Wo àwọn nǹkan tó yẹ kóo mọ̀ nípa Dókítà Rasaq Oyelami ti NNPP tó ń díje dupò gómìnà Osun

Oríṣun àwòrán, Legit.ng
Rasaq Oyelami Saliu jẹ́ akọ́ṣẹ́mọsẹ́ dókítà àti olóṣèlú tó ń díje dupò gómìnà Ìpínlẹ̀ Osun lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria Peoples Party.
Saliu wà lára àwọn ọ̀dọ́ tó dupò gómìnà Ìpínlẹ̀ Osun ní ọdún 2018.
Ní ìlú Okua, ìpínlẹ̀ Osun ni wọ́n ti bi ní ọdún márùndínláàdọ́ta sẹ́yìn àmọ́ ìlú Ilorin ní ìpínlẹ̀ Kwara ló fi ṣe ibùjókòó.
Ní ilé ẹ̀kọ́ Barakat Community Secondary School ló ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé mẹ́wàá.
Ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Ilorin ló ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó lọ́dún 2003.
Òun ni akọ̀wé owó ẹgbẹ́ àwọn dókítà ìyẹn Nigerian Medical Association (NMA) tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ondo.
Bákan náà ló tún jẹ́ igbákejì Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn dókítà Mùsùlùmí ilẹ̀ Nàìjíríà.
RasaOyelami Saliu ló ni ile ìwòsàn Aroleorisun Medical Mission tó wà ní Okua, ìjọba ìbílẹ̀ Odò Otin, ìpínlẹ̀ Osun.
Bákan náà ló tún ni ilé ìwòsàn Shifauk hospital tó wà ní Akure, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ondo.












