Àwọn 17 tó ń díje du ipò ààrẹ ní Naijiria rèé
2023 Presidential Election: Ohun tó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa àwọn olùdíje fún ipò ààrẹ ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Google
Ẹgbẹ oṣelu mẹtadinlogun ninu mejidinlogun to fi orukọ silẹ fun idibo sipo aarẹ ni ọdun to n bọ.
Ẹgbẹ oṣelu Action Peoples Party, APP nikan ni ko fi orukọ oludije silẹ nitori gbedeke Ọjọ Kẹsan an, Oṣu Kẹfa ti Ajọ Eleto Idibo ni Naijiria, INEC fun wọn.
Nibayii, ẹni ti yoo jẹ igbakeji wọn ni awọn araalu n reti ki wọn yan gẹgẹ bi ofin Naijiria ṣe wi.
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu – APC
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu to jẹ ọkan gboogi ninu awọn oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, jẹ ọmọwe onimọ nipa eto iṣiro ọrọ aje ati adari ẹgbẹ oṣelu APC lati igba ti wọn ti da silẹ ni ọdun 2013.
Bola Tinubu ti fi igba kan jẹ gomina ipinlẹ Eko lati ọdun 1999 si 2007.
Ọkan lara awọn orukọ ti awọn eniyan ma n pe ni Jagaban ati pe oun ni Baba isalẹ eto oṣelu ni ipinlẹ Eko ati Guusu Ariwa Naijiria.
Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Oṣu Kẹta, ọdun 1952 ni wọn bi Tinubu ni ipinlẹ Osun.
Ẹlẹsin Musulumi ni Tinubu, to si jẹ ọkọ Arabinrin Olurẹmi Tinubu to di ipo sẹnatọ gbungun aarin ipinlẹ Eko mu.
Tinubu di oye Aṣiwaju ti ipinlẹ Eko mu ati Jagaban ti ilu Borgu ni ipinlẹ Niger, lorilẹede Naijiria.
Ileẹko alakọbẹrẹ St. John's Primary School, Aroloya, ni ipinlẹ Eko ati ileẹkọ Children's Home School ni Ibadan ni Tinubu lọ.
Lẹyin naa lo lọ si orilẹede Amẹrika ni ọdun 1975, nibi to ti lọ kawe ni ileẹkọ Richard J. Daley College ni Chicago, Illinois, ko to ṣẹṣẹ wa lọ si ileẹkọ giga Chicago State University.

Oríṣun àwòrán, @Tinubu
Nibẹ lo ti kẹkọ jade ni ọdun 1979 nipa imọ Accounting.
Ọdun 1992 ni Tinubu bẹrẹ iṣẹ oṣelu lẹyin to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party nibi ti awon oloselu bii Shehu Musa Yar'Adua, Umaru Yar'Adua, Atiku Abubakar, Baba Gana Kingibe, Rabiu Kwankwaso, Abdullahi Aliyu Sumaila, Magaji Abdullahi, Dapo Sarumi atiYomi Edu.
Labẹ ẹgbẹ oṣelu naa lo ti lọ si ile igbimọ aṣofin agba lati ṣoju ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Eko.
Lẹyin ti wọn wọgile idibo aarẹ ti 12 June 1993 ni Tinubu oludasilẹ ẹgbẹ oṣelu National Democratic Coalition to n pe fun ijọba alagbada ati pe ki gbogbo agbaye gba pe Moshood Abiola lo bori ninu idibo sipo aarẹ ni Ọjọ Kejila, Oṣu Kẹfa.
Tinubu sa asala fun ẹmi rẹ ni ọdun 1994 nigba ti Ọgagun Sani Abacha fi ipa gbajọba.
Amọ Tinubu pada si Naijiria ni ọdun 1998 lẹyin iku Abacha, eleyii to bẹrẹ ijọba tiwantiwa Fourth Republic.
Ni ọdun 2006, Tinubu gbiyanju lati jẹki Atiku Abubakar wa si ẹgbẹ oṣelu Action Congress lati wa dije du ipo aarẹ tako ọga rẹ, Olusegun Obasanjo nigba naa lọhun. Amọ Atiku fidi rẹmi ti ẹgbẹ oṣelu PDP si gbegba oroke.
Lẹyin idibo ọdun 2009 naa ni Tinubu bẹrẹ ijiroro lori ati gbe egbe alatako to lagbara dide tako ẹgbẹ oṣelu APC, eleyii ti abajade rẹ jẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ni ọdun 2013.
Ni ọdun 2014 ni Tinubu ṣe atilẹyin fun Muhammadu Buhari to ti dije du ipo aarẹ ni ọdun 2003, 2007, ati 2011 ko to bori ninu idije naa.
Tinubu kọkọ fẹ du ipo igbakeji aarẹ amọ o fi silẹ fun Yemi osinbajo to jẹ eniyan tirẹ ati kọmisọna fun eto idajọ, nipinle ̣Eko .
Lati ọdun 2015 titi di asiko yii ti ẹgbẹ oṣelu APC ti n ṣejọba ni Asiwaju ti n kopa ribiribi lati ripe ẹgbẹ naa tẹsiwaju.
Amọ ni Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Kini, ọdun 2022 ni Tinubu fi lede pe oun fẹ dije du ipo aarẹ Naijiria, ti o si fitọ aarẹ Muhammadu Buhari leti.
Alhaji Atiku Abubakar - PDP
Ogun ọdun ni Atiku fi ṣiṣẹ ni ileeṣẹ to n risi ọrọ ibode ni Naijiria ko to di ọga patapata, to si fẹyinti ni ọdun 1989. Lẹyin naa lo darapọ mọ iṣẹ ara tirẹ ati iṣẹ oṣelu.
Lati igba to ti darapọ mọ oṣelu ni ọdun 1989, lo ti n dije du ipo aarẹ amọ ti ko bosi.
Igba marun lo si ti du ipo aarẹ to fi mọ ọdun 1993, 2007, 2011, 2015 ati ọdun 2019.
Ni ọdun 1993 lo dije labẹ ẹgbẹ oṣelu SDP to si kuna amọ ti Moshood Abiola bori.
Labẹ ẹgbẹ oṣelu Action Congress lo ti dije du ipo ni ọdun 2007, nigba ti o dije du ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ọdun 2011, ki o to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC ni 2015,to si kuna.
Ọdun 2017 ni Atiku pada si PDP, lati dije du ipo aarẹ ni ọdun 2019 to si tun kuna, amọ to tun ti gbegba idije fun ipo aarẹ ni ọdun 2023.
Ogun ọdun ni Atiku fi ṣiṣẹ ni ileeṣẹ to n risi ọrọ ibode ni Naijiria ko to di ọga patapata, to si fẹyinti ni ọdun 1989.
Lẹyin naa lo darapọ mọ iṣẹ ara tirẹ ati iṣẹ oṣelu.
Christopher Imumolen – AP
Ọjọgbọn Christopher Imumolen lo n dije du ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Accord Party, AP.
Ipinlẹ Edo ni agbegbe Esan West, Ekpoma lo ti ṣẹ wa.
Onimọ nipa eto ẹkọ ati oniṣowo ni Imumolen to si ka iwe gboye onimọ nipa Engineering Research ati Educational Management pẹlu Mechanical Engineering.
Imumolen ni idi ti oun fi darapọ mọ idije fun ipo aarẹ ni ọdun 2023 ni pe oun gbagbọ wi pe orilẹede Naijiria nilo adari tuntun nitori ko si ohun to n gberu si ni Naijiria nitori aisi adari.
Hamza Al Mustapha (AA)
Ọgagun Hamza Al-Mustapha ni olori ẹṣọ alaabo fun adari orilẹede Naijria tẹlẹ, Sani Abacha.
Orisiri ipo lo si di mu ni ileeṣẹ ikọ ọmọogun Naijiria pẹlu imọ pipe nipa ẹṣọ aabo.
Ọdun 1998 ni wọn yọ kuro ni ipo lẹyin iku Abacha, ti wọn si fi ẹsun ipaniyan kan wọn.
Amọ ni ọdun 2010 ni wọn dajọ pe wọn ko jẹbi ẹsun ipaniyan, amọ wọn ko yọ ti ẹsun pipa Kudirat Abiola.
Ni ọdun 2012 ni wọn kede pe o jẹbi ẹsun ipaniyan Kudirat Abiola, pẹlu aṣẹ pe ki wọn yẹgi fun un. Amọ ni ọdun 2013 ni wọn kede pe ko jẹbi ẹsun naa mọ.
Ni ọdun 2017 ni Al-Mustapha darapọ mọ oṣelu to si dije du ipo labẹ ẹgbẹ oṣelu Green Party of Nigeria to dasilẹ.
Lẹyin naa lo tun dije du ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Party of Nigeria ni ọdun 2019.
Yabagi Sani – ADP
Oludije ni ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party , ADP ni Yabagi Sani.
Ni Bida lo ti bẹrẹ ẹkọ alakọbẹrẹ ni ọdun 1961, ko to lọ si Technical College, Kontagora ni ọdun 1970.
Lẹyin naa lo lo si ileẹkọ giga Harvard University ni UK, Columbia University ni Newyork naa.
Ileeṣẹ Petroleum Products Marketing Company (PPMC) depot, Kano, labe Nigerian National Petroleum Corporation (NNPC) lo ti kọkọ bẹrẹ iṣẹ ni ọdun 1980, ki o to darapọ mọ oṣelu ni ọdun 1991.
Omoyele Sowore – AAC
Adari ileeṣẹ Sahara Reporters, Omoyele Sowore ni oludije ni ẹgbẹ oṣelu African Action Congress ni ọdun 2023.
Ki o to darapọ mọ oṣelu Naijiria lo ti jẹ ajafẹtọ ati ajijagbara fun awọn akẹkọọ lati ọdun 1989.
Ọpọlọpọ igba ni Ajọ Eleto aabo ni Naijiria, DSS ti ti mọle fun ẹsun dida omi alaafia orilẹede ru nipa awọn ifẹhọnuhan ti o ma n ṣe adari fun kaakiri orilẹede Naijiria.
Oṣu Keji, ọdun 2018 ni Sowore kede pe oun fẹ dije du ipo aarẹ ni ọdun 2019, to si da ẹgbẹ tirẹ silẹ, African Action Congress to ti n dije dupo.
Dumebi Kachikwu (ADC)
Dumebi Kachikwu to jẹ aburo minisita fun ọrọ epo rọọbi ni Naijiria tẹlẹ, Ibe Kachikwu lo n dije dupo lẹyin ti Kingsley Moghalu fidirẹmi ninu idibo abẹle naa.
Odun 1970 ni won bi, o darapo mo egbe oselu ADC ni odun 2020, to si je adari ati oludasile Roots Television.
Kachikwu ni ti won ba di ibo yan oun, oun yoo fi opin si ipaniyan ati igbesunmomi ni Naijiria.
Peter Umeadi (APGA)
Oludije lẹgbẹ oṣelu All Progressives Grand Alliance (APGA), Justice Peter Umeadi (rtd), ni Olootu eto idajọ ni ipinlẹ Anambra ni Ọjọ Kini, Oṣu Kẹta, ọdun 2019.
Ni Oṣu Kẹrin lasiko to n ba awọn oludibo sọrọ ni oun gan an ni ibo aarẹ Naijiria tosi ni ọdun 2023.
Yusuf Mamman Dantalle (APM)
Oludije ni ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement (APM), Yusuf Mamman Dantalle, lo jade lai dije du ipo.
Idi ni wi pe oun ni alaga ẹgbẹ ti ko si si ẹlomiran to jade lati figagbaga pẹlu rẹ.
Amọ ni Oṣu Kẹta, ọdun yii ni ẹgbẹ naa ni ki Dantalle lọ joko si ile lori ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan oun ati akọwe ẹgbẹ, Oyedeji Adebayo.
Amọ Dantalle ṣapejuwe igbesẹ naa bi ohun ti ko le kẹsẹjari.
Sunday Adenuga (BP)
Ko si iroyin nipa arakunrin Sunday Adenuga to n dije du ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Boot Party (BP) ni Naijiria.
Ipinlẹ Ogun lo ti ṣẹ wa to si jẹ oniṣowo.
Peter Obi (LP)
Oniṣowo ati oloṣelu Peter Obi to n dije du ipo labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party.
Ki o to di asiko yii, o dije du ipo igbakeji aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ọdun 2019.
Oun ni gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ lati Oṣu Kẹta,ọdun 2006 si Oṣu Kọkanla, ọdun 2006 kan naa, ki wọn to yọ kuro ni ipo.
Amọ Obi pada si ipo ni ọdun 2007, ti wọn si tun idibo miran ṣe ni June 14, 2007, to si wọle.
Wọn tun dibo yan an gẹgẹ bi gomina ni ọdun 2010.
Amọ Oṣu Karun un, ọdun 2022 lo fi ipo rẹ silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lẹyin ti o kuna lati gbegba oroke gẹgẹ bi oludije, to si lọ si Labour Party, ti wọn ti gba a wọle gẹgẹ bi oludije fun ipo aarẹ.
Okwudili Nwa-Anyajike (NRM)
Oludije fun ipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu National Rescue Movement (NRM), Okwudili Nwa-Anyajike, ti jẹ ko di mimo fun awọn ọmọ Niajiria pe erongba oun ni lati da orilẹede Niajiria pada si ipa iṣerere.
Rabiu Musa Kwankwaso (NNPP)
Rabi’u Musa Kwankwaso darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP), ni ọdun 1992, ti wọn si dibo yan an gẹgẹ bi aṣoju ni Ile Igbimọ Aṣofin to n ṣoju ẹkun Madobi.
Lẹyin naa lo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Democratic Party of Nigeria (DPN) lasiko iṣejọba Ọgagun Sani Abacha.
Ọdun 1998 ni Kwankwaso darapọ mọ PDP, to si jẹ gomina ipinlẹ Kano ni May 29, 1999 si May 29, 2003, to tun wọle pada ni ẹlẹẹkeji ni ọdun 2011.
Ni ọdun 2013 lo yapa kuro ni PDP lọsi APC, amọ to kuna ninu idibo abẹle fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu naa.
Ni ọdun 2018 ni Kwankwaso pada si PDP amọ to tun fidirẹmi ni idibo abẹle sipo oludije aarẹ ni ẹgbẹ naa, eleyii ti Atiku Abubakar bori.
Amọ ni February 22, 2022 ni o lọ da ẹgbẹ tuntun kalẹ, New Nigeria Peoples Party, to si bori gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu naa.
Kola Abiola (PRP)
Kola Abiola to jẹ ọmọ MKO Abiola lo lọ si fasiti Colorado State University, nibi to ti kọ ẹkọ imọ eto iṣuna (Bachelor’s degree in Finance and MBA in Business Administration. )
O pada si Niajiria to si da ileẹkọ University Staff School, Akoka silẹ, lasiko ti iya rẹ jẹ olukọ ni ileẹkọ YabaTech.
Kola Abiola naa lo bori gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Redemption Party (PRP).
Adewole Adebayo (SDP)
Oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP), Adewole Adebayo,jẹ agbẹjọro ati oludasilẹ KAFTAN Television.
Ni January 15, 2022, ni Adebayo kede pe oun fẹ dije du ipo aarẹ orilẹede Naijiria.
Malik Ado-Ibrahim (YPP)
Oludasilẹ ẹgbẹ oṣelu Reset Nigeria Initiative, Malik Ado-Ibrahim ni oludije fun ipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu Young Progressives Party (YPP).
Orilẹede Naijria ni wọn ti bii amọ o kẹkọ gboye ni orilẹede Amẹrika ati Ilẹ Gẹẹsi.
Lọwọlọwọ oun ni adari ileeṣẹ NIGUS International ati alaga ileeṣẹ NEXT Satellite TV Ltd, ti yoo ma pese iṣẹ fun awọn ọdọ ni ẹka ICT ati ẹka idaraya ni Naijiria.
Ipinlẹ Kogi ni Ado-Ibrahim ti wa, to si jẹ ọmọọba Ohinoyi ti ile Ebira.
O ni fun idagbasoke orilẹede Naijiria, ọrọ ẹsin ati ẹlẹyamẹya gbọdọ di ohun igbagbe.
Dan Nwanyanwu (ZLP)
Dan Nwanyanwu ni oludije si ipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party (ZLP), ati alaga ẹgbẹ naa
Ni abẹ iṣakoso rẹ ni Labour Party ni wọn ti gba ipo gomina ni ipinlẹ Ondo labẹ akoso Oluṣegun Mimiko.
Ọdun 2015 lo kuro ni Labour Party to si lọ da ZLP sile.












