Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ṣe ìwọ́de tako lílo íbọn bó ṣe wù wón ní US
March For Our Lives: Ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn ṣe ìwọ́de tako lílo íbọn bó ṣe wù wón ní US

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹgbẹgbẹrun awọn afẹhọnuhan ni ilẹ Amẹrika lo pejọ lati pe fun ki ijọba gbogun ti lilo ibọn lọna itọ nibẹ.
Awọn to n ṣe ifẹhọnuhan naa ni wọn gbe kaadi dani lorisirisi pẹlu akọle to n pe fun gbigbegi dina lilo ibọn ni ọna aitọ.
Wọn ni ki ile aṣofin ṣe agbekalẹ ofin ti yoo dahun kiakia si ibeere wọn.
Bakan naa ni aarẹ Joe Biden buwọlu awọn afẹhọnuhan naa, ti ohun naa si n pe fun oun ti wọn fẹ.
Amọ oṣeeṣe ki awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican ma gba si awọn ifẹhọnuhan.
Ni Ọjọ Kẹrinlelogun, Oṣu Karun un ni agbebọn kan ṣina bolẹ , to si pa awọn ọmọ wẹẹrẹ ni Robb Elementary ni Uvalde, Texas.
Ki eleyii to waye naa ni agbebọn ni Buffalo, New York naa wọ ile aja to si pa eniyan mẹwa.
Awọn ajafẹtọ yii pẹlu akọle ‘’March for our lives’’ ni wọn gbe ifẹhọnuhan to le ni irinwo kalẹ,kaakiri orilẹede Amerika.
Awọn afẹhọnuhan naa ni awọn ko ni gba awọn oloṣelu laaye lati ba aye wọn jẹ.
Wọn ni aibikita awọn oloṣelu ni ilẹ naa n sọ aye wọn di ahoro pẹlu bi awọn agbebọn ṣe n pa wọn ni ipakupa.












