Ìpalẹ̀mọ́ ọjọ́ Arafah, ìmọ̀ràn mẹ́wàá rèé láti lè mú Hajj rọrùn f'álálàhájì

Aworan awọn alalaaji

Ọjọ Arafah jẹ ọjọ pataki fun awọn alalaaji to wa ni Hajj bayi ni Saudi.

Bi eeyan ko ba kopa ninu ọjọ gẹgẹ bi awọn onimọ ẹsin ti ṣe fi kọwa, iru eeyan bẹẹ ko ni laada pe o kopa ninu Hajj.

Ọjọ yi ninu Hajj 2022 yoo bọ si Ọjọru.

Fun awọn musulumi to wa nile, ipalẹmọ ti wọn de ọjọ yoo waye nipasẹ gbigba awẹ.

Fun awọn to n kopa ninu Hajj, ki ni nkan ti wọn yoo ṣe ati pe iru ipalẹmọ wo lo yẹ ki wọn maa fi ṣe igbaradi de ọjọ nla yi?

Mina ni irinajo yoo ti kọkọ bẹrẹ

Aworan tẹnti MIna

Oríṣun àwòrán, SAHUC Hajj

Bẹrẹ lati ọjọ kẹjọ oṣu Dhul Hajj ni wọn yoo ti bẹrẹ si ni ko awọn Hujjaj lọ si aaye kan ti a n pe orukọ rẹ ni Mina.

Alalaaji yoo ti gbe aṣọ fun harami wọ ti eyi si tunmọ si pe wọn ti wọ ipo hajj.

Ni aaye yi, awọn ile ibusun tẹnti ni awọn alalaaji yoo sun si ni ipalẹmọ de kikopa ninu ijọsin Arafah.

Koko pataki ni pe ki awọn to ba n lọ si Mina ma ṣe di ẹru pupọ lọwọ.

Aṣọ harami wọn ni ọpọ yoo wọ lọ sibẹ ti wọn ko si ni di bag to wuwo.

Lẹyin nkan eelo bi burọọṣi ifọnu, ọṣẹ iwe,aṣọ ti eeyan yoo wọ lẹyin to ba bọ aṣọ haraami silẹ ati igbanu ti wọn yoo fi di owo ati foonu wọn si, kii si aaye pupọ ni Mina lati fi gbe ẹru si.

Tori naa, ma ṣe gbe ẹru pupọ lọ si Mina.

Ibusun awọn alalaaji ni Mina

Oríṣun àwòrán, Khidmatul Awaam Pilgrim Services

Ounjẹ ati ohun mimu

Alalaaji ko nilo lati di ounjẹ lọwọ.

Awọn ajọ eleto alalaaji yoo maa gbe ounjẹ wa loore koore.

Bi ounjẹ yi ko ba si to, awọn sọọbu kekeeke ati ile ounjẹ naa wa ni ayika Mina.

tso ṣe pataki lati mu omi daada nitori oru a maa mu ni Mina.

Wọn pese awọn ẹrọ amuletutu ninu awọn tẹnti ṣugbọn kii da oru yi duro.

Baluwẹ naa wa ni tosi nibi to ti le wẹ oogun kuro lara.

Ero maa n pọ to fẹ lo baluwẹ nitori naa suuru ṣe pataki lasiko yi.

Bi eeyan ba ti gbe aṣọ haraami wọ, wọn kii j tabi sọrọ odi si alalaaji.

Aworan ounjẹ fawọ́

Owurọ kutu ni wọn yoo ko alalaaji lọ si Arafah

Aworan aaye Hajj

Oríṣun àwòrán, SAHUC Hajj

Lọpọ igba, awọn eleto alalaaji yoo ti fi to awọn alalaaji lati mura silẹ de igba ti wọn yoo bẹrẹ si ni gbe wọn sọkọ lọ si oke Arafah.

Eleyi le bẹrẹ lati owurọ kutu titi di igba ti irun asuba yoo fi to.

Pupọ yoo ti bẹrẹ si ni gberal ninu ọkọ lati nkan bi ago mejila si ago kan oru.

Nitori pe ero pọ, ti gbogbo ọkọ yoo si maa lọ si oju kanna ni wọn fi n tete bẹrẹ eto yi.

Bi eeyan ba si ti de si aaye tẹnti rẹ ni Arafah, ko si nkan meji ju ki o bẹrẹ si ni ṣe adura si Allah.

Aaye iwẹ́, aluwala ati igbọnsẹ wa ni ayika Arafah.

Ma ṣe oju kokoro lati di ounjẹ ati ẹru lọwọ

Aworan oke Arafah

Oríṣun àwòrán, National Hajj Commission of Nigeria

Aṣiṣe kan ti ọpọ to n kopa ninu hajji maa n se ni pe wọn a maa du ounjẹ ni ọjọ Arafah.

Awọn ọlọdanni ati eleto hajji maa n gbe ounjẹ, aburanda ohun mimu ati awọn nkan ẹbun miran wa fun awọn alalaaji.

Fun awọn to ba ro pe ọfẹ ni awọn nkan yi jẹ ti wọn si di igba di agbọn,inira leleyi yoo jẹ nigba ti wọn ba pari ni Arafah ti wọn dari si Muzdalifah

Awọn alalaaji to n sun si Muzdalifah

Oorun alẹ mọjumọ ni Muzdalifah

Ni nkan bi irọlẹ lawọn alalaaji yoo pari ijọsin ni oke Arafah.

Bi wọn ṣe fi ọkọ gbe wọn wa, bẹẹ naa ni wọn yoo fi ọkọ gbe wọn pada.

Kaka ki wọn pada si Mina ni ibusun wọn, agbegbe Muzdalifah ti o wa ni itosi ni wọn yoo lọ.

Ita gbangba ni aaye Muzdalifah yi jẹ ti ko si si ile ibusun nibẹ.

Pupọ lo maa gbe ẹni kekere dani ti wọn yoo fi sun sibẹ mọjumọ.

Ẹni to ba di ẹru pupọ lọwọ yoo koju ipenija ibi ti yoo gbe si tabi bi yoo ṣe di lọwọ to ba kuro ni Muzdalifah.

Oorun alẹ kan ṣọṣo mọju ni eeyan yoo sun nibi.

Bi illẹ b si ti mọ, pipada si Mina lo ku.

Oko sisọ ni Jamraat

Awọn to baa n dari pada lati Muzdalifah lanfaani lati lọ si Jamrah lọ sọ okuta ti wọ́n ba ṣa ni Muzdalifah.

Oko sisọ yi jẹ afihan bi Anọbi Ibrahim ti ṣe sọ oko lu Shaytan nigba to n ko si lọkan pe ko ma mu adehun fifi ọmọ rẹ Ismail rubọ ṣẹ.

Awọn okuta yi kii ṣe okuta to tobi.

Eeysn yoo ṣa wọn lọwọ yoo si lo si aaye ti wọn n pe ni Jamraat lati sọ akọkọ ninu abala mẹta ti yoo sọ.

Lọpọ igba awọn alaṣẹ maa n sọ igba ti awọn alalaaji yoo lọ sọ oko yi.

Ki wọduwọdu baa ma ṣẹlẹ si ni wọn ti fi eto si.

Rii wi pe akoko ti wọn ba ni ki awọn alalaaji ipinlẹ rẹ lọ sọ oko ni ko lọ bi bẹẹ kọ, o le koju ipenija lilọ bibọ si aaye Jamraat.