Thabo Mbeki: Ààrẹ South Africa nígbà kan sọ ipa tó kó nígbà tí Obasanjo fẹ́ ṣe sáà kẹta

Abdulsalami Abubakar ati Thabo Mbeki

Oríṣun àwòrán, AFP

Aarẹ orilẹ-ede America nigba kan, Thabo Mbeki sọ peoun ati olori ijọba Naijiria tẹẹ, Abdulsalami Abubakar, jọ ṣiṣẹ tako erongba saa kẹta fun Olusegun Obasanjo ni.

Ẹo ranti pe nigba to n ku diẹ ki saa keji Obasanjo pari, ni wọn gbe aba kan lọ siwaju ile aṣofin pe ko ṣe atunṣe si ofin Naijiria, lati faaye saa kẹta gba aarẹ.

Mbeki, lasiko to n sọrọ nibi eto ijiroro kan nilu Abuja latori ayelujara, sọ ipa to ko pẹlu Abubakar lati tako erongba naa lasiko ijọba Obasanjo.

O ni lẹyin ti oun pe Obasanjo lori ẹrọ ibanisọrọ, lati fi aidunnu oun han si àbá yii, oun tun darapọ mọ Abubakar lati dasi titako atunsẹ ofin.

O ni "lọdun 2005, ipolongo kan bẹrẹ ni Naijiria lati ṣatunṣe iwe ofin ko le fi aaye saa mẹta gba awọn aarẹ.

Àkọlé fídíò, Baba Suwe: Aya àkọ́fẹ́ olóògbé ṣàlàyé bí àkókó ìkẹyìn ọkọ́ rẹ̀ ṣe rí

"Nigba ti mo gbọ nipa igbesẹ yii, mo ba Obasanjo sọrọ lati jẹ ko mọ pe mi o faramọ. Ni kẹhin, mo tun jiroro pẹlu Abubakar, a si jọ fẹnuko pe ko dara rara.

"A jọ fi ohùn ṣọkan pe ipa ti ko dara ni yoo ni ni Naijiria, ati gbogbo ilẹ Africa, paapaa fun eto iṣejọba awaarawa ti a ṣẹṣẹ bẹrẹ nigba naa."

Mbeki ni oun rọ Abdulsalami lati ma a fi bi nkan ba ṣe n lọ lori atunṣe ofin naa.

"Inu mi si dun nigba to pada pè lati sọ fun mi pé awọn aṣofin ti dibo tako aba naa.