Ohun méje tó yẹ kí ẹ mọ̀ nípà Samuel Adetona Abede tó ń díje dupò gómínà lẹ́gbẹ́ NRM ní Osun ree...

Oríṣun àwòrán, Google
Oludije sipo gomina nipinlẹ Osun, Samuel Adetona Abede ti seleri lati fopin si ọrọ eto aabo to dẹnukọlẹ nipinlẹ naa ati iwa ipa to n ba awọn eniyan finra.
Oludije lẹgbẹ oṣelu National Rescue Movement (NRM) pegede gẹgẹ bi oludije lẹyin to wọn di ibo abẹle to waye ni ilu Ede.
Ajọ Eleto idibo INEC lo kede Abede to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu ọhun tẹlẹ gẹgẹ bi oludije sipo gomina.
Bakan naa lo kede pe airiṣẹ ṣe yoo dopin ni asiko ti oun ba wa ni ipo gomina.
Awọn ohun meje to yẹ ki ẹ mọ nipa rẹ ree...
- Ọjọ Karun un, Oṣu Karun un, ọdun 1973 ni wọn bi Samuel Adetona Abede naa, to si jẹ ẹni ọdun mọkandinlaadọta.
- Baba rẹ ni Ọmọ ọba Sunday Adewunmi Abede to jẹ ẹlẹsin Kristẹni to jade laye ni Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Kini, ọdun 2018.
- Fasiti Phoenix ni Arizona, lorilẹede Amerika lo bẹrẹ iṣẹ pẹlu Norstead Law, LLC ni ọdun to kọja.
- Oun ni alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Adetona Abede & Co.
- Bakan naa ni o kekọ imọ nipa gbigba owo pada lọwọ awọn oluyawo.
- Ajọ INEC ti kẹde orukọ igbakeji rẹ gẹgẹ bi Amos Fasilat Omolara to jẹ ẹni ọdun aadọta.
- Orukọ iyawo rẹ ni Kọmọlafẹ Tititlayo.
Ajọ Eleto Idibo ni Naijiria, INEC ti kẹde pe Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Keje, ọdun 2022 ni idibo sipo gomina naa yoo waye ni ipinlẹ Osun.











