Sunday Igboho: Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Arewa ní àwọn aláìmọ ló ń bẹnu àtẹ lú DSS àti DIA lórí ààbò Nàìjíría

Oríṣun àwòrán, NNAMDI KANU AND SUNDAY IGBOHO
Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Arewa ní
Awọn ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan kan ti n fesi pada fun awọn akẹgbẹ wọn miran, lori ọrọ to ni se pẹlu bawọn ileesẹ amofinro ni Naijiria se kunju osuwọn si.
Igun ajafẹtọ ẹni labẹ ẹgbẹ ọdọ Arewa lẹkun ariwa Naijiria lo, sọ ninu atẹjade kan pe ko tọ si awọn kan lati maa foju yẹpẹrẹ wo ẹka aabo Naijiria.
Gẹgẹ bi wọn ti se sọ, wọn ni mimu Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu safihn pe awọn osisẹ to wa lẹka aabo Naijiria munadoko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Baba Suwe ti kú tipẹ́ ṣaájú kí gbogbo èèyàn tó mọ̀ - Àbúrò olóògbé
- Kí ló ń dá ọlọ́pàá dúró láti gbé Rahmon Adedoyin àti ọmọ rẹ̀ relé ẹjọ́ lórí ikú Timothy Adegoke?
- Bàyìí ni èmi àti Abdulsalami ṣe ṣiṣẹ́ pọ̀ ba èròngbà sáà kẹta Obasanjo jẹ́ - Thabo Mbeki
- Èèmọ! Kí ló mú àwọn akẹ́kòó gírámà fìkanra dá bàǹtẹ́ ìyà fún DPO ọlọ́pàá l‘Ogun?
- Ìdí rèé ta ṣe fi pósí gbe Baba Suwe tó jẹ́ Mùsùlúmì - Aya rẹ̀ àkọ́fẹ́ ṣàlàyé
- Èròngbà ìjọba Naijiria lórí yíyọ 'subsidy' rújú, a kò fara mọ̀-NLC
- Ẹ wo ẹni tó ń jẹ́ Suwebatu nínú ẹbí Baba Suwe àti ohun tó sọ nípa olóògbé
Ni paapa, wọn darukọ ẹka ileesẹ alaabo ọtẹlẹmuyẹ Department of State Security ,DSS ati Defence Intelligence Agency(DIA) gẹgẹ bi eleyi to duro daada.
''O jẹ iyalẹnu fun wa pe awọn alainikanse ti wọn ko mọ ju ki wọn parọ lọ n bẹnu atẹ lu ipa ribiribi ti ajọ DSS ati DIA n ko ni Naijiria''
''Awọn ajọ wọn yii jẹ eleyi to munadoko, ti a le fi safiwe akẹgbẹ wọn nilẹ mii bi FBI, CIA ati KGB. Ki eeyan ni wọn o kaju osunwọn dabi ko da ẹsẹ didoju ija kọ orileede yii ni''
Awọn ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan naa wa gbosuba kare fawọn DSS ati DIA, ti wọn si ni o jẹ iyalẹnu awọn pe awọn ọmọ Naijiria yoo foju kere isẹ ribiribi ti wọn se ati bi wọn se fẹmi wọn lelẹ lati fi daabo bo Naijiria.
''Gbogbo ẹnu la fi sọ pe bi wọn se mu Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu ati mimu awọn mii naa to fẹ da omi alaafia ilu ru, tọka si pe awọn akọsẹmọsẹ lo wa lẹka aabo Naijiria taa n wi yi''
Wọn ni awọn ọmọ Naijiria ko ni gbagbe bi agbegbe ilẹ Igbo ti se jẹ ibi ti awọn ọdaran ti gbode.
''Idibo Gomina nipinlẹ Anambra ko waye afigba ti awọn ologun ati DSS balẹ sibẹ, ti wọn si le awọn alaburu danu ti alaafia si jọba.
Isẹ daada ree, to si tọ ka gbosuba kaare fun wọn dipo ka maa bẹnu atẹ lu wọn''.


















