Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí mo wà rọ̀ mí lọ́rùn, ètò ìṣèlú ni ìpàdé mi pẹ̀lú Tinubu dálé lórí - Makinde

Oríṣun àwòrán, Others
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ṣe ìtẹnumọ́ rẹ̀ pé ẹgbẹ́ òṣèlú, Peoples Democratic Party, PDP rọ òun lọ́rùn, tí òun kò sì gbèrò láti fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀.
Makinde ló sọ èyí nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé tó ṣe pẹ̀lú Ààrẹ Tinubu ní Abuja lọ́jọ́bọ̀.
Pẹ̀lú bí ọ̀pọ̀ àwọn gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP ṣe ń fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ bọ́ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn, Makinde tẹnumọ pé òun kò ṣetán láti bọ́ sínú òṣèlú All Progressives Congress, APC.
Ó sọ pé àbẹ̀wò òun sí Ààrẹ Bola Tinubu kò dá lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú bíkòṣe ètò ìṣèlú èyí tó nííṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí kò sí nǹkankan ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú rárá.
"Ààrẹ Nàìjíríà kìí ṣe ààrẹ APC, ààrẹ gbogbo Nàìjíríà ni, ọ̀rọ̀ ìṣèlú sì ni à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níbí.
"Ọ̀rọ̀ ìṣèlú ni kókó ohun tí à ń sọ níbí."
Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lórí bóyá awuyewuye tó ń wáyé láàárín òun àti awọn èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP láìpẹ́ yìí ló ṣokùnfà ìpàdé tó lọ ṣe pẹ̀lú Tinubu àti pé bóyá ó fẹ́ bọ́ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣùgbọ́n Makinde sọ pé ibi tí òun wà rọ òun lọ́rùn.
Ó tẹmpẹlẹmọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ṣetán láti bá ààrẹ Tinubu ṣiṣẹ́ papọ̀ lórí àwọn nǹkan tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìlú síbẹ̀ ó ní ìfarajìn òun sí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò yẹ̀bá.
Makinde wòye pé Nàìjíríà nílò ẹgbẹ́ alátakò tó lágbára gidi fún ìṣèjọba àwaarawa tó dúró ire pàápàá bí orílẹ̀ èdè ṣe ń múra fún ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027.
"Ó ṣeéṣe kí ìṣẹ̀lẹ̀ tó nílò kí ẹgbẹ́ òṣèlú méjì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bá wáyé, kò ní jẹ́ APC tàbí PDP nìkan ló ń sọ̀rọ̀, nígbà tí irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ń ṣẹlẹ̀, gbogbo èèyàn lo nílò láti sọ̀rọ̀."
Ó fi kun pé níní ìbáṣepọ̀ tó dánmọ́rán pẹ̀lú ìṣèjọba tó wà lóde kò túnmọ̀ sí pé òun fẹ́ fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ tàbí yapa lórí àwon ìlànà ẹgbẹ́ òun.
Ó tẹ̀síwájú pé àwọn olórí ní láti ṣiṣẹ́ papọ̀ lórí àwọn nǹkan tó kọjá ọ̀rọ̀ òṣèlú pàápàá ohun tó bá níṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ààbò àti mímú àdínkù bá ìṣẹ́ àti òṣì.
"Lóòótọ́ ni a wà lẹ́gbẹ́ òṣèlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣùgbọ́n Nàìjíríà jẹ́ àkànṣe iṣẹ́ tí gbogbo wa gbọdọ̀ pawọ́pọ̀ ṣe nítorí ìgbáyégbádùn àwọn èèyàn."
Tinubu kò retí àtìlẹyìn kankan látọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́dún 2027 - Fayose
Àmọ́ gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayose ti sọ pé ọ̀tọ̀ ni nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Makinde lọ ṣàbẹ̀wò sí Tinubu tí kò sọ síta.
Fayose, nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sójú òpó X rẹ̀ sọ pé Ààrẹ Tinubu ti sọ fún Makinde pé òun kò ní bá ṣe ìpàdé àyàfi tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó níṣe pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Oyo nìkan ló fẹ́ bá òun sọ.
Ó ní Tinubu sọ fún Makinde pé tó bá jẹ́ pé ó fẹ́ sọ fún òun pé Wike ló bí òun nínú tí òun fi lọ sọ gbogbo ohun tó sọ lórí amóhùnmáwòrán.
Fayose fi kun pé Tinubu sọ fún Seyi Makinde pé ọ̀rọ̀ òṣèlú ló fẹ́ bá òun sọ pàápàá pẹ̀lú ẹ̀sùn tó fi kàn pé òun fẹ́ sọ Nàìjíríà di orílẹ̀ èdè ẹlẹ́gbẹ́ òṣèlú kan ṣoṣo, ó dára kó lọ tún lọ sọ lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán.
Ó tẹ̀síwájú pé Ààrẹ sọ fún Makinde òun kò retí àtìlẹyìn kankan látọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́dun 2027.
Ó sọ pé ààrẹ ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé Wike jẹ́ èèyàn tó máa ń ṣe àtìlẹyìn fún òun àti pé tí Makinde bá ní ìkùnsínú pẹ̀lú Wike, kó jẹ́ kó wà láàárín àwọn méjéèjì.
Ó ní ìdí tí Makinde ṣe jáde láti sọ pé PDP tẹ́ òun lọ́rùn nítorí ó ti ri pé kò sí ààyè fún òun lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC.
"Lẹ́yìn ìpàdé náà, Makinde kò lè sọ fún àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo pé òun gba owó N30bn lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ láti ṣe àtìlẹyìn fáwọn tí ìbúgbàmù ṣàkóbá fún lọ́ṣù Kìíní, ọdún 2023."
Àmọ́ Gómìnà Seyi Makinde ní ohun tí Fayose sọ náà kìí ṣe òótọ́ nítorí ààrẹ gan-an ló pe òun sí ìpàdé náà.
Makinde tẹnumọ ọ̀rọ̀ tó nííṣe pẹ̀lú ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Oyo ni ìpàdé náà dá lé lórí tí kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí mínísítà fọ̀rọ̀ ìlú Abuja, Nyesom Wike.
"Mo lọ rí ààrẹ lẹ́yìn tó ránṣẹ́ sí mi láti jíròrò nípa ọ̀rọ̀ ìṣèlú tó ṣe pàtàkì, tó sì jẹ́ pàjáwìrì."














