'Ohun ìtìjú' - Ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú Senegal kúrò lórí pápá ìṣeré fún ìgbà díẹ̀ níbi ìdíje àṣekágbá Afcon 2025

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Keifer MacDonald
- Role, BBC Sport journalist
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kìíní, ọdún 2026 ni Senegal lu Morocco mọ́lé láti fi gba ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Afcon, Afcon 2025 fún ìgbà kejì.
Ìjáwé olúborí wọn náà ló ń wáyé lẹ́yìn tí ìfaǹfà kan wáyé nígbà tí adarí eré fọn fèrè pẹnáritì fú Morocco tako Senegal nígbà tó kù díẹ̀ kí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà parí.
Nígbà tí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà wọ ìṣẹ́jú méjìdínlọ́gọ́rùn-ún ni adarí eré, Jean Jacques Ndala lẹ́yìn àyẹ̀wò VAR fọn fèrè náà pé agbábọ́ọ̀lù tó ń gbá ọwọ́ ẹ̀yìn fún Senegal El Hadji Malick Diouf ṣe aṣemáṣe sí agbábọ́ọ̀lù Morocco, Brahim Diaz.
Èyí ló mú kí akọ́nimọ̀ọ́gbá fún agbábọ́ọ̀lù Senegal, Pape Thiaw fi bínú pé káwọn agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ kúrò lórí pápá ìṣeré nítorí ìpinnu adarí ayò náà kò tẹ lọ́rùn.
Ìgbésẹ̀ Thiaw ló ń wáyé lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀ tí adarí eré pa góòlù tí Senegal ti ṣáájú jẹ nù nítorí aṣemáṣe tí agbábọ́ọ̀lù Senegal ṣe sí agbábọ́ọ̀lù Morocco síwájú.
Àmọ́ Sadio Mane, tó ń gbá ọwọ́ iwájú fún Liverpool tẹ́lẹ̀ dúró lórí pápá ìṣèré, tó sì pàrọwà sáwọn ọmọ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ láti má fi oerí pápá ìṣeré náà sílẹ̀, kí wọ́n ri dájú láti parí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà.
Lẹ́yìn bíi ìṣẹ́jú mẹ́tàdínlógún tí ìdádúró fi wà, àwọn agbábọ́ọ̀lù náà padà sórí pápá láti parí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà.
Ṣùgbọ́n Diaz tó gbá pẹnáritì náà gba sọ́wọ́ aṣọ́lé Senegal, Edouard Mendy tí adarí eré sì fọn fèrè ìparí eré lẹ́yìn náà.
Láàárín ìṣẹ́jú mẹ́rin tí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ bẹ̀rẹ̀ padà fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú àkókó tí wọ́n fi kun láti tẹ̀síwájú eré ni Pape Gueye jẹ ayò kan fún Senegal èyí tó pàpà mú wọn jáwé olúborí níbi ìdíje náà.
Nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lẹ́yìn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà, akọ́nimọ̀ọ́gbá Morocco, Walid Regragui sọ pé ìwà tí àwọn Senegal wù láti kúrò lórí pápá jẹ́ ohun ìdójútì, tí kò sì buyì kún Africa.
Ààrẹ Fifa, Gianni Infantino nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sójú òpó Instagram rẹ̀ bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé náà.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú BeIN Sport, Thiaw sọ pé òun gbà pé kìí ṣe ohun tó bójúmu bí òun ṣe ní káwọn agbábọ́ọ̀lù òun kúrò lórí pápá.
Ó tọrọ àforíjì lórí ìgbésẹ̀ náà àmọ́ tó ní bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ká òun lára ni òun fi hùwà.
"Kò yẹ kí a ṣe bẹ́ẹ̀ àmọ́ ó ti wáyé, a tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn eléré bọ́ọ̀lù."
Ohun tó bí Thiaw nínú kò ṣẹ̀yìn bí adarí eré, Ndala kò ṣe ka góòlù tí Ismaila Sarr tí kọ́kọ́ jẹ fún ẹ̀sùn pé Abdoulaye Seck ti Achraf Hakimi lójú ilé kí wọ́n tó jẹ ayò náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn agbábọ́ọ̀lù Senegal ni wọ́n tẹ̀lé àṣẹ Thiaw láti kúrò lórí pápá, táwọn alátìlẹyìn wọn míì sì gbìyànjú láti yawọ orí pápá.
Diaz tó sọ pẹnáritì nù ni ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́ lẹ́yìn ìdíje náà nítorí orílẹ̀ èdè rẹ̀ kò rí àǹfàní láti gba ife ẹ̀yẹ náà láti ọdún 1976 tí wọ́n ti gbà á kẹ́yìn.
Lẹ́yìn ìdíje náà Mane sọ pé ìdíje pàtàkì ni bọ́ọ̀lù gbígbá jẹ́ àti pé gbogbo àgbáyé ló ń wò wọ́n, tí wọ́n sì nílò láti ṣàfihàn ohun rere.
"Mo wò ó wí pé kìí ṣe ohun tó bójúmu fún wa láti má parí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà nítorí adarí eré fọn pẹnáritì. Mo rò ó pé ohun tó burú jùlọ nínú ìdíje ilẹ̀ Africa ni. Ó tẹ́mi lọ́rùn ká fìdí rẹmi ju irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ.
Aṣọ́lé Senegal, Mendy ní ìwúrí ló jẹ́ fún òun bí Senegal ṣe padà sórí pápá lẹ́yìn tí Mane darí àwón láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì tún padà borí ìdíje náà.
Gueye ní tirẹ̀ sọ pé àwọn rò ó pé ìyànjẹ ló jẹ́ fún àwọn bí adarí eré ṣe pa góòlù àwọn rẹ́ láì ṣe àyẹ̀wò VAR àmọ́ tó ṣe bẹ́ẹ̀ fún Morocco.
'A ò ní fààyè gba ìwà ipá nínú ìdíje ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀'
Lẹ́yìn tí Infantino nínú àtẹ̀jáde tó fi sórí Instagram kí Senegal kú oríire, tó sì kan sáárá sí Morocco fún bí wọ́n ṣètò ìdíje náà, ó ní kò tọ̀nà láti forí pápá ìṣeré sílẹ̀ báwọn Senegal ṣe ṣe.
Ó wòye pé gbogbo àṣẹ táwọn adarí eré bá ti pa ló yẹ káwọn agbábọ́ọ̀lù máa tẹ̀lé nítorí ewu wà níbẹ̀ fún ọjọ́ iwájú eré bọ́ọ̀lù tí wọ́n bá kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Ó ní ohun tó ṣẹlẹ̀ náà kò gbọdọ̀ wáyé ma, tó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ àwọn agbábọ́ọ̀lù àtàwọn òṣìṣẹ́ láti máa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀.
Ó fi kun pé òun ní ìgbàgbọ́ pé CAF máa gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti dá sẹ̀ríà fún gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn.
Ohun tí kò bójúmu láti fi parí ìdíje Afcon
Ó jẹ́ ohun tí kò bójúmu kí ìdíje tó jẹ́ ìpolówó ọjà fún Africa parí bí ó ṣe wáyé náà.
Bí àwọn alátìlẹyìn eré bọ́ọ̀lù ṣe fẹ́ gbìyànjú láti yawọ orí pápá, táwọn òṣìṣẹ́ bọ́ọ̀lù míì ń ba ara wọn fa wàhálà jẹ́ ohun tí mi ò gbàgbọ́ pé ó le wáyé rárá.
Lẹ́yìn náà láwọn agbábọ́ọ̀lù Senegal ń fi orí pápá ìṣeré sílẹ̀. Ohun tí kò dára rárá fún ìdíje Afcon ni.
Ṣáájú ni àwọn èèyàn tó fi mọ́ àwọn akọ̀ròyìn ti ń fẹ̀sùn kàn pé àwọn adarí eré pẹ̀lú lílo VAR ń ṣe ojú ṣàájú fún àwọn Morocco lòdì sí àwọn orílẹ̀ èdè yòókù.
Kódà, yíyan àwọn adarí eré fáwọn ìdíje kan ń fa awuyewuye lórí ayélujára.
Ṣáájú kí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàárín Senegal àti Morocco tó wáyé lọ́jọ́ Àìkú ni Senegal ti ń fẹ̀sùn kàn pé Morocco kò fún àwọn ní ààbò tó péye nígbà tí wọ́n balẹ̀ sí Rabat lọ́jọ́ Ẹtì àti pé wọn kò fún àwọn ní tíkẹ́ẹ̀tì tó péye fáwọn èèyàn wón.
Kò sí ẹni tó ní ìrètí pé ohun tó wáyé lẹ́yìn fífún Morocco ní pẹnáritì le ṣẹlẹ̀, tó sì jẹ́ pé ààrẹ Fifa, Gianni Infantino wà ní ìkàlẹ̀ láti wo eré náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ti ń ṣáájú gbé oríyìn fún Morocco fún àgbékalẹ̀ ìdíje náà pẹ̀lú àwọn pápá ìṣeré àtàwọn ohun èlò tí wọ́n pèsè.
Síbẹ̀, pẹ̀lú bí ó ṣe ku ọdún mẹ́rin láti gbàlejò ife ẹ̀yẹ àgbáyé, ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé yìí jẹ́ ohun tí wọ́n yóò máa rántí nípa ìdíje yìí fún ìgbà pípẹ́.
Ohun tó dára láti sọ nípa ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fí bẹ́ẹ̀ sí ohun tó dùn mọ́ni púpọ̀ níbi ìparí ìdíje Afcon yìí, èèyàn kan tó ṣe dada níbẹ̀ ni Mane.
Òun nìkan ni agbábọ́ọ̀lù Senegal tó fojú hàn pé kò fẹ́ kúrò lórí pápá, tó sì ń sọ fáwọn yòókù rẹ̀ pé kí wọ́n padà.
Bákan náà ló tún lọ sọ́dọ̀ àwọn alátìlẹyìn orílẹ̀ èdè wọn láti ṣe sùúrù nígbà tí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà parí.
Senegal kọminú lórí àwọn agbábọ́ọ̀lù ṣáájú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá
Ṣáájú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá ọjọ́ Àìkú, àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ bọ́ọ̀lù ní Senegal kọminú lórí ààbò àwọn agbábọ́ọ̀lù náà.
Níṣe ni àwọn alátìlẹyìn yabo àwọn agbábọ́ọ̀lù náà bí wọ́n ṣe dé Rabat lọ́jọ́ Ẹtì.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí àjọ náà fi léde, wọ́n kọminú lórí ilé ìtura, iye tíkẹ́ẹ̀tì tí wọ́n fún wọn. Bákan náà ni wọ́n sọ pé wọn kò fún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ní ibi tí wọ́n ti máa ṣe ìgbáradì kí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó wáyé.
Wọ́n ní àìsì ètò ààbò tó péye jẹ́ fífi ẹ̀mí àwọn agbábọ́ọ̀lù náà àtàwọn òṣìṣẹ́ míì sínú ewu.
'Fífi orí pápá sílẹ̀ kò dára fún bọ́ọ̀lù Africa'
Agbábọ́ọ̀lù iwájú fún Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Efan Ekoku sọ pé bí Thiaw àtàwọn agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ ṣe kúrò lórí pápá fún ìgbà díẹ̀ náà kò dára tó fún bọ́ọ̀lù ilẹ̀ Africa.
Ekoku sọ fún E4 pé ìpinnu adarí eré náà kò burú rárá nítorí ohun tí Diouf ṣe kò tọ̀nà àti pé rẹfẹrí ti sọ̀rọ̀, ó sì di dandan kí wọ́n tẹ̀le.
John Mikel Obi ní tirẹ̀ sọ pé òun mọ nǹkan tó ṣe àwọn agbábọ́ọ̀lù Senegal àmọ́ kíkúrò lórí pápá kọ́ ni ohun tó kàn.












