Aishat Adesina: Iléẹ̀kọ́ fásitì OAU dí títì pa lórí akẹ́kọ̀ọ́ tó gbẹ́mì mì ní iléwòsàn fásitì

OAU

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn alaṣẹ fasiti Obafemi Awolowo, OAU ti paṣẹ fun awọn akẹkọọ lati maa lọ si ile wọn ti wọn si ti ọgba fasiti naa.

Eyi ko ṣẹyin ifẹhọnu han to ṣẹyọ lẹyin ti ọkan lara awọn akẹkọọ, Aishat Adesina gbẹmi mi nitori aisan to ṣe arabinrin naa.

Awọn akẹkọọ faraya nitori pe wọn da ẹbi iku akẹkọọbinrin naa ru ileewosan fasiti OAU nitori aibikita wọn ni eto ilera akẹkọọ naa nigba to lọ si ileewosan ọhun fun iwosan.

Àkọlé fídíò, 'Ìyà Muinat kú nígbà tó ń mu ọmú lọ́wọ́ ni èmí ìyà-ìyá rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀ kí ògiri kíláàsì tó wó pa á'

Awọn akẹkọọ to fariga naa ni awọn oṣiṣẹ eto ilera naa ko naani ẹmi akẹkọọ, ti wọn si sọ wi pe kii ṣe igba akọkọ niyii ti iru iṣẹlẹ naa ma waye.

Amọ, awọn alaṣẹ fasiti naa ni awọn ti sa gbogbo ipa awọn lati ba awọn akẹkọọ to n fẹhonuhan naa sọrọ, amọ pabo lo jasi.

Wọn fẹsun kan awọn akẹkọọ naa pe wọn n da rudurudu silẹ loju popo pẹlu bi wọn 'se ti opopona Ibadan si Ifẹ to fi mọ opopona Ede is Ifẹ pẹlu, eleyii to da inira silẹ fun awọn arinrinajo.

Bakan naa ni awọn adari ileewe naa fikun un pe ifẹhonuhan yii yoo ni ipalara lori eto ilera wọn ati awọn araalu to n rin irinajo.

Wọn rọ awọn akẹkọọ lati fi ileewe naa silẹ ni asiko yii, ki wọn si gba alaafia laaye.

Awọn alaṣẹ ileewe naa fi da awọn akẹkọọ loju wi pe iwadii yoo bẹrẹ lori iku akẹkọọbinrirn naa lai yọ ẹnikẹni silẹ.

Ẹgbẹ akẹ́kọ̀ọ́ OAU wọ́dé tórí pé wọ́n ní iléèwòsàn kò bìkítà nípa ẹ̀mí akẹ́kọ̀ọ́ tó gbẹ́mìí mì

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni fasiti Obafemi Awolowo nilu Ile Ife, OAU ti fẹdun ọkan wọn han lori iku to pa ọkan lara wọn Aishat Adesina, tii se ẹni ọdun mẹrinlelogun.

Awọn akẹkọọ OAU to n se iwọde

Aishat Adesina yii lo jẹ akẹkọọ ọlọdun kẹrin ni ẹka imọ nipa ede ilẹ okeere, ti yoo si kẹkọọ jade ni ọdun yii amọ nitori aisan ti ko to nnkan, to mu ẹmi rẹ lọ lairotẹlẹ.

Atẹjade kan ti ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni fasiti OAU, eyi ti alukoro ẹgbẹ naa, Ogunperi Taofeek Olalekan (Tao) fọwọ si, lo sisọ loju isẹlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade naa ni Aishat lo wa lara ọpọ akẹkọọ to ti padanu ẹmi wọn nitori ailakasi awọn osisẹ eleto ilera nibudo ilera to wa ninu ọgba ile ẹkọ fasiti naa.

"O ba wa ninu jẹ pe ọkan lara ọmọ ẹgbẹ wa ni wọn tun n gbe oku rẹ lọ ba awọn ẹbi rẹ, nigba ti wọn n foju sọna si akoko ti yoo kẹkọ jade.

Àkọlé fídíò, Nàìjíríà kàn wà ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́

A ba n ransẹ ibanikẹdun sawọn mọlẹbi oloogbe yii amọ a ko le foju fo awọ̀n isẹlẹ to waye, eyi to mu ẹmi alaisi naa lọ, paapaa ipa ti ibudo iwosan fasiti naa ko."

Ẹgbẹ akẹkọọ naa ni iku Aishat kọ ni yoo jẹ akọkọ ti yoo waye nitori ailakasi awọn osisẹ ibudo ilera naa, ti iku akẹkọọ lati ọwọ wọn si ti n di lemọ-lemọ.

Ẹgbẹ akẹkọọ lọgba fasiti OAU wa n ke si awọn alasẹ ileẹkọ naa lati sewadi iku to pa Aishat, ki wọn si jẹ osisẹ ti aje naa ba si mọ lori niya to jopin.

"Awọn osisẹ yii lo kọ lati fun Aishat ni itọju kiakia to nilo amọ ti wọn wa ni ki wọn maa gbe lọ sile iwosan Seventh-Day nigba ti ẹmi ti fẹ bọ lẹnu rẹ tan.

Lai si iwadii to yẹ ni kiakia, awọn alasẹ ọgba fasiti OAU kan n fi ẹmi awọn akẹkọọ wọn sinu ewu ni, a ko si ni gba kẹ maa fi ẹmi wa ta kati, ka si maa ku bi adiẹ.

Àkọlé fídíò, Ààrẹ Buhari àti ìjọba rẹ̀ màá ń làágùn, ìyẹ́ àdiyẹ wọn ni kò jẹ́ kí ẹ mọ̀

Ẹ dakun, ẹ ma da eto idanwo to n lọ lọwọ ru - Awọn alasẹ fasiti OAU bẹ akẹkọọ

Wayi o, igbimọ alasẹ ile ẹkọ fasiti OAU ti kẹdun iku akẹkọọ naa, Aishat Adesina to jade laye nitori awọn arun aile foju ri kan to n ba finra.

Atẹjade ti alukoro ile ẹkọ fasiti naa, Abiodun Olanrewaju fisita salaye pe lootọ ni Aishat yọju sibudo ilera to wa lọgba ile ẹkọ naa, ti wọn si fun ni oogun pe ko tun pada wa.

Atẹjade naa ni Aishat pada wa sile iwosan naa lọjọbọ ana, ti wọn si ni ko tete maa lọ sile iwosan Seventh Day fun itọju to peye nibi to papa ku si.

Awọn alasẹ ile ẹkọ fasiti OAU wa ba awọn obi, ọrẹ ati akẹkọọ ẹgbẹ rẹ kẹdun lori iku aitọjọ to mu ẹmi alaisi naa lọ.

Bakan naa ni wọn rawọ ẹbẹ lati bu omi suuru mu lori isẹlẹ yii, ki wọn si mase fa wahala lati pagidina idanwo ilaji simẹsita to n lọ lọwọ.