Àwọn gómìnà ilẹ̀ Yoruba kéde ọ̀fọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta lẹ́yìn ìkọlù tó mú ẹ̀mi èèyàn 40 lọ nílùú Owo

Àwọn gómìnà ilẹ̀ Yoruba ṣe ìpàdé pàjáwìrì lórí ọ̀rọ̀ àbò

Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, Kayode Fayemi

Lọna ati fi ifẹ han si awọn eeyan ipinlẹ Ondo lẹyin ikọlu to waye nile ijọsin St Francis Catholic Church, Owo, awon gomina ilẹ Yoruba ti kede ọjọ mẹta lati fi ṣọfọ awọn eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ibanikẹdun naa yoo bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, si ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, asia orilẹ-ede Naijiria ni gbogbo ọọfisi ijọba ipinlẹ Ekiti ati lawọn agbegbe to lamilaaka yoo wa ni aarin fun gbogbo ọjọ mẹta ti wọn fẹ fi ṣọfọ naa.

Awọn gomina ilẹ Yoruba ṣe ipade pajawiri

Lẹyin ikọlu naa lawọn gomina ipinlẹ Ondo, Ogun, Oyo, Osun, Eko ati Ekiti ṣe ipade pajawiri kan lori eto abo lawọn ipinlẹ wọn.

Ninu atẹjade kan lẹyin ipade ọhunh, awọn gomina naa fẹnuko pe asiko ti to fun awọn lati ṣe gbogbo ohun to yẹ lati fopin si iṣẹ awọn agbesumọmi lagbegba awọn.

Atẹjade naa ni “A ti pinnu nibi ipade ti a ṣe lati ṣe awọn ohun to yẹ lati daabo bo awọn eeyan ati dukia awọn ti a n ṣe ijọba le lori.”

“A ti wa fẹnuko lati ṣe afikun bi a ṣe n ṣọ ayika ati agbegbe wa lati ṣawari awọn atọhunrinwa to n gbe laarin wa amọ ti a ko da mọ.”

“Awọn gomina naa, gẹgẹ bii ẹṣọ alabo akọkọ ni ipinlẹ wọn ti fẹnuko lati ṣe iranlọwọ to yẹ fun awọn agbofinro lagbege wọn fun abo to peye.”

“Bẹẹ naa ni wọn tun sọrọ lori bi awọn ọlọkada ti ṣe gba gbogbo oju popo ati bi wọn yoo ṣe yanju wahala awọn ọlọkada ọhun.”

Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, Kayode Fayemi

Ẹmi ogoji eeyan sọnu

O kere tan, ẹmi ogoji eeyan lo sọnu ninu ikọlu naa to waye lọjọ Aiku, ọjọ karun un, oṣu Kẹfa ti a wa yii.

Ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede naijiria, to fi mọ awọn eekan mii kaakiri agbaye lo ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa si awọn olujọsin.

Amọ titi di asiko yii, ko si ẹgbẹ kankan to tii sọ pe awọn lo wa nidi ikọlu naa bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ Naiiiria ni awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi ISWAP lo ṣe iṣẹ laabi naa.