Ọ̀nà tí a lè fi san oore fún àwọn tó fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ fún ìjọba àwarawa ni láti lé APC kúrò lórí oyè - Atiku

June 12: Atiku, Tinubu, Lawan àtàwọn èèkàn mì sọ̀rọ̀ sókè

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, @atiku

Lonii, ọjọ Aiku, to jẹ ayajọ ọjọ iranti June 12, ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti n fi ọrọ lede nipa pataki ayajọ ọjọ naa.

Ṣaaju ni Aarẹ Mumhammadu Buhari ti kọkọ ba awọn araalu sọrọ, leyii to jẹ ọrọ ayajọ June 12 ti yoo sọ kẹyin gẹgẹ Aarẹ Naijiria.

Buhari sọ pe oun yoo ri daju idibo yiyan Aarẹ tuntun lọdun 2023 ko ni mu itajẹsilẹ lọwọ.

O fi kun pe oun yoo tun ri daju pe ojutaye ni wọn yoo ṣe igbese bi oun yoo ṣe gbe ijọba kalẹ fun Aarẹ to n bọ laifi nkankan pamọ fun ara ilu.

Yatọ si Aarẹ Buhari, awọn eekan ilu mi tun ti sọrọ lori ayajọ June 12 ọdun yii.

Ki ni Atiku sọ?

Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar sọ pe ọna kan gboogi lati fi ẹmi imoore han si awọn to fi ẹmi wọn lelẹ fun ijọba awarawa ni Naijiria ni lati le ẹgbẹ oṣelu APC kuro lori oye.

Gẹgẹ bii ohun ti Atiku sọ, ijọba APC to wa lode ti mu gbogbo nnkan le koko bi oju ẹja fun awọn araalu.

O ni ayajọ Jun 12 ti ọdun 2022 yii ṣe pataki nitori oun ni yoo ṣaaju eto ibibo gbogbogbo ọdun 2023, awọn araalu si gbọdọ lo ọjọ naa lati mọ awọn ohun ti wọn n fẹ lọwọ ijọba.

Atiku sọ pe “Asiko yii lo yẹ ki awọn araalu lọ forukọsilẹ lati dibo, wọn ko si gbọdọ sọ ireti nu.”

“Amọ o ti han gbangba pe ijọba Buhari ko ṣe awọn ọmọ Naijiria ni anfaani kankan, eredi ree ti wọn fi gbọdọ le ijọba APC kuro lorui oye lọdun to n bọ.”

Awọn ọmọ Naijiira gbọdọ gba idajọ ododdo ati alafia laaye – Ahmed Lawan

Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Ahmed Lawan naa ti sọrọ lori ayajọ ọjọ June 12 ti 2022.

O ni ọjọ naa kii kan n ṣe ọjọ kan ṣa, amọ o jẹ ọjọ ti awọn ọmọ Naijiria gbọdo mọ ibi ti wọn n lọ gẹgẹ bi orilẹ-ede.

Lawan sọ pe awọn ọmọ Naijiria gbọdọ maa ṣe ohun ti yoo ṣe awọn ẹnikeji wọn lanfani.

O ni “O yẹ ka mọ pe eto oṣelu awarawa jẹ eyii ti ọpọ eeyan ti wọn ni erongba to yatọ si tiwa maa n da si, nitori naa a ni lati bọwọ fun ẹtọ awọn ẹlomiran.

“Bẹẹ ni a gbọdọ gba idajọ ododo ati alaafia laaye laarin ara wa.”

Ẹ ma ṣe sọ ireti nu, nnkan ṣi maa dara – Tinubu

Ẹwẹ, oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Tinubu ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati ma sọ ireti nu nitori nnkan ṣi maa pada bọ sipo.

Ninu ọrọ ikini ayajọ June 12 to fi lede, o ni Naijiria ṣi maa bori gbogbo iṣoro to n koju gẹgẹ bii eto oṣelu awara ṣe bori ijọba ologun ni Naiiiria.

Tinubu ni eto idibo June 12 fi han pe eto idibo to lọ wọrọwọ le waye ni Naijiria gẹgẹ bo ṣe n ṣelẹ lawọn orilẹ-ede to ti goke agba lagbaye.