BB Naija latest news: Ẹ bá wa bẹ̀ BB Naija kò bẹ̀rẹ̀ Big Mama nàá, mo ṣetán láti ṣí ara sílẹ̀ nítorí owó - Fali Werepe

Fali Werepe

Oríṣun àwòrán, Instagram/fali werepe

Ko sarugbo ni Ghana, ẹ ba awa naa ṣeto Big Mama Naija.

Gbajugbaja oṣere Yoruba, Modupe Johnson, ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Fali Werepe ti kesi awọn alamojuto ati olootu gbajugbaja eto amohunmaworan Big Broda Naija (BBN) pe ki wọn o ṣeto fun awọn mama agbalagba naa.

Eto BBN ni eto kan nibi ti awọn ọdọ ti ma n kopa lati figa-gbaga fun owo to to aadọrun miliọnu Naira.

Fali Werepe

Oríṣun àwòrán, Instagram/fali werepe

Bo tilẹ jẹ pe lọdọọdun ti eto naa ba waye ni oriṣiriṣi awuyewuye ma n waye, paapaa nipa awọn iwa 'ko tọ' bii ibalopọ to ma n waye lori rẹ.

Ṣugbọn ninu fidio kan to fi si ori ayelujara, Fali Werepe sọ pe ki wọn o da abala eto naa silẹ fun awọn Mama naa.

Àkọlé fídíò, Abiodun Duro Ladiipo, Moremi: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti 'remarry'

O ni oun ṣetan lati ṣe gbogbo nkan ti awọn ọdọ naa n ṣe lati ri owo gba.

"Ọrọ awọn to n ṣe Big Broda ti su mi. Aadọrun miliọnu Naira ti wọn fẹ ẹ gba yẹn pọ.

"Inu mi a dun ti wọn ba ṣe ti awa Big Mama, ma a le lọ sibẹ lati ri owo.

"Awọ ara mi mọ lolo daadaa, ma a ṣi gbogbo ara mi silẹ fun wọn ki wọn o mọ bo ṣe n lọ."

O ni ọrọ lori owo ni.

Àkọlé fídíò, Nàìjíríà kàn wà ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́