Wo òkúta tó sọ ìlú Ilorin lórúkọ tó ń jẹ́

Àkọlé fídíò, Wo òkúta tó sọ ìlú Ilorin lórúkọ tó ń jẹ́
Wo òkúta tó sọ ìlú Ilorin lórúkọ tó ń jẹ́

O ti pẹ ti awọn eeyan ti maa n sọrọ nipa bi ilu Ilọrin ṣe gba orukọ rẹ. Bi awọn kan ba ṣe n sọ pe ilu Erin lo yi pada di Ilọrin lawọn miran n sọ omiran.

Eyi lo mu ki BBC News Yoruba ṣe abẹwo si ilu Ilọrin lati lọ ba awọn ọmọran to mọ oyun igbin ninu ikaraun lori iṣẹdalẹ ilu Ilọrin, ni ile kan ti wọn n pe ni Ile Ilọrin ni ilu Ilọrin.

Ọgbẹni Dauda, to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ile Ilọrin ṣalaye fun BBC News Yoruba pe ara okuta kan ni wọn ti fun ilu Ilọrin lorukọ rẹ.