NLC bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de nílùú Eko, Osun, Oyo, Ondo àti Ogun láti ṣàtìlẹyìn fún ASUU

NLC Protest in Lagos
NLC iwode fun ASUU

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, NLC ti bẹrẹ iwọde lati ṣatilẹyin fun awọn oṣiṣẹ fasiti ni Naijiria, ASUU.

Bi iwọde naa ṣe n lọ lọwọ niluu Eko naa lo n lọ niluu Ibadan atawọn ilu nla mii ni Naijiria.

NLC iwode fun ASUU
NLC iwode fun ASUU

Egbẹ́ oṣiṣẹ Naijiria, NLC ẹka ti ipinlé Eko ti fun ijoba apapọ Naijiria ni gbendeke.

Wọn sọ pe asiko ti to ki ijọba gbe igbesẹ to yẹ lori iyanṣẹlodi awon oluko Fasiti lati oṣu karun un sẹyin.

Ose meji ni gbendeke asiko ti wọn fun ijọba Buhari lati yanju ọrọ ASUU.

NLC iwode fun ASUU
NLC iwode fun ASUU
NLC iwode fun ASUU
NLC iwode fun ASUU

Alaga ẹgbe Osise NLC ti ipinle Eko, Arabinrin Agnes Sessy rọ ijoba apapọ lati tete gbe igbesẹ to yẹ tabi ki wọn maa reti iwọde bii ti #Endsars ti ọdun 2020

NLC iwode fun ASUU
NLC iwode fun ASUU

Koda, agbejoro agba, Femi Falana gan an kopa ninu iwọde naa ni ipinle Eko.

NLC Protest in Lagos

Niluu Eko, oniruru awọn ọlọpaa atawọn agbofinro lo peju sibi ifẹhonuhan naa lati ri daju awọn janduuku ko lo ifẹhonuhan ọhun fun iwa ipoa kankan.

NLC iwode fun ASUU
NLC Protest in Lagos

Abẹ afara kan to wa ni Ikeja, niluu Eko ni ifẹhonuhan naa ti bẹrẹ.

Ifẹhonuhan ọhun ti mu idiwọn ba lilọ-bibọ oju popo lagbegbe ọhun.

NLC iwode fun ASUU

NLC yarí fún ìjọba, wọn yóò tèsíwájú pẹlú ìwọ́de àtìlẹ́yìn ASUU

Aworan aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, NLCHQ

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorileede Naijiria ti faake kọri pe awọn ko ni yẹ pẹlu ipinnu iwọde atilẹyin fawọn oṣiṣẹ fasiti to yanṣẹlodi lọjọ Iṣẹgun yi.

Iwọde naa ni wọn lawọn fẹ ṣe ni atilẹyin ẹgbẹ awọn olukọ fasiti Naijiria ati awọn oṣiṣẹ fasiti bakan naa.

Ninu atẹjade kan ti akọwe agba ẹgbẹ naa Comrade Emmanuel Ugboaja fi sita, o ni awọn ko ni yẹ lati tẹsiwaju pẹlu iwọde atilẹyin fun ẹgbẹ oṣiṣẹ ati olukọ fasiti Naijiria.

Ṣaaju asiko yi ni awọn ọlọpaa ati ẹka ijọba kan ti n sọ pe iwọde wọn yi ko bofin mu ati pe ki wn jawọ nibẹ.

Amọ ninu atẹjade eyi ti NLC kọkọ gbe sita lọgunjọ oṣu Keje wọn ni toun ti gbogbo igbiyanju lati wa ojutu si iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ fasiti, ọrọ naa ko lojutu.

Wọn ni kaka ki ijọba yanju ọrọ naa niṣe ni wọn n runa si pẹlu aṣẹ ko ṣiṣẹ ko si owo ti wọn fida owo oṣu awọn olukọ fasiti duro.

NLC wa sọ pe tori idi eyi, ''awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo lewaju iwde lọ si ile ijọba, ile aṣofin ipinlẹ lọjọ Iṣẹgun ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Keje lati fẹhonu han''

Yatọ si ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC awọn ẹgbẹ miran ti ṣelerilati darapọ mọ iwọde naa lati ṣe atilẹyin bi wọn ko ṣe wa ojutu si iyanṣẹlodi yi to ti le ni oṣu mẹrin.

Ninu awọ́n to fẹ darapọ mọ NLC la ti ri ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ilera, Medical and Health Workers’ Union of Nigeria (MHWUN).