Petroleum Subsidy Removal: Afenifere bu ẹnu àtẹ́ lu èròngbà ìjọba láti sọ lítà epo di ₦340

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ awọn agbaagba nilẹ Yoruba, Afenifere ti bu ẹnu ẹtẹ lu erongba ijọba apapọ lati sọ lita kan epo bẹntiro di ₦320 tabi ₦340 lọ́dún 2022.
Ni Ọjọru ni ileeṣẹ epo rọbi ni Naijiria, NNPC ta awọn araalu lolobo pe o ṣeeṣe ki wọn maa ra lita epo bẹtiro n ọọdunrun le logun si ọọdunrun le ni ogoji Naira lẹyin ti ijọba ba ti yọ owo ajẹmọnu ori epo kuro.
Amọ, ninu atẹjade to fi sita, Afenifere ni erongba ijọba aarẹ Muhammadu Buhari lati fowo kun owo epo fihan pe ijọba rẹ ko nani igbayegbadun araalu.
- Ẹ màá múra sílẹ̀ láti ra lítà epo kan ní ₦320 sí ₦340 lọ́dún 2022- NNPC
- Ìrìn-àjò Baba Suwe pẹ̀lú àjọ NDLEA lórí bó ṣe ''yàgbẹ́ tì'' ní àtìmọ́lé
- "Màá pa màálù fún ọ, ọmọ mi Khadija, tí mo bá rí ọ gbà padà lọ́wọ́ ajínigbé"
- Ọmọ tuntun tí wọ́n bá lórí pẹpẹ ṣọ́ọ́ṣì gba orúkọ tuntun
- "Lẹ́yìn ti mo lo ọdún 42 lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n tú mi sílẹ̀ pé ń kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn"
- Bàbá mi máa ń sunkún torí bí kò ṣe le padà ṣeré tíátà mọ́ - Ọmọ Baba Suwe
- Clem Ohameze, òṣèré tíátà ní àìlera, ó ń bẹ̀bẹ̀ àdúrà lórí iṣẹ́ abẹ
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Tówẹ́ẹ̀lì ni bàbá mi ró mọ́ ìdí nígbà tí àwọn sọ́jà wọlé mu lọ - Ọmọ Akintunde
- Jàndùkú kọlù mi, gé mi lára bíi olè torí mo jẹ́rìí tako ìjọba níbi ìwádìí ìpànìyàn Endsars Lekki''
Afenifere sọ ninu atẹjade ti akọwe iroyin ẹgbẹ naa, Jare Ajayi, buwọlu pe afikun owo epo lọdun 2022 ko le bimọ ire fun Naijiria.
Ajayi ni awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lapapọ yoo gunle iyanṣẹlodi kaakiri eleyii ti yoo ṣe akoba fun eto oṣelu ati ọrọ-aje Naijiria.
Ẹgbẹ naa wa rọ ijọba Buhari lati maa tẹsiwaju lori erongba rẹ lati ṣe afikun owo epo bẹntiro.
Afenifere sọ pe awọn araalu gan an ko le gba ijọba to wa lode yii gbọ lori ileri rẹ lati maa fun wọn lowo diẹdiẹ lẹyin to ba ṣe afikun owo epo tan.
Akọwe iroyin ẹgbẹ Afenifere sọ pe awọn ọmọ naijiria ko le gba ijọba gbọ mọ nitori o ti ṣe iru ileri bẹẹ sẹyin ti ko mu un ṣẹ.
Kọmureedi Ajayi ni kilode ti ijọba fẹ yọ owo iranwọ ori epo lẹgbẹ to ṣeleri lati ṣe atunṣe awọn ile ifọpo rọbi ti orilẹede Naijiria.
''Ati pe kii ṣe asiko ti ile ifọpo aladani maa to bẹrẹ iṣẹ lo yẹ ki ijọba tun sọ pe oun fẹ ṣe afikun owo epo ni Naijiria.
Kilode ti ijọba ko le duro ki awọn ileeṣẹ ifọpo bẹrẹ si ni ṣiṣẹ ki o le yọ owo iranwọ ori epo?
Ọrọ owo iranwọ ori epo rọbi ti pẹ, ṣugbọn ko yẹ ki ijọba maa loo lati fiya jẹ awọn araalu.
Ijọba gbọdọ ṣe atunṣe awọn ileeṣẹ epo rọbi ki wọn bẹrẹ si ni ṣiṣẹ pada ki o to maa sọ nipa afikun owo epo,'' Kọmureedi Ajayi lo sọ bẹẹ.

Ẹ màá múra sílẹ̀ láti ra lítà epo kan ní ₦320 sí ₦340 lọ́dún 2022- NNPC
Ileesẹ to n risi pipọn epo rọbi ni Naijiria NNPC ti ta araalu lolobo pe o seese ki wọn ra jala epo bẹntiroo ni ọọdunrun le logun si ọọdunrun le ni ogoji Naira bẹrẹ lati osu keji ọdun to n bọ.
Ọga agba ileesẹ naa Mele Kyari lo sọ ọrọ yi to si ni idẹkun ti ijọba se lori epo ko ni si mọ bẹ́rẹ lati ibẹrẹ ọdun 2022.
O ni bi kii ba se fun awọn idiwọ kọọkan wọn ko ba ti yọ ''subsidy'' lati ọdun taa wa ninu rẹ yi.
- Wo kókó márùn-ún nípa òfìn tuntun lórí eporọ̀bì tí Buhari buwọ́lù àti bó sẹ kàn ọ́
- Ilé ẹjọ́ ju Àfáà tó ń gbé àwọ̀ Femi Adesina wọ̀ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 28, ó tún pàdánù dúkìá
- A kò da iṣẹ́ sílẹ̀ mọ́, ó di ọjọ́ míì, ọjọ́ re - IPMAN, PTD
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Kò sí ìfẹ̀míṣòfò kankan ní Lekki Too Gate, àlọ́ àpamọ̀ lásán ni èsì ìgbìmọ̀ EndSARS - Lai Mohammed
- Rúdurùdu nílé aṣòfin l‘Ogun, Igbákejì olórí ilé ní wọ́n lo ayédèrú ìbuwọ́lù òun láti gbé ₦50m jáde
Amọ sa o ni ijọba n gbero idẹkun ẹgbẹrun marun un Naira fawọnogoji miliọnu ọmọ Naijiria lasiko ti wọn ba yọ ẹdinwo inu epo bẹntiroo.
Nilu Abuja lọga NNPC yi ti fi ọrọ naa sita lasiko ipade apero osu kọkanla ajọ banki agbaye.
Amọ sa ẹgbẹ osisẹ Trade Union Congress,TUC ti fi ikilọ sita fun ijọba lati ma se da yọ tabi dawọ ẹdinwo epo tara ilu n gbadun.
O ni awọn ko ni fẹlẹ gba yiyọ ẹdinwo yi lalai se awọn ohun ti osisẹ́ beere lọdọ ijọba.
Kyari ninu alaye ti rẹ sọ pe ''ko ni si ipese fun labẹ ofin sugbọn o yẹ kẹ mọ riri pe ojuse ijọba pọ lati mu idẹkun ba awọn alaini lawujọ nitori naa a o gbe ilana ti yoo rọrun lati yọ ẹdinwo yi wa''
O ni ko si aniani pe wọn ko ni yọ ẹdinwo yi ni 2022 nitori ofin Naijiria ti de igbesẹ yi.
O salaye pe jala epo bẹntiroo yoo wa laarin ọọdunrun le logun si ọọdunrun le ni ogoji Naira.
Ẹwẹ Gomina ipinlẹ Kaduna Nasir El-Rufai ti fi ifarajin awọn Gomina han lati gbaruku ti ijọba lori igbesẹ yiyọ ẹdinwo subsidy yi.
Ninu alaye rẹ, El Rufai sọ pe bi awọn ko ba yọ ẹdinwo yi,marundinlogoji si mẹrindinlogoji awọn ipinlẹ ni ko ni le san owo osu osisẹ lọdun to n bọ.Gẹgẹ bo ti se sọ, Kerosiini ti o se pataki sawọn araalu ko ni owo ẹdinwo lori ti ko si mu wahala wa.
O ni bẹẹ naa lo ri pẹlu disuu fawọn osisẹ awako arinrinajo.
''Gbogbo ariwo lori bẹntiroo yi jẹ nkan ta gbọdọ fẹnu ko si ka si yanju rẹ .A ko le maa pese bẹntiroo fawọn orileede alabagbe wa nitori nkan taa n se lọwọ ni yẹn.''
''Ki lo de ta fi n se eleyi?Nitori ta la fi n se?Ta lo n jẹ anfaani rẹ?Awọn wo lo n jere nidi rẹ tori naa ki lo de ti wọn fi fẹ jẹ eto ọrọ aje Naijiria run?''
O tẹsiwaju pe Naijiria n padanu owo to to ojilenigba le mẹwaa Naira losoosu nitori ẹdinwo o si gbọdọ de opin.Awa ijọba ipinlẹ setan lati gbaruku ti ijọba apapọ lori yiyọ ẹdinwo yi''
Ki ni TUC sọ lori ọrọ yiyọ ''Subsidy''
Ẹgbẹ osisẹ TUC naa fi ikilọ sita lọjọ Isẹgun si ijọba lati ma se danikan gbe igbesẹ yiyọ ẹdinwo lọdun to n bọ lai fi ti awọn se.
Wọn ko lawọn ko tako yiyọ ẹdinwo yi.
Wọn ni bi ijọba ba gbe igbesẹ yi lai fi tawọn se awọn yoo tako wọn.
Aarẹ ẹgbẹ yi,Quadri Olaleye, gẹgẹ bi iwe iroyin Naijiria the Nation se jabọ sọ pe iyalẹnu lo jẹ pe ijọba fẹ yọ ẹdinwo lopin igba ti igbimọ ti wọn gbe kalẹ ko ti pari isẹ lori rẹ.
Losu Keji ọdun yi ni igbimọ yi se ipade kẹyin ti awọn to sju ijọba si beere fun asiko si lati se ijiroro pẹlu awọn ẹgbẹ osisẹ.
O ni lati igba naa ijọba apapọ ko ti pe ipade miran lori ọrọ yi.













