''Naijiria máa tó gba adé mọ́ Amerika lọ́wọ́ ninú ipò gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀èdè kẹ́ta tí...''

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

 O ṣeeṣe ki orilẹede Naijiria di orilẹede kẹta ni agbaye ti awọn eniyan wọn pọju lọ.

Ajọ iṣọkan agbaye ni ẹka United Nations Department of Economic and Social Affairs lo gbe e jade pe eyi yoo ṣẹlẹ ki o to di ọdun 2050.

Wọn ni ko nipe ko ni jina ti iye awọn eniyan to wa lorilẹede Naijiria yoo ju ti orilẹede Amẹrika.

Nibayii, Naijiria ni orilẹede keje ni agbaye ti iye awọn eniyan rẹ pọju lọ.

O ṣeeṣe ki iye eniyan ni agbaye wọ biliọnu mẹjọ ni osu Kọkanla, ọdun 2022 - UN

Gẹgẹ bi iroyin naa ninu atẹjade, o ṣeeṣe ki iye eniyan ni agbaye wọ biliọnu mẹjọ ni osu Kọkanla, ọdun 2022.

Wn ni ti orilẹede India naa yoo ju ti China lọ ni ọdun 2023.

Nibayii, iyẹ awọn eniyan ni agbaye wa ni 7.6 billion, ti yoo si da 8.6 billion ni 2030, 9.8 billion ni 2050 ati 11.2 billion ni 2100.

United Nations Department of Economic and Social Affairs fikun un pe o kere tan eniyan mẹtalelọgọrin lo n dapọ mọ iye awọn eniyan lagbaye, bi o tilẹ jẹ pe iye awọn eniyan to n bimọ si n lọ silẹ kaakiri agbaye.

Awọn orilẹede ti yoo pọju lagbaye ati bi wọn yoo ṣe ri ree...

  • India
  • Nigeria
  • Democratic Republic of Congo
  • United Republic of Tanzania
  • United States of America
  • Uganda
  • Indonesia

Bakan naa ni wọn fikun pe laarin ọdun 2017 si 2050 awọn orilẹede ni Africa yoo ma pọsi.