Ilé ẹjọ́ wọ́gilé ẹjọ́ tí wọ́n pe tako Al-Mustapha, olórí ẹ̀ṣọ́ Sani Abacha, lórí ikú Kudirat Abiola

Oríṣun àwòrán, @deji_of_lagos
Ile ẹjọ giga orilẹede Naijiria ti da ẹjọ ti wọn pe tako amugbalẹgbẹ aarẹ tẹlẹ, Ọgagun Sani Abacha., Ọgagun fẹyinti Hamza Al- Mustapha fun ẹsun iṣekupa Kudirat Abiola, iyawo oludije aarẹ, MKO Abiola.
Lasiko igbẹjọ naa, wọn ṣafihan pe ijọba ipinlẹ Eko lo tun si aṣọ loju ẹjọ naa ṣugbọn ko si agbẹjọro kankan to wa soju ipinlẹ naa, ti ko sisi iwe kankan to ti lẹyin lati ọdun 2014 ti wọn gbe ẹjọ naa kalẹ.
Agbẹjọro Al-Mustapha, Paul Daudu sọ fun awọn adajọ pe ipinlẹ Eko ko tig be igbesẹ kankan lati tẹle aṣẹ ile ẹjọ ti wọn fun un lọdun 2014.
O fikun pe lẹyin ọdun mẹsan an, ipinlẹ Eko ko gbe igbesẹ kankan, to si pe fun pe ki ileẹjọ yi ẹjọ naa danu lẹsẹkẹsẹ.
Adajọ Uwani Aba-Aji, ẹni to lewaju awọn adajọ lori igbẹjọ naa beere lọwọ akọwe ile ẹjọ lo boya wọn kesi ijọba ipinlẹ Eko pe igbẹjọ yoo waye, to si dahun pe bẹẹni.
Lẹyin ọpọ jiroro, ile ẹjọ fẹnuko pe ijọba ipinlẹ ko fẹ tẹsiwaju ninu igbẹjọ naa, ti wọn s iyi danu.
Ta ni Kudirat Abiola?
Kò sí àní àní pé, ti à bá ti ń sọ̀rọ̀ iromi Moshood Kasimawo Olawale (MKO) Abiola to n jo lori omi, à máa gbúròó Kudirat Abiola, akọni obinrin tó jẹ onilu to ń lu ilu fun lábẹ omi.
Alhaja Kudirat Abiola pé ọdún mẹ́tàlélógún lónìí to wọ káà ilẹ̀ sùn, ọ̀pọ̀ ló gbàgbọ́ pé ìkú rẹ̀ kìí ṣe àmúwá ọlọrun nítori àwọn agbanípa ló pa a, nígbà ti ìjọba fi ọkọ rẹ̀ sẹ́wọ̀n.
Wọn mú ọkọ rẹ̀ nígbà ti wọn rii pe oun ló ń jawé olúbori nínú ìdìbò àpàpọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọdun 1993.
A bí Kudirat Abiola ni ọdún 1951 ní ilú Zaria, òun ni ìyàwó keji ti Abiola fẹ́, tó si bi ọmọ mẹ́fa.
Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣirísi ìwádìí ló wáyé lẹ́yìn ikú Kudirat, ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ̀yìn ti ó ti kú, gẹ́gẹ́ bí ohun ti ìròyìn sọ, wọn pàṣẹ fún ènìyàn ẹlẹni mẹ́fà kan láti parí iṣẹ́ ọhun ni.
Wọ́n pa Kudirat sínú ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbọn, bẹ́ẹ̀ ni awakọ̀ rẹ̀ náà bá ìṣèlẹ̀ yìí lọ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n olùrànlọ́wọ́ pàtàkì rẹ̀ tí wọn fẹ̀sùn kàn pé ó lọ́wọ́ nínú iku rẹ̀, to wà nínú ọkọ pẹ̀lú rẹ̀, kò fi ara pa rárá.
Lẹ́yìn ikú Kudirat Abiola ní wọn yíi orúkọ ilé iṣẹ́ rẹdíò tí wọn pé ni Radio Democracy, ti wọ́n ṣẹṣe dá sílẹ̀ ní Norway, pada sí Radio Kudirat.














