Yoruba Nation: Afenifere àti Ilana Omo Oduduwa fèsì sọ́rọ̀ Alaafin tó ni kò s'ọ́nà nínú pínpín Nàìjíríà

Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III

Ẹgbẹ Afenifere ilẹ Yoruba ti sọ pe ọrọ ti Alaafin sọ pe atunto lo le mu ilọsiwaju ati iṣọkan ba orilẹede Naijiria kii ṣe iyapa wa ni ibamu pẹlu ero ẹgbẹ naa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, eekan ẹgbẹ Afenifere, Bashorun Seinde Arogbofa ṣalaye pe ohun to dara julọ fun Naijiria bayii ni pe ''ki a maa pinya.

Ai maa tẹle eto ijọba ẹlẹkun-jẹkun lo mi ki awọn eeyan bii Sunday Igboho ati IPOB maa beere fun iyapa kuro lara Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ìran mi ò ja ẹ̀ṣẹ́ rí, ẹ̀gbin yìí ló ta lé mi tí mo fi di "Scorpion" Ọ̀gá ọ̀gá nínú ìjà

Niṣe lo yẹ ki awọn ipinlẹ ati ẹkun kọọkan ma dari ọrọ aje wọn fun ra wọn ki wọn si maa fi si ida diẹ ranṣẹ si ijọba apapọ bi igba aye ijọba Obafemi Awolowo.

O si ti n bẹrẹ diẹdiẹ pẹlu bi awọn ipinlẹ lẹkun Guusu ti fofin de idẹran jẹko ni gbangba ati gbigba owo ori VAT fun ra wọn.''

Amọ, ero ẹgbẹ Ilana Omo Oduduwa yatọ lori ọrọ naa.

Alukoro ẹgbẹ Ilana Omo Oduduwa, Ọgbẹni Maxwell Adeleye sọ fun BBC Yoruba pe ọgbọn ni Alaafin fi sọrọ nitori abẹ ijọba lawọn ọba alaye wa nilẹ Yoruba.

''Abẹ alaga ijọba ibilẹ ni Alaafin wa, ohun ti ofin ti Fulani gbe le wa lọwọ sọ niyẹn.

Baba Alaafin ti awa mọ o, ẹyin otitọ lo wa, ọmọ ọdọ naa fi ọgbọn ṣee ni.

Alaafin to sọ pe oun wa lẹyin Igboho tẹlẹ ko le sọ nisinyii pe oun ko ṣe ti Igboho mọ.

Nitori idasilẹ orilẹede Yoruba ni Igboho n beere fun, nitori naa, ti baba ba sọ pe oun fẹ Yoruba Nation mọ, a jẹ wi pe baba ko ṣe ti Igboho mọ niyẹn.

Baba ni Alaafin jẹ fun wa, a ko si le maa gbo wọn lẹnu, ṣugbọn a mọ pe ọdọ wa ni ọkan wọn wa,'' Ọgbẹni Adeleye lo sọ bẹẹ.

Kò sí ọ̀nà nínú kí Nàìjíríà pín, àtúntò ló lè mú àlááfíà àti ìṣọ̀kan wá - Alaafin

Alaafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta ti rọ awọn ọmọ Naijiria atunto orilẹede yii lo le mu iṣọkan ati ilọsiwaju wa kii ṣe pinpin Naijiria.

Alaafin rọ awọn eeyan lati kọ eti ikun si awọn to n pe fun iyapa kuro lara orilẹede Naijiria.

Oba Adeyemi sọrọ yii nibi ayẹyẹ ifilọlẹ yara ikẹkọọ marunlelọgbọn ile ẹkọ Royal Gold Model ati fifi ipilẹ mọṣalaaṣi kan lelẹ niluu Ibadan.

Àkọlé fídíò, Ọ̀wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run Olódùmarè ni Ogboni máa wà bí ó bá re ibi àgbà ń rè

Alaafin ni ọpọ nkan to ṣẹlẹ sẹyin lo ṣe okunfa iwa ẹlẹyamẹya ati idẹyẹsi laarin awọn ọmọ Naijiria.

Amọ, o rọ awọn ọmọ Naijiria lati wa ọna ti wọn le fi yanju awọn ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin ni itubi inubi ki orilẹede Naijiria le tẹsiwaju.

''Mi o lero pe pinpin Naijiria ni ojutuu si iṣoro to n koju Naijiria.

Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III

Ṣugbọn a le ṣe atunto orilẹede yii lọna ti alaafia yoo fi jọba ti a o si maa gbe pọ ni alaafia.

A nilo lati wa ni iṣọkan ni Naijiria ki orilẹede yii maa baa pin yẹlẹ yẹlẹ,'' Alaafin lo sọ bẹẹ.

Oba Adeyemi ko ṣai lu adari ile ẹkọ naa, Alhaji Taofeek Akewugbagold, lọgọ ẹnu lori bi o ti n pe fun iṣọkan laarin awọn ọmọ Naijiria.

Ninu ọrọ tiẹ, Akewugbagold naa rọ awọn musulumi lati ma dẹyẹ si awọn ẹlẹsin miran.

Alhaji Akewugbagold ni ''ko yẹ ki awọn ẹlẹsin kan maa doju ibọn kọ awọn ẹlẹsin miran.

Onikaluku lo lẹtọọ lati ṣe ẹsin ti wọn ba fẹ tori ojiṣẹ Ọlọrun ni Jesu ati Anọbi Muhammad.''

Almufty Ilorin, Sheikh Sulaimon Onikijipa to sọrọ apilẹkọ nibi ayẹyẹ naa kepe awọn musulumi lati maa tẹle awọn ẹkọ iwe mimọ Quran, ki wọn si ye wa iṣẹ iyanu nibi ti ko si.

Àkọlé fídíò, 'Mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi'