Buhari lifts Twitter ban: Buhari fún ọmọ Naijiria lẹ́bùn ayẹyẹ òmìnira, ó gbẹ́sẹ̀ kúró lórí Twitter pẹ̀lú ìkìlọ̀

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad

Bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n ṣe ayẹyẹ ayajọ ominira ọdunkọkanlelọgọta ti orilẹede Naijiria gba ominira, Aarẹ Muhammadu Buhari ti gbẹsẹ kuro lori ofin to fi de Twitter.

Ni oṣu kẹfa ọdun 2021 yii ni ijọba kede pe oun ti fofin de lilo oju opo igbọrọkaye Twitter lori ohun ti ijọba pe ni aṣilo rẹ.

Buhari ni lootọọ ni Twitter wulo lati maa fi pin iroyin ni waranṣesa, ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria lo n lo lati huwa ọdaran.

Àkọlé fídíò, Nàìjíríà kàn wà ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́

Aarẹ Buhari ni ọpọ eeyan lo n Twitter lati gbe ayederu iroyin kiri nigba ti awọn mii n loo lati da ija ẹlẹyamẹya ati ija ẹsin silẹ.

''Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ọmọ Naijiria ni Twitter ti fun lanfani lati ba oriṣiiriṣii eeyan pade, ṣe owo ati anfani si iroyin yajo yajo.

Amọ, awọn iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Naijiria ti fihan pe awọn nkan n lo Twitter lati huwa ibajẹ lawujọ.

Eyi gan an lo jẹ ki ijọba gbẹsẹ le Twitter ni ọjọ karun un oṣu karun un ọdun 2021 ki ijọba le wa ojutuu si iṣoro to n koju Naijiria nipasẹ Twitter.

Mo ṣe agbekalẹ igbimọ to ba Twitter sọrọ lati jiroro lori ọna abayọ eleyii ti wọn jọ fẹnu ko lori rẹ.