Ẹ wo bí ọwọ́ ṣe tẹ dókítà tó fipa ba aláboyún tó ń rọbí lọ́wọ́ lòpò

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Aworan yii ko niiṣe pẹlu iṣẹlẹ ti a n kọ nipa rẹ, apejuwe ni eyi.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ilu Rio De Janeiro ni orilẹede Brazil ti fi panpẹ ọba mu dokita kan lẹyin ti ẹrọ amohunmaworan safihan bi o ṣe fi ipa ba alaboyun ti wọn n ṣiṣẹ abẹ fun lopọ.

Dokita naa ti orukọ rẹ n jẹ Giovanni Quintella Bezerrani wọn ri to n fi nkan ọmọkunrin rẹ si ẹnu obinrin ti wọn n ṣiṣẹ abẹ fun naa fun bii iṣẹju mẹwaa.

Dokita naa ni o ma n fun awọn alaboyun ti wọn ba fẹ ṣiṣẹ abẹ fun ni abẹrẹ oorun sisun, eleyii ti awọn oloyinbo n pe ni Anaesthetic.

Awọn dokita yii ni wọn ma n fun wọn ni abẹrẹ naa ti ko ni jẹ ki wọn ni inira lasiko iṣẹ abẹ naa.

Amọ dokita yii nigba ti o ba ti fi ipa bawọn lopọ tan ni yoo nu ẹnu wọn nu pẹlu ‘’tissue paper.’’

Iṣẹlẹ naa waye ni Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Keje, ọdun 2022 ti wọn si fi panpẹ mu dokita naa ni ọjọ Aje.

 Ohun ti awọn dokita ẹgbẹ rẹ kọkọ sakiyesi ni bi o ṣe ma n fun awọn alaboyun ni oogun orun to pọju bi o ṣeyẹ lọ.

Bakan naa ti yoo si tun le awọn mọlẹbi ati dokita kuro nibẹ lasiko ti wọn ba n ṣiṣẹ abẹ naa lọwọ.

Eyi lo mu ki awọn alaṣẹ ileewosan naa fun ra, ti wọn si fẹ mọ ohun to ṣẹlẹ, ki ọwọ palaba rẹ to segi.

Njẹ ari awọn miran to ni iru iriri bẹẹ?

Awọn ileeṣẹ iroyin labẹle ni ọkọ ẹlọmiran ti o ṣelẹ si ti jade lati wa sọ.

O ni nigba ti wọn darukọ ọkunrin naa pẹlu aworan rẹ ni oun fi daa mọ.

Arakunrin naa ni iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti wọn le oun jade kuro ninu ileewosan nigba ti wọn n ṣiṣẹ abẹ fun iyawo ounlọwọ, ti wọn ko tilẹ tii gbe ọmọ jade.

Bakan naa lo ni iyawo oun si ti sun fọnfọn ti ko mọ nakankan.

Ijọba orilẹede naa ati ileeṣẹ eto ilera ni Brazil ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, ti wọn si awọn yoo fi jofin ti iwadii ba pari.

Ti o ba jẹbi ẹsun ifipabanilọpọ, o ṣeeṣe ko fi ẹwọn ọdun mẹjọ si marundinlogun jura.