"Nítorí àwọn ọmọ mi tí wọ́n jí gbé ni mo ṣe darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ ọlọ́pàá"

Foday Musa ree, o wọṣọ alawọ ofeefe, ibanujẹ han loju rẹ, o de fila dudu to ni funfun ninu, o si jokoo kọyin sibi kan to jọ gilaasi.
Àkọlé àwòrán, Foday Musa ree, o ti fẹrẹ pe ọdun meji to ti foju kan awọn ọmọ rẹ gbẹyin
    • Author, Saidu Bah
    • Role, BBC Africa Eye
    • Reporting from, Makeni
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Baba ti aworan rẹ wa loke yii ni orukọ rẹ n jẹ Foday Musa, ibanujẹ han loju rẹ bo ṣe ṣẹṣẹ gbọ atẹjiṣẹ ohùn to gba gbẹyin lati ọdọ ọmọ rẹ ọkunrin.

Atẹjiṣẹ ọhun ko gùn rara, ọmọ rẹ to si n sọrọ nibẹ n sọrọ bii ẹni to n fẹ iranlọwọ kia, o n sunkun, bẹẹ lo n bẹ baba rẹ fun iranlọwọ.

"O nira lati maa gbọ. Bi mo ṣe n gbọ ohun rẹ yẹn ni ara n ni mi,"

Musa lo sọ bẹẹ fun BBC Africa Eye, ọmọ rẹ ọkunrin ati obinrin ni awọn kan fi ẹtan ati jibiti gbe lọ.

Iṣẹlẹ ọhun waye loṣu Keji ọdun 2024, nigba naa ni wọn fi ẹtan mu ọmọkunrin Musa, ẹni ọdun mejilelogun (22) ati ọmọ rẹ obinrin, ẹni ọdun mejidinlogun, (18) pẹlu awọn marun-un miran.

Wọn ni wọn n ko wọn lọọ ṣiṣẹ loke okun lati abule wọn to wa lagbegbe Faranah , Aarin Gbungbun Guinea.

Amọ wọn ko riṣẹ ọhun ṣe, o si pada wa jẹ pe awọn to n ta eeyan soko ẹru gbowo lo ko wọn lọ, wọn ki i ṣe agbanisiṣẹ rara.

Wọn ko wọn kọja aala ilu, o di Sierra Leone ti wọn ti sọ wọn sinu igbekun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ọkan mi gbọgbẹ. Omije ko yee wa soju mi. Ti o ba wo oju mi bayii, wa a ri inira naa nibẹ"

Musa lo sọ bẹẹ.

Ẹka ọlọpaa kan, Global policing agency Interpol, ni Guinea lo pada ni ki ẹka wọn to wa ni Sierra Leone dide iranwọ si Musa.

Osu Kẹjọ to kọja ni Musa lọ si Makeni, ni Aarin Gbungbun Sierra Leone, o wa awọn ọmọ rẹ lọ.

Awọn ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni QNET ni wọn lo wa nidii kiko awon eeyan lọ silẹ ibomi-in lọna aito yii.

Ilu Hong Kong ni wọn ti da QNET silẹ, ohun to si wa fun ni lati fun awọn eeyan ni igbesi aye ire ati alaafia, koda, wọn lorukọ labẹ ofin.

Ṣugbọn awọn kan n lo ileeṣẹ naa lati fi ko awọn eeyan lẹru.

Niṣe ni wọn maa n ṣeleri fawọn eeyan pe awọn yoo ko wọn lọ so US, Canada, Dubai ati Europe fun iṣẹ, wọn yoo si tun ni ki wọn sanwo to pọ ki wọn too fun wọn niṣẹ ọhun.

Bi wọn ba sanwo naa tan, awọn ilu alamuleti wọn ni wọn saba maa n ko wọn lọ, wọn yoo si si sọ fun wọn pe bawọn naa ba ri ẹlomi-in mu wa ni wọn yoo too le lọ soke okun tawọn jọ sọ.

Amọ bi wọn tiẹ pada tan awọn ẹbi wọn naa wa, iṣẹ kankan ki i yọju naa, wọn yoo tun jọ wa loko ẹru ni.

QNET funra rẹ ko dakẹ ṣaa, wọn n kede kiri pe ileeṣẹ awọn ko mọ nipa tita eeyan soko ẹru.

Bẹẹ ni wọn n fi patako polongo kiri pe kawọn eeyan ma ṣe ka awọn mọ olokoowo ẹru rara.

Aworan awọn ọlọja to n kiri nigboro Freetown, Sierra Leone, wọn n kọja niwaju patako ikede 'QNET to loun ko faramọ jibiti
Àkọlé àwòrán, Ọkan lara awọn patako ti QNET fi n kede pe awọn ko faramọ kiko eeyan lọ ta soko ẹru.

Idaamu Musa, baba to sanwo nla fawọn to mu awọn ọmọ rẹ lẹru

Ni ti Musa, idaamu rẹ ko kere bo ṣe ṣalaye.

Oun ati awon ẹbi rẹ ti kọkọ sanwo to to $25,000 (£19,000) fun awọn to ta ọmọ rẹ meji soko ẹru naa

-Wọn sanwo miran to wa fun pe kawọn ọmọ fi pada wale.

Bẹẹ lo si tun rin irinajo lọ so Sierra Leone, nibi to jẹ opin ireti fun un.

Ikọ ọlọpaa Interpol lo n ran an lọwọ.

Mahmoud Conteh, olori ikọ naa laaarin Sierra Leone, sọ pe idaamu Musa yii jẹ oun logun gan-an.

"O rọrun fun awọn to n ko wọn lọ soko eru yii lati ko wọn sọda sapa ibomiran."

Conteh lo sọ bẹẹ fun BBC.

Nigba to gbọ pe awọn ọdọ kan wa nibi kan ti wọn n pe ni Makineh, nibi ti wọn fi wọn pamọ si, oun ati Musa pẹlu awọn ọlọpaa jọ lọ sibẹ, wọn lọ tu ile ọhun wo yẹbẹyẹbẹ

Eeyan mẹwaa si mẹẹẹdogun lo n sun sinu yara kan ṣoṣo.

Awọn ọlọpaa Interpol naa ko gbogbo wọn, wọn si ri i pe awọn mi-in ko ju ọmọ ọdun mẹrinla lọ ninu wọn, ọmọ Guinea si ni pupọ wọn

Ṣugbọn awọn ọmọ Musa ko si ninu wọn, bo tilẹ jẹ pe ọmọkunrin kan sọ fun wọn pe wọn wa ninu ile yii lọsẹ to kọja.

Aworan awọn ọdọkunrin ati ọdọbinrin ti wọn jokoo silẹẹlẹ, wọn bo oju wọn. Inu ile tawọn ọlọpaa yabo ni Makeni naa wọn ti ri wọn.
Àkọlé àwòrán, Pupo ninu awon ti won ba nile to wa ni Makeni naa ni wọn wa latiGuinea

Ọlọpaa ko awọn ọdọ ti wọn ri lọ si agọ wọn

Agọ ọlọpaa ni wọn ko awon ọdọ ti wọn ba ninu ile naa lọ fun iwadii, ki wọn too ko mọkandinlogun ninu wọn lo sile wọn ni Guinea.

Gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi, o ti ju igba ogun (20) lọ ti wọn ti yabo awọn ibuba awọn to n ta eeyan soko ẹru naa, o si ti le ni ọgọrun-un kan eeyan ti wọn ti gba kalẹ.

Ọkan lara awọn ọmọ to lugbadi ẹtan yii ni Aminata, ẹni ti a yi orukọ rẹ pada nitori aabo rẹ.

O ni oun yege idanwo ti wọn ṣe foun, wọn si loun yoo lọ fi imọ kun imọ ranpẹ lori iṣẹ kan koun too tirafu lọ soke okun lati kawe koun si tun maa ṣiṣẹ.

Aminata sọ pe wọn ni oun gbọdọ san $1,000 lati lọ kẹkọọ naa, bayii ni awọn ẹbi rẹ ṣe ko owo to yẹ ko fi lọ si ẹkọ fun un lati fi ṣọna irinajo rẹ yii.

Amina ṣalaye pe bi eeyan ba ṣẹṣẹ de, awọn olokoowo ẹru naa yoo maa gbe e gẹgẹ, fun un lounjẹ. O ni to ba ya ni wọn ko ni i fun ni nnkan kan mọ.

"O gbọdọ maa ta ara rẹ nipa ibalopọ ni ko o le rowo jẹun, tọju ara rẹ." Amina lo sọ bẹẹ.

O ni wọn ni koun mu awọn ẹlomiran wa boun ba fẹ rin irinajo toun. Wọn si ti fun oun ni nọmba to jọ pe oun ti wa loke okun loootọ.

Aminata ni oun pe ọrẹ oun mẹfa ati ẹbi lati darapọ, wọn si wa, sibẹ, US ti wọn ṣeleri foun ko bọ si i.

Ṣugbọn ile ko ṣee pada si , nigba tawọn eeyan ti ro pe ilu oyinbo loun wa.

A ti mu mejila ninu awọn ẹlẹtan naa

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe wi, o ti to mejila ti ọwọ ti ba lara awọn to n ṣowo ẹtan naa.

BBC foju kan pupọ ninu awọn to lugbadi ẹtan naa ti wọn wa lati awọn ilu bii Burkina Faso, Guinea, Ivory Coast ati Mali.

Sugbọn otitọ to wa nibẹ ni pe pupọ ninu awọn ti wọn n mu yii ni ki i jẹjọ.

Akọsilẹ ẹka to n ri si onka iṣẹlẹ yii lati US sọ pe laaarin oṣu Keje ọdun 2022 ti wọn ṣofin to tako kiko eeyan lọ ṣowo ẹru ni Sierra Leone ati oṣu Kẹrin ọdun, igbẹjọ mẹrin pere lo waye fun ẹsun kiko eeyan lọ sibomiran lọna aitọ.

Ṣe Musa pada ri ọmọ rẹ?

Baba ti a fi bẹrẹ iroyin yii, Musa, ko ri awọn ọmọ rẹ to wa lọ, niṣe lo pada sile ni Guinea nipari oṣu Kẹsan-an ọdun to kọja .

Ṣugbọn ọlọpaa Conteh sọ fun BBC pe wọn ti fi awọn ọmọ naa silẹ.

BBC fidi ẹ mulẹ pe ọmọbinrin Musa pada si Guinea, ṣugbọn ko ti i pada si abule wọn ko si fẹ ba oniroyin sọrọ.

Koda, ko ti i kan si baba rẹ, eyi to fi han pe oju n ti i gẹgẹ bo ṣe maa n ri fun ọpọ awon to ba lugbadi ẹtan yii.

A ko mọ ibi ti ọmọkunrin Musa wa ni tiẹ, o si n jẹ ibanujẹ gidi fun baba wọn.

"Lẹyin gbogbo ohun to ṣẹlẹ, mo ṣaa fẹ ri awọn ọmọ mi ni" Musa lo sọ bẹẹ..

"A fẹ ki wọn pada wa si abule bayii, o wu mi ki wọn wa pẹlu mi."

Bẹẹ ni baba naa fi ẹdun ọkan ṣalaye.

Afikun iroyin lati ọwọọ Paul Myles, Chris Walter, Olivia Acland ati Tamasin Ford