Femi Adesina: Ilé ẹjọ́ ju ẹni tó n gbé àwọ̀ Femi Adesina wọ̀ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 28, ó tùn pàdánù dúkìá

Alfa Jamiu ati Femi Adesina

Oríṣun àwòrán, femi adesina/nigerian tribune

Ọ̀gà fi aṣọ ti ẹ silẹ, o n da aṣọ alaṣọ bora.

Ọrọ yii gan-an lo ti sọ Alfa kan, Jamiu Isiaka, deero ẹwọn bayii nipinlẹ Kwara, nitori pe o n gbe awọ ẹlomiran wọ.

Ọjọ Ọjọbọ ni Onidajọ Mahmud Abdulgafar, ti ile ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Kwara dajọ ẹwọn ọdun mejidinlọgbọn fun Isiaka nitori pe o n fi ara rẹ pe Femi Adesina, agbẹnusọ Aarẹ Muhammadu Buhari.

Ajọ EFCC lo gbe Alfa naa lọ sile ẹjọ ni ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa,ọdun 2019, fun ẹsun mẹrin to nii ṣe pẹlu pipe ara rẹ ni ẹlomii, jibiti, ati gbigba owo pẹlu irọ.

Wọn fi ẹsun kan Jamiu pe o n fi ara rẹ han gẹgẹ bi Ọgbẹni Femi Adesina, o tun pe ara rẹ ni Ọga Agba ajọ NNPC tẹlẹ, Maikanti Baru, lati lu ọmọ orilẹ-ede South Korea kan, Keun Sig Kim ni jibiti ọgbọn miliọnu Naira.

Àkọlé fídíò, 'Ìyà Muinat kú nígbà tó ń mu ọmú lọ́wọ́ ni èmí ìyà-ìyá rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀ kí ògiri kíláàsì tó wó pa á'

Jamiu sọ fun Sig Kim pe oun yoo baa gba iwe aṣẹ lati le maa ra epo rọbi ni Naijiria.

Amọ nigba ti wọn n fi ọrọ wa Jamiu lẹnu wo, o ni oun lo owo naa lati fi ṣe etutu fun ọkunrin naa ni.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun fi owo naa ra ẹyẹ igún, awọ eerin, agbari kiniun ati ẹdọ inaki fun etutu naa.

EFCC sọ pe ẹsun naa tako ofin iwa jibiti ti ọdun 2006.

Alfa Jamiu sọ pe oun ko jẹbi nigba ti wọn kọkọ gbe e lọ sile ẹjọ, amọ ko ri nkankan fi tako awọn ẹsun naa lasiko ti igbẹjọ n waye.

Àkọlé fídíò, Nàìjíríà kàn wà ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́

Onidajọ Abdulgafar sọ pe gbogbo ẹri ti EFCC ko wa sile ẹjọ fihan pe lootọ ni Jamiu jẹbi ẹsun mẹrin ti wọn fi kan an.

Eyi si lo mu ko dajọ ẹwọn ọdun meje fun ikọọkan awọn ẹsun naa.

Amọ, yoo ṣe ẹwọn naa papọ ni.

Bakan naa ni onidajọ naa tun sọ pe ki ijọba gbẹsẹ le awọn dukia kan ti wọn gba lọwọ Alfa Jamiu, eleyi to fi èrè jibiti naa ra.

Lara awọn dukia naa ni ile oni yaara mẹrin kan, ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla kan, Plasma TV kan, firisa, ẹrọ amunawa, ẹrọ to n fọ aṣọ ati ẹrọ amuletutu.