Imam tó dá ààbò bo àwọn Kristẹni sínú mọ́ṣáláṣí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn darandaran jáde láyé

Oríṣun àwòrán, US EMBASSY NIGERIA
Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu ti kọrin aro lẹ́yìn Imam Abdullahi Abubakar, ẸNI TÓ Jẹ́ Imam àgbà ìlú Nghar ní ìjọba ìbílẹ̀ Ladi, ìpínlẹ̀ Plateau.
Ní ọdún 2018 ni Imam Abubakar di gbajúgbajà káàkiri àgbáyé fún bí ó ṣe sá ààbò bo àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó lé ní 200 lásìkò tí ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà kan wáyé ní ìpínlẹ̀ Plateau lásìkò náà.
Nígbà tí ìjà náà wáyé, Imam Abubakar fi àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó lé ní 262 pamọ́ sí inú ilé àti mọ́ṣáláṣí rẹ̀ láti dá ààbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn darandaran tó ń fa wàhálà náà.
Lọ́dún 2019 ni Amẹ́ríkà fi àmì ẹ̀yẹ International Religious Freedom Award dá Imam Abubakar lọ́lá fún akitiyan náà àti pé ó fi ààyè gba àwọn ẹlẹ́sìn lásìkò ìpọ́njú.
Ní ọdún 2022 ni ìjọba Nàìjíríà tún fi àmì ẹ̀yẹ da lọ́lá lórí ìgbésẹ̀ náà.
Lọ́jọ́bọ̀ ni Imam Abubakar jáde láyé ní ilé ìwòsàn Plateau Specialist Hospital tó wà ní ìlú Jos lẹ́ni ọdún méjìléláàádọ́rùn-ún (92).
Àìsàn ọkàn ni ìròyìn sọ pé ó ṣekúpa Imam Abubakar.
Ààrẹ Tinubu nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀, Bayo Onanuga fi léde lọ́jọ́ Ẹtì jùwe Imam náà bíi olórí ẹ̀sìn tí ìgbé ayé rẹ̀ ṣàfihàn ìgbàgbọ́, ìgboyà àti ìfarajìn sí ọmọnìyàn.
Ó ní Imam náà dúró lórí òótọ́, àánú lásìkò tí ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti ẹ̀sìn ń ru bojú àwọn èèyàn.
Ó wòye pé Imam náà kò nání ewu tí ìwà rẹ̀ le mú bá ẹ̀mí rẹ̀ tó sì jẹ́ kí ìfẹ́ jọba dípò ìpinyá.
Bákan náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Gyang Bere fi léde ní èèyàn tó ní ìmọ̀lára tó sì máa ń mú àgbéga bá àlááfíà àti ìṣọ̀kan ni Imam Abubakar kó tó jáde láyé.
Gómìnà Caleb Mutfwang ní Imam Abubakar fi gbogbo ìgbé ayé rẹ̀ dá ààbò bo àwọn tí wọ́n nílò àánú tó fi mọ́ àwọn ọmọdé àti obìnrin.
Ó ní àdánù ńlá ni ikú rẹ̀ jẹ́ fún àwọn ẹbí, ìlú àti ìpínlẹ̀ náà lápapọ̀, tó sì kan sáárá sí Imam náà fún ipa rẹ̀ nínú ìlú náà nígbà ayé rẹ̀.
Bákan náà ni igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Nàìjíríà, Atiku Abubakar kọrin arò lẹ́yìn Imam náà fún ìwà rẹ̀ láti dá ààbò bo àwọn tí kìí ṣe ẹlẹ́sìn rẹ̀ lásìkò tí wọ́n nílò rẹ̀.















