Nigeria at 61: "October 1", tí a bá ń ṣépè fún àwọn olórí wà, ó máa bàjẹ́ síi ni, ẹ má ṣépè mọ́

Àkọlé fídíò, Nàìjíríà kàn wà ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́

Awọn ọdọ Naijiri ti fi ọjọ ayẹyẹ ominira Naijiria bu ẹnu atẹ lu ipo ti orilẹede naa wa ati bi awọn adari rẹ ṣe huwa.

Eyi waye gẹgẹ bi ọjọ kini oṣu kẹwa ṣe jẹ ọjọ to orilẹede naa kede ominira kuro lọwọ awọn oyinbo amunilẹru.

Ikọ BBC Yoruba yan lati ba awọn ọdọ Naijiria sọrọ lati mọ boya wọn ṣi nigbagbọ ninu orilẹede wọn ati pe boya wọn ṣi nigba gbọ pe awn lee di adari ọla ni Naijira.

"Nàìjíríà ò ní ọjọ íwájú tẹlẹ, Ọlọrun nìkan ni ọjọ iwaju wa". Ni idakeji ẹwẹ, ọdọ kan ti a fọrọ wa lẹnu wo ni "kò sígbà tí mi ò kí ń gbàdúrà fún Nàìjíríà. Kódà mo ṣi gbàdúrà fun Naijiria láàrọ yìí".

fun idi eyi, iha meji lo fi si gẹgẹ bi awọn ọdọ naa ṣe n fesi. O le ya ni lẹnu pe ireti eeyan kan ni ki gbogbo ọdọ tako iṣejọba aarẹ Muhammadu Buhari amọ awọn to ṣi nigbagbọ ninu ayipada rere Naijiria naa wa laarin awọn ọdọ.