Iléẹjọ́ dájọ́ ikú fáwọn méjì tó pa akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún márùn-ún
Hanifa Abubakar: Iléẹjọ́ sọ afurasí kẹta lórí ikú ọmọ ọdún márùn-ún sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan

Oríṣun àwòrán, Abubakar Abdulsalam
Ile giga tilu Kano ti dajọ pe ki wọn yẹgi fun oludasilẹ ileẹkọ Noble Kids Academy, Abdulmalik Tanko, tori pe o jẹbi pipa ọmọ ọdun marun kan, Hanifa Abubakar losu kinni ọdun 2022 yii.
Adajọ Sulaiman Na Abba tun dajọ iku fun Hashim Isyaku, ẹni to seranwọ lati gbe ọmọ naa sin.
Bakan naa ni adajọ ni ki afurasi kẹta lori iku ọmọ naa, Fatima Musa lọ se ẹwọn ọdun kan fun ipa to ko nitori bo se gbiyanju lati gbe Hanifa gbe.
Bawo ni isẹlẹ naa se waye:
Osu meje sẹyin ni ariwo gbalẹ pe Hanifa lọ sileẹkọ amọ ti ko pada wa sile mọ.
Gẹgẹ bi ileesẹ ọlọpaa ti wi, awọn afurasi ọkunrin mejeeji naa lo gbinmọ pọ lati ji ọmọde na gbe, ti wn si gba ẹmi lẹnu rẹ.
Nigba ti isẹlẹ naa waye, ariwo idajọ ododo fun Hanifa lo gba ori ayelujara kan ni Naijiria.
Ariwo naa si tun gba ilẹ kan nigba tawọn ọlọpaa ri oku Hanifa ninu ọgba ile ẹkọ Northwest Preparatory school to wa ni adugbo Tudun Murtala nilu Kano.
Ile ẹkọ naa si ni ọmọdebinrin naa n lọ, tawọn ọlọpaa si mu afurasi mẹta lori isẹlẹ naa, to fi mọ olukọ ọmọ naa.

Oríṣun àwòrán, Abubakar Abdulsalam
Awọn eeyan ilu Kano faraya lori iku Hanifa:
Se ni ojora mu awọn abiyamọ nilu Kano nigba ti wn ri oku ọmọdebinrin naa.
Ọjọ Kẹrin osu Kejila ọdun 2021 si ni wọn ji Hanifa gbe lọ lasiko to n ti ile keu bọ pẹlu awọn ọrẹ rẹ.
Bi ọmọbinrin naa si se di awati lo ka ọpọ eeyan lara lori ayelujara nigba naa, paapaa nigba ti wọn ri aworan Hanifa ti baba rẹ gbe sori ayelujara.
Abubakar Abdulsalam, tii se baba Hanifa, nigba to n salaye bi ọmọ rẹ ti se awati, o ni adanwo Ọlọrun ni isẹlẹ naa.
“Bi Hanifa se n mura ile keu lo wa ba mi ni ọjọ Satide naa.
O ni oun n lọsile keu Islamiyah, mo si ni ko maa ka awọn keu kan tẹle mi, to si n ka a.
O wa yiju si mama rẹ pe to ba n ti ọja bọ, ko ba oun ra suuti oni miliki bọ.
Igba ikẹyin ta fi oju wa ri ọmọ naa ree, ohun ti mo si ranti nipa rẹ ni pe ọmọ to ja fafa ni, to si jẹ aayo mi, koda, awn aladugbo lo fẹran rẹ.”
Ààrẹ Buhari gbéra lọ Liberia láti gbàwọ́n ní ìmọ̀ràn lórí ètò ààbò

Oríṣun àwòrán, Google
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari yoo gbera kuro ni ilu Abuja lọ si ilu Monrovia ni orilẹede Liberia lati gba wọn ni imọran lori pataki eto aabo ni iha iwọ oorun Afrika ati pataki idibo ti ko ni abuku ninu.
Ninu atẹjade ti Oluranlọwọ pataki fun aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, Garba Shehu fi lede ni koko ọrọ ti arẹ Buhari yoo sọrọ le lori ni eto aabo ati ibọwọ fun ofin.
Aarẹ Buhari yoo darapọ mọ awọn adari miran ni ilẹ Afrika lati ṣe ayẹyẹ ọdun marundinlọgọsan (175) ti wọn gba omiran, ti wọn si ti n sẹ ijọba tiwantiwa.
Orilẹede Liberia ni orilẹede ni ilẹ Afrika to ni ijọba awarawa to dagba julọ.
Eleyii n waye lẹyin ọjọ meji ti awọn agbesunmọmi fi fidio sita nibi ti wọn ti n na awọn arinrinajọ ti wọn jigbe ni oju irin Abuja si Kaduna.
Ọkan lara awọn agbebọn naa jẹ lara awọn to sakuro ni ọgba ẹwọn Kuje nigba ti ikọ Boko Haram ṣekọlu si ibẹ lati tu awọn eniyan wọn silẹ.
Ninu fidio ti wọn ṣe naa ni wọn ti dunkoko mọ aarẹ Muhammadu Buhari ati gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai.

Oríṣun àwòrán, Google
Ohun ti Aarẹ Buhari yoo sọrọ nipa rẹ niyii ni Liberia...
Amọ Agbẹnusọ aarẹ Buhari ni abẹwọ aarẹ si Liberia pọn dandan lati jiroro nipa eto aabo to dẹnukọlẹ ni iha iwọ oorun ilẹ Afrika.
‘’Aarẹ Buhari ni alaejo pataki nibi ayẹyẹ ijọba awarawa ọdun 175 ni Liberia, ti aarẹ Buhari yoo si ba awọn eniyan sọrọ lasiko yii ti ijọba ogun ti n waye ni ilẹ Afrika.
‘’Liberia, Sierra -Leone to fi mọ orilẹede Naijiria ni yoo maa ṣe idibo gbogboobo ni ọdun 2023, ti aarẹ Buhari yoo si fi idi rẹ mulẹ pe ijọba awarawa lai si idiwọ idena ninu ṣe koko ni ilẹ Afrika.’’
‘’Aarẹ Buhari yoo sọrọ nipa eto aabo to jẹ mọ ọrọ ibode ati eto ọrọ aje.’’












