'Nígbà tí mo rí àwọn Bàtà "Made in Italy" lórí igbá ní ọjà Aba tí wọ́n ṣe ní Nàìjíríà, ojú mi là sí iṣẹ́ tó ń jáwó yìí'

Àkọlé fídíò, Agbelekale Medinat graduate shoe maker: Àwọn bàtà tí mò ń ṣe, ó yàtọ̀ sí èyí tàwọn bàbá àgbà máa ń ṣe

"Bi Naijiria ṣe pada n lọ lọwọlọwọ, tẹẹ ba duro de pe iṣẹ tẹẹ ka nileewe gangan lẹ maa wa, o ṣeeṣe ko jẹ wipe awọn ọmọ kekeeke to wa lẹyin yin ni wọn a pada da owo ounjẹ fun un yin ni".

Medinat Agbelekale to jẹ akẹkọgboye fasiti to si ti ṣe agunbanirọ sọ fun BBC Yoruba pe oun kabamọ asiko ti oun fi ṣofo ni gbogbo igba ti oun n wa iṣẹ ijọba kiri.

Bata

Oríṣun àwòrán, Denaah footwears

Amọ o ni iye oun sọ ni ilu ti oun ti lọ ṣe agunbanirọ nigba ti o de ọja nla kan ni ilu Aba nibi to ti ri awọn oriṣiriṣi bata ti wọn ṣe ni Naijiria amọ ti wọn kọ sii lara pe orilẹede Italy ni wọn ti ṣee ti wọn si dara gidi gan.

Bakan naa, o ṣalaye bi bata obinrin ko ṣe fibẹẹ ja owo to si tun fi imọ kun imọ lori ṣiṣe bata ọkunrin.

Medinat Agbelekale
Bata

Oríṣun àwòrán, Deenah footwares

Lafikun, Medinat sọ bi iwe kika ko ṣe ṣee fọwọ rọ sẹyin to si sọ lọlọkan o jọkan anfani ti iwe kika ti mu wa sori iṣẹ rẹ ati iyatọ to fihan laarin iṣẹ rẹ ati eyi tawọn ti ko kawe n ṣe