Taliban's law against Shaving beards: Wo dẹndẹ ìyà tó ń bẹ fún ọ báyìí o tóo bá fa irungbọ̀n ní Afghanista torí Sharia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ti di ewọ bayii lati maa fa irugbọn lorilẹede Afghanistan, ijọba Taliban lo sọ bẹẹ.
Ijọba Taliban ti kilọ fawọn gẹrigẹri lẹkun Helmand pe wọn ko gbọdọ fa irugbọn fun ẹnikan kan mọ.
Taliban sọ pe eyi ṣe ilodi si ilana ofin Islam, ati pe ijiya to tọ ti wa fun ẹnikẹni to ba tapa si ikede ijọba yii.
- Jíjẹ́ obìnrin ti ṣí ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ọ̀nà fún mi, ẹ̀yin obìnrin ẹlẹgbẹ́ mi ẹ wá kọ́ bẹ́ẹ ṣe lè lo kíní yín - Bobrisky
- Hijab kò dí mi lọ́wọ́ láti di obìnrin agbábọ́ọ́lù láì náání yẹ̀yẹ́ - Zulfah Abdulazzez
- Kò sí ọ̀nà nínú kí Nàìjíríà pín, àtúntò ló lè mú àlááfíà àti ìṣọ̀kan wá- Alaafin
- Ọ̀wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run Olódùmarè ni Ogboni máa wà bí ó bá re ibi àgbà ń rè - Oba Ogboni
- Agbẹjọ́rò méjì yọ ẹ̀sẹ́ síra wọn níwájú adájọ ó ku ẹni tí yóò yanjú ọ̀rọ̀
- 'Bola Tinubu ńbọ̀ ní Nàìjíríà láìpẹ́, àmọ́ kò tíì dé'
- 'Eniola Badmus wọ pátá lọ sí ààfin Oba Elegushi, "ọ̀ín" kí ló burú níbẹ̀?'
- Wo ohun tí ọlọ́pàá sọ nípa 'Charlie', ajá tó gé kórópọ̀n akẹ́kọ̀ọ́ fásitì AAUA jẹ l'Ondo
- Ọkùnrin tó fẹ́ bá mi d'ọ̀rẹ́ lórí Facebook fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ nígbà tó rí mi lójúkojú - Folashade Adeyemo
Awọn ọlọpaa Taliban ti wa nilẹ lati maa da ṣeria fun ẹnikẹni to ba tapa si ofin ti ijọba gbe kalẹ yii.
Awọn gẹri-gẹri kan to wa ni olu ilu Afghanistan, Kabul naa ti sọ pe awọn ti gba aṣẹ yii lati ọdọ ijọba.
Igbesẹ yii tọka si pipa si ọna ti awọn Taliban fi ṣe ijọba wọn tẹlẹ lorilẹede naa bo tilẹ jẹ pe wọn ṣeleri lati ma mu aye le fawọn eeyan.
Ijọba Taliban ti bẹrẹ si ni fi ọwọ lile mawọn alatako lẹyin ti wọn gba ijọba loṣu to lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọjọ Abamẹta ni wọn pa awọn afurasi ajinigbe mẹrin ti wọn si so oku wọn rọ lopopona Herat.
Awọn ọlọpaa ijọba Taliban ti lẹ ikilọ si awọn ile gẹri-gẹri ni ẹkun Helmand pe wọn gbọdọ maa tẹle ofin Sharia lori irun gigẹ ati irugbọn fifa.
Wọn sọ ninu ikilọ pe ko si aye fun awawi kankan lati ọdọ awọn gẹri-gẹri lori ọrọ yii.
Baba kan niluu Kabul sọ pe niṣe lawọn ọlọpaa Taliban n ṣọ awọn lọwọ lẹsẹ lati ti pe awọn tẹle ofin ti wọn ṣe agbekalẹ rẹ ni tipa tipa.
Lasiko ijọba Taliban laarin ọfdun 1996 si 2001, ijọba ko faye gba kawọn eeyan maa ṣe irun to ba wu wọn.
Ẹnikẹni ko gbọdọ ge irugbọn rẹ tabi rẹẹ silẹ rara lasiko ijọba Taliban nigba naa.















