Wo àwọn èèyàn tí wọ́n ti n kí àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré ní Olu Jacobs kú oríire ọjọ́ ìbí ọgọrín ọdún.

Oríṣun àwòrán, @NAN
Opọlọpọ eto ni awọn eeyan ti n sọ nipa rẹ lori ayelujara lati sami ayẹyẹ ọjọ ibi ogbontarigi oṣere ni Olu Jacobs.
Ọgọrin ọdun ni Oloye Olu Jacobs yoo pe lori oke eepe lọjọ kọkanla, oṣu keje, ọdun yii.
Opọ awọn oṣere asiko yii lo n yombo agba ọjẹ oṣere ni ori ayelujara.
Bakan naa ni Joke Silva to jẹ aya agba osere naa, ṣafihan okọ rẹ ni ọpọlọpọ ọdun seyin to si fi akọle sii pe: “Ta ni o le sọ orukọ arẹwa ọdọmọkunrin adumaadan yii tó fẹ pe ẹni ọgọrin ọdun lori oke eepẹ yii.....”
Bakan naa ni Femi adebayo naa ni oun bu ọla fun agba ọjẹ to n ṣayẹyẹ orikadun ọgọrin ọdun laye.
O ni Baba Olu Jacobs bni imọlẹ ti ọpọ ọdọ osere fi n riran ninu iṣẹ ọna bayii. Adura pe ki Oba Oke da Olu Jacobs si tiletile lo tun gba.

Oríṣun àwòrán, @Olu Jacobs
Ni afikun, Jide Kosoko naa ti ki Olu Jacobs ku ayéyé orikadun yii.
Saheed Balogun naa ki Olu Jacobs pe: ‘ Igba ọdun ọdun kan fun eekan to tobi julọ lagbo oṣere, Baba Olu Jacobs, a mọ riri yin pupọ’
Mustapha Sholagbade naa ni pe: E ku oriire ọgọrin ọdun Sir, Inu Olodumare a dun si ọlọjọ ibi. Mo gbadura fun okun ati agbara sii lasiko yii fun Babab wa.
Ileeṣẹ iroyin Naijiria sọ pe ọdun 1942 ni wọn bi Olu Jacobs.
O ti ṣe ọpọlọpọ ere sẹyin lori amohunmaworan ati ninu fiimu agbelewo.
Opó lo gbagbọ pe Oloye Olu Jacobs ni afara to so awọn agba oṣere papọ mọ awọn ọdọ osere lasiko yii.












