Òkú ènìyàn 17 ní a rí padà nínú omi Lagoon ní Eko - NEMA

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ajọ pajawiri nipinlẹ Eko ti ni awọn ti ri oku eniyan mẹtadinlogun pada ninu awọn ti ijamba ọkọ oju omi ṣẹlẹ si ni alẹ Ọjọ Ẹti.
Ọkọ oju omi to n gbe eniyan mẹrindinlogun lo ko sinu omi ti gbogbo awọn to wa ninu rẹ si di awati.
Lati Mile 2 si Ibeshe, Ojo ni ọkọ oju omi naa ti n ṣiṣẹ.
Ajọ̀ Nema ni awọn bẹrẹ wiwa awọn eniyan naa lẹṣẹkẹṣẹ lati doola ẹmi wọn lẹyin iṣẹlẹ ọhun, to si ni awọn ri oku eniyan mẹrin ni ọjọ Satide.
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Eko ni awakọ oju omi naa tapa si ofin nipa wiwa ọkọ oju omi ni alẹ ni aago mẹjọ ku iṣẹju diẹ, eleyii ti o lodi si ofin aago meje ale ti ijọba ni ki ọkọ oju omi maa ṣiṣẹ mọ.
Bakan naa ni wọn fẹsun kan awọn awakọ oju omi yii pe wọn ki n wọ aṣọ idaabobo ‘’Life Jacket’’.
Ti wọn a si tun lo ọkọ oju omi ti wọn fi igi kan lati ṣiṣẹ ati lati gbe awọn eniyan.
Iṣẹlẹ yii waye lai ti pe ọjọ mẹta ti iṣẹlẹ ọkọ oju omi miran waye, ti o si mu ẹmi eniyan meji lọ.
Ilé ẹjọ́ ju awakọ̀ ojú omi sẹ́wọ̀n gbére lórí ikú èèyàn mẹ́tàlá
Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Eko tó wà ní agbègbè Lekki ti ju awakọ̀ ojú omi kan, Happiness Elebiju sí ẹ̀wọ̀n gbére fẹ́sùn lílọ́wọ́ nínú ikú àwọn èrò mẹ́tàlá tó kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi.
Adájọ́ Josephine Oyefeso tún ju Elebiju sí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà fẹ́sùn wíwa ọkọ̀ ojú omi láìní ìwé ẹ̀rí.
Elebiju kojú ẹ̀sùn mọ́kànlá fẹ́sùn ìpànìyàn àti ṣíṣòwò ọkọ̀ ojú omi láìní ìwọ́ lrí láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Adájọ́ Oyefeso ní Elebiju jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án tó sì jù ú sẹ́wọ́n gbére.

Oríṣun àwòrán, Google
Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ Elebiju ń wáyé, olùpẹ̀jọ́ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Eko, Olayinka Adeyemi ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 2020 ni Elebiju ṣẹ àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án nígbà tó kó àwọn èrò láti agbègbè Kirikiri sí Badagry ní ìpínlẹ̀ Eko.
Adeyemi ní Elebiju wa ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ ní ìwàkuwà kó tó di pé ọkọ̀ náà dànù tó sì ṣokùnfà ikú àwọn ènìyàn mẹ́tàlá nínú àwọn ogún èrò tó kó.
Elebiju ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun àti pé òun kò ní ẹjọ́ láti jẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Adájọ́ Oyefeso lẹ́yìn atótónu àwọn agbẹjọ́rò ní Elebiju jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án tó sì jù ú sí ẹ̀wọ́n gbére.
Ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi gbẹ̀mí obìnrin méjì l’Ekoo
Àwọn obìnrin méjì ní ìpínlẹ̀ Eko lánàá pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó wáyé ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹfà, oṣù Keje , ọdún 2022.
Gíwá àgbà àjọ tó ń mójútó ètò ìrìnnà ojú omi ní ìpínlẹ̀ Eko, Oluwadamilola Emmanuel tó fi ọ̀rọ̀ náà léde nínú àtẹ̀jáde kan ní kò pẹ́ púpọ̀ tí ọkọ̀ ojú omi náà gbéra tó fi dànù.
Emmanuel ni àwọn mẹ́ẹ̀dógún nínú àwọn mẹ́tàdínlógún tó wọ ọkọ̀ ojú omi náà ni àwọn rí yọ ní ààyè.
Ó ṣàlàyé wí pé ní nǹkan bí ago mẹ́jọ kú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún òwúrọ̀ ọjọ́rú ni ọkọ̀ ọkọ̀ ojú omi “R &N 2” tó kó èrò mẹ́tàdínlógún ní pápákọ̀ omi Ipakodo ní Ikorodu ṣà dédé dànù sómi.
Ó ní lẹ́sẹ̀ kan ni àwọn òṣìṣẹ́ ààbò àwọn débẹ̀ tí wọ́n sì dóòlà ẹ̀mí àwọn èrò inú àwọn mẹ́tàdínlógún tó wà nínú ọkọ̀ náà ṣùgbọ́n àwọn méjì tó jẹ́ obìnrin tó wà nínú rẹ̀ pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí wọ́n fi máa dé ilé ìwòsàn.

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Àwọn méjì tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ kò wọ aṣọ ìdáàbòbò wọn
Emmanuel ní àwọn obìnrin méjéèjì tó lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ oju omi náà kò wọ aṣọ ìdáàbòbò èyí tí àwọn máa ń pèsè fún ẹnikẹ́ni tó bá wọ ọkọ̀.
Ó ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn wí pé àwọn olóògbé náà kò wọ aṣọ náà láti fi dá ààbò bo ara wọn nígbà tí wọ́n wọ inú ọkọ̀.
Ó ṣàlàyé wí pé àwọn máa ń ṣàrídájú pé àwọn tó bá fẹ́ wọ inú ọkọ̀ wọ aṣọ náà ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé nígbà tí àwọn obìnrin ọ̀hún wọnú ọkọ̀ wọn ni wọ́n bọ jù sílẹ̀.
Bákan náà ló fi kun pé ọkọ̀ ojú omi náà bàjẹ́ lásìkò tó wà lórí ìrìnàjò ló fà á tó fi dànù.













