Ọ̀pọ̀ ènìyàn pàdánù àǹfàní láti ṣe Hajj 2022

Hajj

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Kò dín ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àwọn tó fẹ́ lọ sí Saudi Arabia ní ọdún yìí láti lọ ṣiṣẹ́ Hajj ló ṣeéṣe kí wọ́n má ríbi lọ bí ó ṣe kú ọjọ́ kan tí ìjọba Saudi yóò gbé ilẹ̀kùn rẹ̀ tì pa.

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Keje ní àjọ tó ń mójútó ètò Hajj ṣíṣe ní Nàìjíríà, NAHCON, kéde wí pé ìjọba Saudi ti fún Nàìjíríà ní àǹfàní ọjọ́ méjì si láti kó àwọn tó fẹ́ ṣiṣẹ́ Hajj wọlé.

Èyí túmọ̀ sí wí pé kíkó àwọn tó fẹ́ ṣe Haj wọ Saudi tó yẹ kó wá sópin ní ọjọ́ Ajé ni wọ́n ti sún sí ọjọ́rú.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn yìí fi àwọn kan lọ́kàn balẹ̀ láti ṣì tún lè kópa níbi Hajj ọdún yìí síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ti fẹ́ lọ fojú kan sàárè ànọ́bí láti ọdún 2020 ni ó ṣeéṣe kí wọ́n tún má ribi lọ ní ọdún yìí.

Ní báyìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ ló ti ń dá àwọn ènìyàn rẹ̀ tí kò rí bi kó lọ sí Hajj padà nítorí àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan.

Lára àwọn ìpèníjà tí wọ́n ń kojú ni wí pé àwọn owó tó yẹ kí àwọn tó ń mójútó iṣẹ́ Hajj ní Saudi kò rí owó tó yẹ kí wọ́n fi pèsè físà, oúnjẹ àti ibùgbé fún àwọn tó fẹ́ ṣe Hajj.

Bí NAHCON ṣe ti sọ wí pé àwọn ti san owó náà sí akoto owó Saudi ni Saudi ní àwọn kò rí owó kankan tó sì ṣokùnfà ìdí tí àwọn ènìyàn kò fi rí bi lọ sí Hajj.

Àwọn ènìyàn 150 ni kò ríbi lọ Hajj ní ìpínlẹ̀ Oyo

Àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìnàjò lọ sí Saudi

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Kò dín ní àádọ́jọ ènìyàn tí kò ní rí bi kópa nínú ètò Hajj ọdún yìí ní ìpínlẹ̀ Oyo nítorí wọn kò rí físà gbà ní orílẹ̀ èdè Saudi.

Alága àjọ tó ń mójútó ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ tẹ̀ka mùsùlùmí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Sayed Malik nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní abala àwọn tó kẹ́yìn láti lọ sí ilẹ̀ mímọ́ náà ti balẹ̀ sí Jedda ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun.

Malik ṣàlàyé wí pé àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà yàtọ̀ sí àádọ́jọ tí Saudi kò fún ní físà, gbogbo àwọn tó kù ló ti balẹ̀ sí Saudi láti ṣiṣẹ́ Hajj wọn.

Bákan náà ló ní gbogbo àwọn tí kò ríbi lọ sí Hajj ọdún yìí tó bá fẹ́ gba owó wọn padà ní gómìnà Seyi Makinde ti pàṣẹ wí pé kí àwọn dá owó wọn padà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Àmọ́ ó ní àwọn tí kò bá gba owó wọn padà ní àwọn yóò kọ́kọ́ dá lóhùn ní ọdún tó ń bọ̀ àti pé wọn kò ní fi kún owó tí wọ́n máa san lọ́dún tó ń bọ́ rárá.

Àwọn tó ń lọ sí Hajj

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ní ìpínlẹ̀ Bauchi ẹ̀wẹ̀, àádọ́jọ ènìyàn náà ni kò ní àǹfàní láti ṣe Hajj ọdún yìí bí àwọn náà kò ṣe rí físà gbà.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, akọ̀wé àgbà àjọ tó ń mójútó ìrìnàjò Hajj ní ìpínlẹ̀ Bauchi, Abdurrahman Idris ní àwọn àádọ́jọ tí NAHCON ṣe àdéhùn fún àwọn láti kó lọ ni kò bọ́ si mọ́.

Idris pàrọwà sí àwọn tí kò ríb lọ náà láti gbà á gẹ́gẹ́ bí àmúwá Ọlọ́run àti wí pé ó ní òhun tí Ọlọ́run fi ṣe.

Ó ni àwọn ti fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà láti fi wọkọ̀ padà sílé kóówá wọn.

Hajj

Bákan náà ni ọmọ ṣe sorí fún àwọn àádọ́jọ mìíràn ní ìpínlẹ̀ Niger.

Àwọn ènìyàn tó fẹ́ ṣe ìrìnàjò lọ sí Saudi ni kò rí físà nítorí kò sí orúkọ wọn lórí ẹ̀rọ àwọn tó ti sanwó ní ìpínlẹ̀ náà.

Àjọ Hajj ìpínlẹ̀ náà ní àwọn ti ń ṣèwádìí gbogbo àwọn ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ń fi sùn.