Nnamdi Kanu: Wo ìdí tí ilé ẹjọ́ gíga Abuja ṣe dá ẹ̀sùn mẹ́jọ nù nínú mẹ́ẹ̀dógún tí wọ́n fi kan Nnamdi Kanu

Ile ẹjọ giga nilu Abuja ti wọgile mẹjọ ninu ẹsun mẹẹdogun ti wọn fi kan Nnamdi Kanu eyi to rọ mọ igbesunmọmi.
Awọn ẹsun taa n wi yi wa lara awọn ẹsun tuntun ti ijọba Naijiria fi kun eleyi ti wọn ṣaaju fi kan olori ikọ ajijagbara IPOB.
Adajọ Binta Nyako to gbe idajọ yi kalẹ sọ pe fawọn ẹsun lati ẹlẹkẹẹfa dori ikọkanla ti wọn gbe wa siwaju ile ẹjọ, wọn ko ribi fẹsẹmulẹ pe afurasi naa daran kankan.
Amọ fawọn ẹsun kini de ori ẹkarun-un ati ẹsun ikẹtala ati ikẹẹdogun, wọn ribi fẹsẹ mulẹ.
Awọn ẹsun mẹẹdogun ti wọn gbe wa si ile ẹjọ da lori igbesunmọmi ati iditẹmọjọba. O si ti sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun yi.
Bakan naa ni adajọ gbe idajọ kalẹ pe bi wọn ṣe ji Kanu gbe lati ṣe iwadii ko si laburu.

O ni ṣaaju ni iwe ipẹjọ ti wa lori Kanu nitori o ṣa mọ ile ẹjọ lọwọ.
Amọ niṣe ni agbẹjọro rẹ tẹnumọ pe wọn tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ labẹ ofin agbaye ni pẹlu bi wọn ṣe ji gbe lati ilẹ mii wa si Naijiria lọdun to kọja.
Wọn ti sun igbẹjọ Kanu titi di ọjọ Kẹtadinlogun, ikejidinlogun ati ọjọ Kẹrindinlọgbọn lati wa dahun si awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Igbẹjọ oniduro rẹ forisanpọn nitori adajọ wọgile pe ki wọn gba beeli rẹ.
Eleyi jẹ nkan ti ko tẹ agbẹjọro rẹ lọrun to si sọ fawọn akọroyin pe ile ẹjọ kuna lati wọgile beeli onibara rẹ.
Ijọba gbé ìlànà tuntun jáde fún ìgbẹ́jọ́ àwọn agbesùnmọ̀mí bí Nnamdi Kanu ṣe ń farahàn nílé ẹjọ́ lónìí
Ijọba orilẹede Naijria ti ṣagbejade awọn ilana tuntun ti ile ẹjọ yoo maa lo bayii fun igbẹjọ nikẹni ti wọn ba ti fi sun igbesunmọmi kan ni ile ẹjọ giga.
Gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade kan ti alamojuto iroyin ni ile ẹjọ giga ti Naijiria, Catherine Oby Christopher fi sita, ilana tuntun naa sọ pe awọn oniroyin ko ni lanfani lati maa royin ohun to ba n lọ ninu ile ẹjọ mọ ayafi bi adajọ ba fun wọn laṣẹ.

"Awọn adajọ nikan, agbẹjọro atawọn ti ọrọ kan nikan ni aye yoo gba ki wọn wọ ile ẹjọ bẹẹ si ni eto abo to ṣe gbagba yoo wa nilẹ lasiko ti igbẹjọ naa ba n lọ lọwọ".
Ninu oṣu keji dun yii to farahan niwaju ile ẹjọ, ohun to ṣẹlẹ niyi ti Iléẹjọ́ tún sún ìgbẹ́jọ́ olórí ẹgbẹ́ IPOB Nnamdi Kanu síwájú.

Atẹjade naa sọ wipe wọn ko ni gba ki awọn araalu ni anfani kankan lati sunmọ ile ẹjọ.
Ikede yii n waye lẹyin to ku ọjọ kan ki igbẹjọ adari ikọ awọn to n ja fun Biafra (IPOB), Nnamdi Kanu tsiwaju ni Abuja lonii.
Ni ọjọ Ẹti, ile ẹjọ giga ilu Abuja yoo joko lori gbigbọ ẹjọ awọn ẹsun ti wọn fi kan Kanu eyi to ni ṣe pẹlu igbimọditẹ mọ ijọba ati igbesunmmi.
Awọn ilana mii to wa ninu atẹjade naa ni wipe:
- Wọn ko ni fi oju awọn ba wa jẹri nile ẹjọ tabi afurasi han mọ.
- Alaye nipa bi ẹnikẹni ṣe le mọ wọn yoo farasin nitori aabo wọn.
- Ẹnikẹni to ba tapa si ofin to wa ninu alakal yii "yoo di wipe o ti huwa ọdaran" to si lodi si ofin orilede to nii ṣe pẹlu igbesunmọmi.
Atẹjade naa tun fi kun un pe Adajọ agba ile ẹjọ giga ilu Abuja n reti lati ṣe igbẹjọ adari ẹgbẹ to n ja fun ominira Biafra, Nnamdi Kanu ni ọjọ Kẹjọ oṣu Kẹrin ọdun 2022.
- Wo ǹkan tí o kò mọ̀ nípa ESABOD tí òun àti Lizzy Anjorin jọ ń fi omi èpè wẹ ara wọn
- Ǹkan ọmọkùnrin rẹ ńgbálẹ̀ kiri, gbogbo ìlú ló wà fún; Gbas gbos tún bẹ̀rẹ̀ láàrin Tontoh dike àti olólùfẹ́ rẹ̀
- "Mo sá fún oògùn owó, igbó mímu, mo tún ní sùúrù fún ọdún 15 kí n tó di olókìkí"
- Ó bọ́ mọ́ Wizkid, Femi Kuti, Burna Boy lọ́wọ́ ní Grammy Awards, wo àwọn tí wọ́n jọ figagbága
- Tí ẹ̀yin ará ìpínlẹ̀ Ọyọ bá fẹ́, ó wù mí láti ṣèjọba ní ọdún mẹ́rin míràn síi - Seyi Makinde
















