A kò ní ṣe ayẹyẹ ọdún June 12 nítorí ìkọlù tó wáyé nílùú Owo - Akeredolu

Owo attack

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu

Ijọba ipinlẹ Ondo ti wọgile ayẹyẹ ọdun “June 12” ti ọdun 2022 nitori ikọlu awọn agbesumọmi si ile ijọsin St Francis Catholic Church niluu Owo.

Gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu lo kede ọrọ naa loju opo ayelujara Facebook ati Twitter rẹ.

O ni “A ti wọgile ayẹyẹ iranti June 12 ti ọdun yii lati bọwọ fun awọn ti ẹmi wọn sọnu nibi ikọlu to waye ni ijọ Aguda St Francis, to wa niluu Owo, nipinlẹ Ondo.”

“A gbe igbesẹ lati wọgile ayẹyẹ naa ki awọn eeyan ipinlẹ Ondo le ri ọna ati ṣedaro awọn mọlẹbi wọn ti wọn ba iṣẹlẹ naa lọ.”

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Mi o faramọ ọrọ ijọba ijọba apapọ pe ISWAP lo kọlu Owo - Akeredolu

Ẹwẹ, Akeredolu ti kọkọ bu ẹnu atẹ lu ijọba apapọ lẹyin ti wọn kede pe awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi ISWAP lo wa nidi ikọlu naa.

O ni ko bojumu to bi ijọba apapọ ṣe di ẹbi ikọlu naa le ISWAP lori lai fi ẹri to munadoko kin ọrọ naa nidii.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Akeredolu, Richard Olatunde fi lede, o ni awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi ọhun yoo ti sọrọ soke to be jẹ pe lootọ awọn lo wa nidi ikọlu ọhun.

Gomina naa ni “Mi o gba ọrọ naa wọle pe ISWAP lo kọlu ilu Owo nitori ISWAP kii dakẹ lẹyin ti wọn ba ṣe ikọlu tan.”

 “To ba jẹ pe lootọ ISWAP lo ṣe ikọlu si Owo, wọn yoo ti funrere ohun ti wọn ṣe fun araye gbọ.”

“A ko tii mọ awọn to ṣiṣẹ ibi naa, amọ awọn agbofinro wa ti n tọpinpin awọn to ṣisẹ laabi naa.”

Gẹgẹ bii ohun ti Akeredolu sọ, Naijiria nilo ọlọpaa agbegbe ki eto abo rẹ le munadoko.

O pari ọrọ rẹ pe oun n gbiiyanju lati tan iṣoro eto abo pẹlu ikọ Amotekun amọ o loju ibi ti Amotekun le ṣe iṣe de nitori wọn ko ni awọn ohun ija ogun igbalode.