Èrèdí tí mi ò ṣe ní ìbò kankan níbi ètò ìdìbò abẹ́nú APC l’Abuja rèé - Bakare
Tunde Bakare ṣàlàyé èrèdí tó ṣe fìdírẹmi nínú ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Oríṣun àwòrán, Pastor Tunde Bakare
Pasitọ ijọ Citadel Global Community, Tunde Bakare, ti ṣalaye eredi ti ko ṣe ri ibo kọkan nibi eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC lati yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu eto idibo Aarẹ ọdun to n bọ.
Lasiko to n ba awọn ọmọ ijọ rẹ sọrọ niluu Eko, o ni awọn eeyan kọ lati dibo yan oun nitori oun kọ lati ṣe awọn ohun ti ko tọ.
Ọjọ kẹfa si ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa yii ni eto idibo abẹnu naa waye ni gbagede Eagles Square niluu Abuja.
Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Asiwaju Bola Tinubu lo gbegba oroke ninu eto idibo abẹle naa pẹlu ibo 1,217.
Minisita fun eto irinna tẹlẹ, Rotimi Amaechi ni ibo 316 nigba ti igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yemi osinbajo ni ibo 235.
100 milioọnu owo fọọmu laisi ibo kọkan
Awọn ti ko ni ibo kọkan ni pasitọ Tunde Bakare, gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, Rochas Okorocha, minisita eto iroyin tẹlẹ, Ikeobasi Mokelu ati oniṣowo, Tein Jack-Rich.
Bo tilẹ jẹ pe ọgọrun miliọnu naira ni awọn eeya naa fi ra fọọmu eto idibo abẹnu ọhun lati le dije du ipo Aarẹ, wọn ko ni ibo kọkan.
Nigba to n sọrọ niwaju awọn ọmọ ijọ rẹ lọjọ Aiku, ṣe ni awọn ọmọ ijọ naa duro lori ẹsẹ wọn ti wọn si bu iyi fun Bakare.
Bi a ko tilẹ ni ibo, a ko ja kulẹ
Bakare sọ niwaju awọn ọmọ ijọ rẹ pe “A ko mikan nitori a ko ṣe ohun ti o lodi si orilẹ-ede Naijiria tuntun ti a fẹ kọ, eyii lo ṣe pataki si wa julọ.
“Eredi ree ti oju ko ṣe ti wa pe a ko ni ibo kọkan, nitori a ko lọwọ si ohun ti ko tọ nidi eto oṣelu.”
Bakare tun sọ niwaju awọn ọmọ ijọ naa pẹlu igboya pe oun ṣi ni yoo di Aarẹ lọdun 2023.
O ni “Inu iwe Daniel 4:17 ni ireti wa wa.”
Lẹyin naa lo ki Bola Tinubu ku oriire fun aṣeyọri rẹ ninu eto idibo abẹnu ọhun, to si tun tẹnumọ pe “Emi ni yoo di Aarẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2023.”












