Eniola Badmus wọ pátá lọ sí ààfin Oba Elegushi, kí ló burú níbẹ̀? Wo bí wọ́n ṣe ń wa itọ́ ọ̀rọ̀ lée lórí

Oríṣun àwòrán, Eniola Badmus
Loju awọn eeyan kan, gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Eniola Badmus ti ṣe nkan eewọ bi wọn ṣe ri awọn aworan rẹ ninu aafin Kabiyesi Ọba Elegushi.
Ki ni Eniola Badmus ṣe to to bẹẹ ti ọrọ ati eebu yii pọ bayii? Eyi tun ni ibeere awọn mii to n gbe lẹyin rẹ.
Gbajumọ oṣere fiimu Yoruba ni Eniola Badmus, lọjọ bii melo kan syin si ni awọn eeyan n wa eguna ọrọ lee lori pe o wọ ẹwu ati ṣokoto pempe ti wọn n pe ni "Bum short" lọ si aafin Ọba.

Oríṣun àwòrán, Eniola Badmus
Eniola fi awọn aworan ibẹwo rẹ si aafin Ọba naa sita, kete to fi sita lawọn eeyan ti bẹrẹ si nii bu pe ki lo wọ.
Awọn mii ni eewọ ni iru nkan bẹẹ ati pe ariofin ni ki eeyan mura bẹyẹn lọ si aafin Ọba Yoruba.
"Lootọ, ko sohun to buru ninu wiwọ ṣokoto pempe am a gbagbe pe a ni lati mura ni ibamu pẹlu ibi ti a ba n lọ ni bii "a n lọ eti okun, ibi apeja, ipeni si iṣẹ...
Ṣugbọn a lati ronu, bi awọn eeyan ba ni idi lati lọ ọdọ Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi tabi Ọba orilẹede mii, oo wọ aṣọ gidi oo si tẹle ilana.
Amọ ni Afirika yii, o yẹ ki a tubọ ni ibọwọ fun aṣa wa, kilode too wa fi mura bii pe inu ile ara rẹ lo wa tabi leti okun lati lọ ki Ọba l'aafin. O yẹ ka ronu o..." - MNkem Ojei-Adibe

Oríṣun àwòrán, Kemi Filani
- Aṣọ tí mo wọ̀ lọ sí 'Headies Award' ló sún mi débi oríire ipò aṣojú LAWMA- Eniola Badmus
- Ẹ̀yin tí ẹ máa ń bú àwon tó sanra ni ẹ ń jẹ́ kí wọ́n ronú pa ara wọn - Eniola Badmus
- Èèyàn 300 ló pè mí láti mọ̀ bóyá ìbọn bà mí ní Lekki - Eniola Badmus
- Wo ìdí tí àwọn tọkọ-taya kan ṣe ń ṣe ìgbéyàwó nínú pósí
- Ó bà ni kò bàjẹ́, ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Anthony Joshua sọ lẹ́yin tí Usyk fẹ̀ṣẹ̀ gbadé orí rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀
Ṣe ni awọn eeyan n sọrọ pe ko wo bi awọn ọkunrin to wa ninu aafin ṣe n wo idi Eniola.
Awọn mii ni boya o fẹ fa oju ọba mọra ni lo ṣe mura bẹẹ.
Ẹwẹ, Olanite Nosimot Motunrayo ni tirẹ woye pe to ba ṣe pe kii ṣe eeyan to sanra ni, ko sẹni ti yoo woo debi pe wn yoo maa pariwo.
Udysammy Akwaowo naa gbe lẹyin r pe awn olofofo adugbo lo kan n fi eebu ara bu u.

Oríṣun àwòrán, Kemi Filani
Loju opo Instagram Eniola Badmus funrarẹ to fi awọn fọto naa si, awọn akẹgbẹ rẹ n kan sara sii. Amọ lara awọn ololufẹ rẹ mii ni ibi ti fifi ibalopọ lọ ni ti n bẹrẹ ree o.

Oríṣun àwòrán, Eniola Badmus
Eniola ni oun ni anfani nibẹ lati fọrọ jomi toro ọrọ pẹlu Ọba nipa ayẹyẹ ogun ọdun lori itage ti oun fẹ ṣe. Koda o ti n fi tọ awn ololuf rẹ lẹnu wo pe Ọba Orin Wasiu Ayinde Marshal yoo krin lọjọ naa.
niola Badmus ni ọjọ nla ni ọjọ ti oun n reti yii toun si fẹ gbalejo gbogbo eeyan to fi m awọn to pade ni irinajo ogun ọdun to ti lo ninu iṣẹ tiata.



















