa jawe olubori to si da ẹni akọkọ lati orilẹede Naijiria ti yoo gbegba oroke ni idije Championships ni agbaye.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 5

Lẹyin to pegede tan, o gba okẹ marun un dọla owo ilẹ okeere ati ẹgbẹrun aadọrin dọla fun jija we olubori to si gba ami ẹyẹ wura.

Apapọ owo to gba ti wọn ba yii si owo orilẹede Naijiria yoo le ni aadọrin miliọnu Naira.

Tobi Amusan rèé ògbóǹtarìgì elére orí ọ̀dàn tó gbé ògo orúkọ Nàìjíríà ga ní ìdíje Commonwealth

Aworan Tobi Amusan

Oríṣun àwòrán, AFP

Ṣaaju asiko yi, ọpọ le ma mọ nipa elere ori ọdan Tobilola Amusan ṣugbọn pẹlu ara to da nibi idije C0mmonwealth to n lọ lọwọ, ọpọ lo n kan sara si arabinrin ọmọ Naijiria yi.

Ninu idije elere sisare fo igi taa mọ si hurdles lo ti fi ounjẹ fẹgbẹ to si gbawo bọ nigba to kopa ninu abala to kangun si aṣekagba.

Ko fi mọ ni eleyi nikan nigba to tẹsiwaju ni abala aṣekagba to si gba ami ẹyẹ wura ninu idije naa.

Pẹlu itu to pa, oun ni ẹni to sa are lasiko to kere julọ ni isọri awọn obinrin.

Ni onka iṣẹju, iṣẹju mejila ati iṣẹju aaya mejila(12.12 secs) lo fi gba ife ẹyẹ naa.

Ẹni ọdun marundinlọgbọn yi fi itan lelẹ nipa pe o la akoko ti ọmọ orileede Amẹrika nii Kendra Harrison ti ṣaaju fi lelẹ gẹgẹ bi ẹni to sare julọ ni isọri ere hurles 100m fawọn obinrin.

Akoko ti Harrison jẹ 12.20 lọdun 2016 lo si fi lelẹ.

Ninu aṣekagba idije ti wn sa lorileede Amẹrika yi, Harrison ṣe ipo keji lẹyin Amusan ninu abala to kangun si aṣekagba.

Wakati meji lẹyin igba to fi ẹyin Harrison lulẹ ni Amusan tẹsiwaju lọ gba ami ẹyẹ goolu ninu aṣekagbga idije naa.

Koda o tun sare ju ti 12.12 to sa ni abala to kangun si aṣekagba ṣugbọn nitori atẹgun to pọ lasiko ere naa, wọn ko kọ 12.06s toi sa silẹ fun.

Omije jabọ loju Amusan eyi to mu ori awọn ọmọ Naijiria wu lori aṣeyọri yi

Fọnran fidio ibi ti omije ti n jabọ loju arabinrin Tobilola jẹ nkan ti ọpọ ti n sọrọ rẹ ni Naijiria loju opo ayelujara.

Niṣe ni Tobi n yọ omi loju nigba ti wọn n kọrin orileede Naijiria fun Tobi gẹgẹ bi ẹni to jaweolubori.

Eyi mu ki ọpọ ọmọ Naijiria kan saara si ki wn si ni akikanju lo jẹ to si tun gbe ogo Naijiria ga.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 6

Wọn bi Tobilola Amusan ni ilu Ijẹbu Ode lọdun 1997 to si kẹkọ jade nileẹkọ girama Our Lady of Apostles Secondary School, Ijebu-Ode.

Ọmọ Yoruba atata yi tẹsiwaju lọ si fasiti University of Texas, El Paso.

Ninu awọn ami ẹyẹ to ti gba sẹyin tẹlẹ ni eyi to gba lọdun 2018 ni ilẹ Afrika ati nibi idije Commonwealth.

Bakan naa lo tun jaweolubori nibi idije Diamond League ni Zurich lọdun 2021

nibi idije elere ori ọdan ni abala 100 metres hurdles.