Kò sí àníàní lórí ìwọ́de ta fẹ́ ṣe – NLC, ìwọ́de yín kò bá òfin mu - ìjọba fèsì

Oríṣun àwòrán, Google
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Nàìjíríà, NLC ti ní kò sí àníàní tàbí yíyí ìpinnu àwọn padà lórí ìwọ́de ńlá tí àwọn ń gbèrò láti nítorí ìyanṣẹ́lódì tí ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ fásitì Nàìjíríà, ASUU gùnlé.
Agbẹnusọ ẹgbẹ́ NLC, Benson Upah ní tí ìjọba bá fẹ́ fòpin sí ìyánṣẹ́lódì tí ASUU àti àwọn ẹgbẹ́ mìíràn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga gùnlé, kò le gbà wọ́n ju ọjọ́ mẹ́ta lọ.
Upah ní ọ̀sẹ̀ méjì tí Ààrẹ Muhammadu Buhari fún Mínísítà fétò ẹ̀kọ́, Mallam Adamu Adamu kò ní dá àwọn dúró láti ṣe ìwọ́de tí àwọn ń gbèrò láti ṣe.
Ó ní ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n àti ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n ni àwọn fẹ́ ṣe ìwọ́de náà, ní èyí tí gbèdéke tí ìjọba fún Mínísítà náà kò ní tíì pé.
Ó ní tó bá jẹ́ wí pé ọjọ́ méjì sí mẹ́ta ni Ààrẹ fún Mínísítà náà láti fi wá ojútùú sí ìyanṣẹ́lódì tó ń lọ lọ́wọ́ bóyá àwọn le má nídìí láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìwọ́de àwọn.
Upah tẹmpẹlẹmọ pé àwọn máa ṣe ìwọ́de náà dandan ní ọ̀sẹ̀ tó ń àyàfi tí ìjọba bá ti fòpin sí ìyanṣẹ́lódì ASUU.
Ìjọba ní ìwọ́de tí NLC fẹ́ ṣe lòdì sí òfin, ẹgbẹ́ òṣèlú ló ń lò wọ́n
Mínísítà fétò ìròyìn àti àṣà ilẹ̀ Nàìjíríà, Lai Mohamaaed ti ní ẹgbẹ́ òṣèlú ló ń ti NLC lẹ́yìn láti fẹ́ ṣe ìwọ́de ọlọ́jọ́ méjì tí wọ́n ṣe nítorí NLC àti ìjọba àpapọ̀ kò ní aáwọ̀ kankan.
Mohammed ní ó yẹ kí NLC ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú òṣèlú nítorí ìyanṣẹ́lódì tó ń lọ lọ́wọ́ kò kan NLC, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ NLC tó jẹ́ ASUU ló kàn àti pé NLC náà wà lára àwọn tí wọ́n jọ ń wá bí ASUU àti ìjọba yóò ṣe wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá.
Ó ní kò tọ́ rárá kí NLC kó àwọn ènìyàn jọ sí títì láti máa ṣe ìwọ́de bẹ́ẹ̀ nítorí ohun tó túmọ̀ sí ni pé wọ́n ń pè fún ogun ni.
Bákan náà ló ní ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lòdì sòfin nítorí ìfẹ́ inú lásán ló fẹ́ mú NLC gbé ìgbésẹ̀ náà tó sì yẹ kí wọ́n dá dúró gedegbe sí òṣèlú.
Òfin fàyè gbà wá láti ṣèwọ́de – NLC fèsì
Ẹ̀wẹ̀, nígbà tó ń fèsì pé ìwọ́de náà lòdì sí òfin, agbẹnusọ NLC, Upah ní òfin fi ààyè gba àwọn láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì tàbí ṣe ìwọ́de tí àwọn bá nílò rẹ̀ láti fi bèèrè ẹ̀tọ́ àwọn.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé NLC kò ní ìjà pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀, ẹgbẹ́ ASUU àti àwọn ẹgbk mìíràn tí wọ́n ń yanṣẹ́ lódì wà lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn tí àwọn sì nílò láti jà fún wọn.
Bákan náà ni Upah ní ìgbésẹ̀ àwọn láti ṣèwọ́de kò lọ́wọ́ òṣèlú kankan nínú, àwọn ń jà fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn lásán ni.
“Ó yẹ kí ẹ̀rí ọkàn máa bá mínísítà fétò ìròyìn náà jà nítorí bí àwọn ọmọ wa ṣe wà nílé láti bí oṣù mẹ́fà sẹ́yìn yìí, ipa rẹ̀ kò ní da rárá.
Ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò darapọ̀ mọ́ ìwọ́de
Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Nàìjíríà, Sunday Asefon ní àwọn náà ti ń múra láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórí ìwọ́dé ńlá tí yóò wáyé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀.
Asefon ní àwọn kàn máa kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dání ni àmọ́ ìdarí tí NLC bá fún àwọn ni àwọn máa tẹ̀lé nítorí NLC gangan ló ni ìwọ́de.
Mínísítà, wá ojútùú sí ìyànṣẹ́lódì ASUU, SSANU, NASU, NAAT láwọn fásitì láàárín ọ̀sẹ̀ méjì - Buhari

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti darí Mínísítà fétò ẹ̀kọ́, Mallam Adamu Adamu láti wá ojútùú ti yoo fòpin sí ìyanṣẹ́lódì tí ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, ASUU, gùnlé.
Buhari ní yàtọ̀ sí ASUU, gbogbo àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó ń yanṣẹ́ lódì ni kí mínísítà náà fòpin sí.
Ààrẹ Buhari pasẹ bẹẹ nígbà tó ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn mínísítà kan àti àwọn olórí àjọ ati iléeṣẹ́ ìjọba kan, tí wọ́n ń gbìyànjú láti wá ojútùú sí ìyanṣẹ́lódì náà.
Lára àwọn tó wà níbi ìpàdé náà ni mínísítà fétò ìsúná, Zainab Ahmed, mínísítà fọ́rọ̀ òṣìṣẹ́, Chris Ngige, Mínísítà fọ́rọ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀, Isa Pantami àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ààrẹ Buhari, lẹ́yìn tó gbọ́ ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró láti ẹnu àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn, wa pasẹ fun mínísítà fétò ẹ̀kọ́ láti ṣe ohun tó yẹ, tí ìyanṣẹ́lódì náà yóò fi wá sópin, kó sì jábọ̀ fún òun lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì.
Bákan náà ló darí mínísítà fọ́rọ̀ òṣìṣẹ́, Chris Ngige láti kópa nínú gbogbo ìjíròrò tí yóò wáyé lórí ọ̀rọ̀ náà.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní kí akọ̀wé ìjọba apapọ, Boss Mustapha naa gbọdọ kópa níbi ìpáde tí yóò wáyé náà.
Ẹ ó rántí pé láti ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹta ni ẹgbẹ́ àwọn olùka ilé ẹ̀kọ́ gíga fásità ASUU ti gùnlé ìyanṣẹ́lódì.
Yàtọ̀ sí ASUU, àwọn ẹgbẹ́ ilé ẹ̀kọ́ fásitì tó ń yanṣẹ́ lódì ni ẹgbẹ́ àwọn àgbà òṣìṣẹ́ fásitì (SSANU), ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí kìí ṣe olùkọ́, (NASU) àti ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ, ( NAAT).
Má sọ fún wa pé ó tó gẹ́! Ààrẹ Buhari ohun tó yẹ kóo se rèé - ASUU fún Buhari lésì

Oríṣun àwòrán, Google
Ẹgbẹ awọn olukọ ileẹkọ giga lorilẹede Naijiria, ASUU ti fun aarẹ Buhari lesi pe ki o ko ọrọ rẹ jẹ.
Lẹyin ti aarẹ Buhari paṣẹ pe iyanṣẹlodi awọn olukọ fasiti naa ti to gẹ ki wọn pada si ileẹkọ.
Aarẹ Buhari rọ awọn olukọ naa lati wo ti awọn akẹẹkọ to ti wa ni ile fun oṣu marun un bayii.
Bakan naa ni Buhari fikun un pe igbeṣẹ ẹgbẹ awọn olukọ yii yoo ni ipa lori awọn akẹkọọ ni Naijiria bayii ati ni ọjọ iwaju pẹlu.
Amọ ẹgbẹ ASUU naa ni aarẹ Buhari ko i tii sọ oju abẹ ni iko nitori awọn ni igba ọrọ naa ṣi mọ lori.
Ijọba Buhari lo fa iyanṣelodi awọn olukọ fasiti kii ṣe awa- ASUU
Ẹgbẹ ASUU ni ko si nkan to n jẹ otogẹ ti aarẹ Buhari sọ nitori oun gan an lo jẹbi iyanṣelodi ti awọn gunle.
ASUU ni bi awọn fasiti sẹ bajẹ patapata kaakiri Niajiria ko bojumu ki aarẹ Buhari ṣe atunṣe rẹ ni kiakia.
Bakan naa ni wọn kesi aarẹ Buhari pe o ku diẹ kaato nipa owo osu wọn ti ko san, to si tun kọ lati san owo osu marun un ti wọn ti da isẹ silẹ bayii.
Ẹgbẹ ASUU tun kesi ijọba aarẹ Buhari pe ki wọn mu adehun wọn ṣe, paapaa eleyii ti wọn ni ikọ ajọ Nimi Briggs-led Committee gbe fun minisita fun eto ekọ lati gbe lọ si ọdọ aarẹ lati buwọlu.
Ẹgbẹ ASUU ni ti ijọba ba ti fi aṣe si adehun ọdun 2009 laarin awọn mejeeji, ti wọn si tun fi aṣẹ si awọn adehun miran to jọ mọ ọ, lẹṣẹ\kẹṣẹ ni awọn yoo pada si ẹnu iṣẹ wọn.












